Muyiwa Ademola: Ẹ forí jìn mí, àpàrá lásán tí mo dá nípa òṣèlú ṣíṣe ti gbọ̀nà míì yọ

Oríṣun àwòrán, Instagram/authenticmuy
Muyiwa Ademola, ti ọpọ eeyan mọ si Muyi Authentic ti sọ pe, iṣẹ tiata ni iṣẹ ti ori ran oun ati pe oun ko nifẹ si oṣelu ṣiṣe.
Ademola lo sọ ọrọ naa loju opo Instagram rẹ, lẹyin to ti kọkọ kede saaju nipa ipinu rẹ lati darapọ mọ oṣelu sise.
Ninu ikede to kọkọ gbe jade lọjọ kinni, oṣu Kẹrin lo ti sọ pe oun ti bẹrẹ oṣelu, ati pe oun yoo du ipo sẹnatọ ninu idibo gbogbo gboo ti yoo waye lọdun 2023.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Gbàjarè! Ọ̀gá ọlọ́pàá fi ìwé ìpè àti géńdé 15 ránṣẹ́ wá mú mi - Sunday Igboho pariwo
- Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá Oyo fèsì sí ẹ̀ṣùn Aláàfin àti Gani Adams pé ó ń tú afurasí sílẹ̀
- Oluwo, tí wọ́n bá rán ọmọ níṣẹ́ ẹrú, kó fi t'ọmọ jẹ - Gani Adams
- Òkùtà wọ agbe ṣíṣe, alágbe kò rí àánú gbà mọ́, ariwo sọ
- Rògbòdìyàn gbòde lọ́jà Bodija torí aṣọ́bodè tó fi tipá kó àpò ìrẹsì tírélà méje lọ
- Àwọn òṣèré tó ti bàjẹ́ láti ilé, ló kó ìbàjẹ́ wọ agbo tiata débi a'ṣọ ìhòòhò - Dele Odule
- Omijé ẹkún ṣàn níbi ìsìnkú sájẹ́ǹtì ọlọ́pàá táwọn tọ́ọ̀gì òṣèlú pa l'Ekiti
- Wo ohun tí yó ṣẹlẹ̀ sí àwọn tí kò ní nọ́mbà ìbánimọ̀ NIN ní Nàìjíríà
- Awọn Dokita 'NARD' da iṣẹ silẹ lati bere ẹtọ wọn lọwọ ijọba
Ṣugbọn o ti wa sọ pe apara lasan ni ọrọ oun akọkọ nipa sise oṣelu.
O ni "Apara ti mo da yii ti n gbọna mii yọ o, mo kan ni ki n ṣere diẹ ni, ṣugbọn mo ni lati tọrọ aforoji lọwọ ẹyin ololufẹ mi."

Oríṣun àwòrán, Instagram/authenticmuy
Muyi Authentic sọ pe, oriṣiriṣi ipe ni oun gba lati ọdọ awọn ololufẹ oun kaakiri Naijiria titi de ilu Abuja lori ọrọ pe oun ti di oloṣelu, ṣugbọn o ni "April Fool" lasan ni ikede ọhun.
O sọ siwaju si pe, apara ti oun da naa, jẹ ki oun mọ si nipa ifẹ ti awọn eeyan ni si oun ati irufẹ oju ti ọpọ eeyan fi wo ọrọ oṣelu ni Naijiria.
O ni "bi awọn kan ṣe n ṣọ pe awọn wa lẹyin mi digbi bii ike, lawọn mii n sọ pe ki n ma ba wọn lọwọ si ọrọ oṣelu Naijiria fun idi kan tabi omiran."
Muyiwa ni oun tun kọ ẹkọ tuntun miran nipa awọn eeyan ilu ti oun n gbe lori, nipa bi wọn ko ṣe lee ti oun lẹyin to ba tilẹ jẹ pe lootọ ni oun fẹ gbegba oṣelu.

Oríṣun àwòrán, Instagram/authenticmuy
Ọmọ Ademola sọ pe "o jẹ ohun iyalẹnu fun mi pe awọn eeyan ilu ti mo ti ka gbogbo iwe aye mi, ti mo kọle si, ti mo n gbe, ti mo si tun ti n ṣiṣẹ ko ti mi lẹyin ninu ọrọ oṣelu yii, to ba tilẹ jẹ pe lootọ ni mo fẹ ṣe oṣelu."
Lẹyin naa lo tọrọ aforiji lọwọ awọn ololufe rẹ fun apara ọhun, o si tun fidi rẹ mulẹ pe, iṣẹ tiata ni iṣẹ ti ori ran oun.
Ẹwẹ, April Fool ni apara ti awọn eeyan maa n da ni gbogbo ọjọ kinni, oṣu Kẹrin, ọdọdun, fun ẹfẹ tabi ere ṣiṣe.
Ṣugbọn ọpọ lo ti n bu ẹnu ẹtẹ lu apara naa nitori irufẹ atubọtan to maa n gbẹyin awọn apara miran.
Iroyin ni ọpọ eeyan lo ti dero ileewosan lẹyin ti wọn daku nitori apara April Fool, ti ẉon ro pe o jẹ ootọ.

Muyiwa Ademola kéde ìdí tó ṣe fi iṣẹ́ tíátà sílẹ̀

Oríṣun àwòrán, Instagram/authenticmuy
Gbogbo ẹda lo maa n gbero lati de ibi giga, ti ẹda kii si sinmi titi yoo fi de ibi ọla rẹ.
Bẹẹ ni ọrọ ri pẹlu ilumọọka osere tiata nni, Muyiwa Ademola, ti ọpọ eeyan mọ si Muyi Authentic.
Muyiwa Ademola lo kede loju opo instagram rẹ pe oun ti setan lati dara pọ mọ agbo oselu ilẹ wa, ti oun yoo si gbegbe ibo lọdun 2023.
- Kí ló mú àwọn ẹni ọdún 90 méjì yìí ṣẹ̀ṣẹ̀ máa gbéyàwó lásìkò yìí?
- 'Mo máa tó dìde lórí àìsàn', Muyiwa Ademola sọ̀rọ̀ látorí àkéte àìsàn rẹ̀
- Wo àwọn òṣèré tíátà Yorùbá tó bí ìbejì
- Iṣẹ́ amòfin tí mo kọ́ ni Fáṣítì kò mú owó wọlé fún mi bíi iṣẹ́ tíátà - Femi Adebayo
- Àwọn òṣèré sinimá Yorùbá tó padà lọ sí fásiti lẹ́yìn tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ eré.
Ademola ni oun yoo sinmi fun igba diẹ naa fun ere tiata, ti oun yoo si kọju mọ oselu sise gẹgẹ bo se wa ninu erongba oun lati ọjọ pipẹ wa.

Oríṣun àwòrán, Instagram/authenticmuy
Bakan naa ni ilumọọka osere tiata naa ni oun ti pinnu lati dije fun ipo asofin agba ta mọ si Sẹnetọ ninu idibo gbogbo gboo lọdun 2023.
Ademola ni "Isisẹ sin ọmọniyan ni owo ile to san pe o n gbe ile aye, gẹgẹ bi Muhammed Ali ti wi. Lẹyin o rẹyin, mo ti wa n jade sita bayii lati sisẹ sin orilẹede mi atawọn eeyan mi.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Wo èèwọ̀ tó so mọ́ ọdún Ẹ̀yọ̀, tí obìnrin kìí ti di Sùkú tàbí wé gèlè
- Kí ló dé tí Jaiye Kuti ṣe ń fi omijé ṣe oúnjẹ lọ́pọ̀ ìgbà?
- Agbébọn kọlu Charles Soludo, ọlọ́pàá mẹ́ta dèrò ọ̀run
- Tẹlifísàn pásítọ̀ Oyakhilome wọ gàù nílẹ̀ UK torí òfegè ìròyìn
- Afúrasí darandaran tó pa ènìyàn 15, jó ọ̀pọ̀ dúkìá ni Ebonyi ti bọ́ sí àhámọ́ ọlọ́pàá
- Àbọ̀ ìpàdé Seyi Makinde àtàwọn oríadé l‘Oyo rèé, lórí ààbò tó mẹ́hẹ
Mo n yẹba diẹ na fun isẹ tiata sise lati dije fun ipo Sẹnetọ, ki Ọlọrun ran mi lọwọ.
Ademola ni ilu Ibadan ni oun tẹdo si, fun ọdun mẹtadinlaadọta amọ ọmọ ọba ni oun ni ididle ọba kan nilu Abeokuta nipinlẹ Ogun.

Oríṣun àwòrán, Instagram/authenticmuy
Gbajumọ osere tiata naa wa n beere lọwọ awọn ololufẹ rẹ pe nibo ni wọn lero tabi ti wọn le gba oun nimọran lati dije fun ipo naa.
O ni se ilu Ibadan lo yẹ ki oun ti dije ni abi Abeokuta tii se ilu abinibi oun.
Bẹẹ ba si gbagbe, Ademola lo ti kọkọ beere lọwọ awọn ololufẹ rẹ pe ki wọn sọ orukọ musulumi oun nitori oun ni orukọ abisọ to jẹ ti ẹsin Islam.
Osere tiata naa sisọ loju rẹ pe ọmọ bibi ilu Ilorin ni iya oun, ti baba oun si sọ oun ni Muyiwa Ademola Stephen amọ wọn fun oun ni orukọ Mususlumi.


















