Oyo Police: Irọ́ ní o, kò sí ẹni tó ń dúkòkò mọ́ wá látí fí ọdáràn sílẹ̀

Kọmisọnna ọlọpaa nipinlẹ Oyo, Ngozi Onadeko ti ni, ko si ẹni to n dunkoko mọ awọn lati fi afurasi ọdaran tabi apaniyan to wa ni panpẹ awọn silẹ.
Ninu atẹjade kan ti ileeṣẹ ọlọpaa naa fi sita ni wọn ti bu ẹnu atẹ lu iroyin pe, ileeṣẹ ọlọpaa n ṣe agbatẹru fun awọn ọdaran nipinlẹ Oyo.
Aarẹ Ọna Kakanfo fun ilẹ Yoruba, Iba Gani Adams lasiko ifọrọwerọ rẹ pẹlu BBC News Yoruba, lo fẹsun kan awọn agbofinro pe wọn kọ lati ṣiṣẹ papọ pẹlu awọn araalu.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Gbàjarè! Ọ̀gá ọlọ́pàá fi ìwé ìpè àti géńdé 15 ránṣẹ́ wá mú mi - Sunday Igboho pariwo
- Oluwo, tí wọ́n bá rán ọmọ níṣẹ́ ẹrú, kó fi t'ọmọ jẹ - Gani Adams
- Òkùtà wọ agbe ṣíṣe, alágbe kò rí àánú gbà mọ́, ariwo sọ
- Rògbòdìyàn gbòde lọ́jà Bodija torí aṣọ́bodè tó fi tipá kó àpò ìrẹsì tírélà méje lọ
- Àwọn òṣèré tó ti bàjẹ́ láti ilé, ló kó ìbàjẹ́ wọ agbo tiata débi a'ṣọ ìhòòhò - Dele Odule
- Omijé ẹkún ṣàn níbi ìsìnkú sájẹ́ǹtì ọlọ́pàá táwọn tọ́ọ̀gì òṣèlú pa l'Ekiti
- Wo ohun tí yó ṣẹlẹ̀ sí àwọn tí kò ní nọ́mbà ìbánimọ̀ NIN ní Nàìjíríà
- Awọn Dokita 'NARD' da iṣẹ silẹ lati bere ẹtọ wọn lọwọ ijọba
Bakan naa ni Alaafin tilu Oyo ti ke gbajare sita lasiko to gbalejo Oluwo tilu Iwo pe awọn ọlọpaa ma n tu afurasi ọdaran ti wọn ba fa le wọn lọwọ silẹ.
Gani Adams ni ihuwasi awọn agbofinro fihan pe, wọn ko mu isẹ wọn lọkunkundun lati dẹkun ipenija abo ni ilẹ Yoruba.
O wa sapejuwe bi ọlọpaa se mu mẹta ninu awọn ọmọ ẹgbẹ OPC si ahamọ, lẹyin ti wọn fi panpẹ mu Wakili, afurasi Fulani ti wọn ni o n da awọn eeyan oke Ogun laamu.
Amọ, ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Oyo ni, gbogbo awọn afurasi ti awọn fi panpẹ mu ni awọn ti gbe lọ si ileejọ lati Oṣu Kẹta, ọdun 2021, paapaa awọn ti ẹsun wọn nii ṣe pẹlu ẹsun iditẹ mọ ijọba, ipaniyan, ijinigbe ati ole jija.
Lara awọn ẹsun ti wọn gbe lọ si ileẹjọ ni igbẹjọ laarin kọmisọnna ọlọpaa ati Abdulahi Yakubu Wakili, Kọmisọnna ọlọpaa ati Lawal Oseni ati Aliyu Oseni, pẹlu ti kọmiṣọnna ọlọpaa ati Ayuba Tukur.

Oríṣun àwòrán, Others
''Igbẹjọ Abdulahi Yakubu yoo waye ni ọjọ kẹtadinlogun osu Karun, ti Lawal Oseni ati Aliyu Oseni waye ni ọjọ kọkandinlogun osu Karun nigbati ti Ayuba Tukur yoo bẹrẹ ni ọjọ Kẹrindinlgbọn osu Karun ọdun 2021.''
Kọmisọnna ọlọpaa nipinlẹ Oyo, Ngozi Onadeko ni, o da awọn loju wi pe idajọ otitọ yoo leke ninu gbogbo igbẹjọ to wa ni iwaju awọn.
Nitori naa ileeṣẹ ọlọpaa naa n fi da awọn araalu loju wi pe, awọn n ṣiṣẹ awọn bi iṣẹ lai si ibẹru tabi ifoya.













