Agodi-Gate Fire: Seyi Makinde ṣèlérí ìrànwọ́ fáwọn ọlọ́jà mọ́tò t'íná ṣe ìjànbá fún ọrọ̀ ajé wọn

Agodi Gate fire

Oríṣun àwòrán, Twitter/Seyi Makinde

Gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde ti ṣebẹwọ si ile itaja ẹya ara mọtọ to jona raurau ni agbegbe Agodi Gate, ni Ibadan.

Seyi Makinde ṣe abẹwo si ibẹ lati wo iru ijamba ti ina naa ṣe si agbegbe ọhun, pẹlu awọn oṣiṣẹ ijọba ti wọn tẹle gomina lọ si ibẹ.

Gomina fi aidunnu rẹ han ati ipaya si ijamba to waye ni ọja naa nitori ọpọlọpọ dukia ni wọn padanu ni agbegbe ọhun.

O ni oun yoo ṣepade pẹlu awọn adari ninu ọja yii lati wa ọna abayọ si idojukọ awọn ọlọja nibẹ.

Agodi Gate fire

Oríṣun àwòrán, Twitter/Seyi Makinde

''A o ni gba ki ẹ dojukọ iṣoro yii nikan, maa ran yin lọwọ laipẹ lai jina, ni nkan bi ọṣẹ kan si meji si iṣinyin''.

Agodi Gate fire

Oríṣun àwòrán, Twitter/Seyi Makinde

''Amọ ṣe e ko lero wipe ki a gbe ọja yii lọ si ibomiran ti o tobi daradara, ti yoo fun yin ni aaye lati ṣiṣẹ bo ṣe tọ ati bo ṣe yẹ?''

Agodi Gate Fire

Oríṣun àwòrán, Twitter/Seyi Makinde

Gomina ipinlẹ Oyo naa ni bi awọn yoo ba tilẹ duro ni agbegbe naa, wọn gbọdọ tunkọ, to jẹ pe yoo fi aye gba awọn eniyan, ki iru iṣẹlẹ naa ma ba waye mọ.

Seyi Makinde ni ki awọn adari wọn ninu ọja naa ko ara wọn jọ, ki wọn si wa ni ileeṣẹ ijọba ni Ọjọ Karun, Ọjọ Aje, ọṣẹ yii.

Agodi Gate Fire

Oríṣun àwòrán, Twitter/Seyi Makinde

O ni awọn yoo ma jiroro lori ọna abayọ ati itẹsiwaju awọn ọlọja ti wọn padanu ohun ini wọn naa.

Agodi Gate fire

Oríṣun àwòrán, Twitter/Seyi Makinde

Ti a ko ba gbegbe ni opin ọsẹ ni ariwo ọkun gbalẹ kan lati se itara aje bi ọpọ ọja se n jona ni ọja isọ paati ọkọ to wa ni Agodi Gate, nilu Ibadan.

Agodi Gate fire

Oríṣun àwòrán, Twitter/Seyi Makinde

Bi o tilẹ jẹ pe awọn osisẹ panapana de sibi isẹlẹ naa lati bomi pa ina ọhun amọ o nira fun wsn lati ri ọna de ibi ti awọn ina ọhun ti n jo.

Ẹkún àti ìdárò gbòde bí ọja páàtì ní Agodi-Gate ní Ibadan ṣe jóná mọ́jú

Ọja Gate to jona

Oríṣun àwòrán, Screen Shot

Se ni ariwo ọkun gbalẹ kan, ti ọpọ eeyan si n kawọ lori lati se itara aje nitori bi ọpọ ọja se n jona ni ọja isọ paati ọkọ to wa ni Agodi Gate, nilu Ibadan.

A gbọ pe abala ti wọn ti n ta taya ọkọ ni ina ọhun ti rinlẹ julọ.

Bi o tilẹ jẹ pe awọn osisẹ panapana de sibi isẹlẹ naa lati bomi pa ina ọhun amọ o nira fun wsn lati ri ọna de ibi ti awọn ina ọhun ti n jo.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

A ri gbamu pe ọpọ sọọbu ni wọn ti kọ di awọn oju ọna to yẹ ki ọkọ maa gba laarin ọja naa, eyi to mu ko nira fawọn ọkọ panapana lati ri aaye wọnu ọja.

Ọpọ sọọbu ti awọn ẹya ara ọkọ olowo iyebiye wa lo jona kanlẹ ninu ijamba ina naa to bẹrẹ ni deede aago mọkanla alẹ ọjọ Ẹti.

Ọja Gate to jona

Oríṣun àwòrán, Screen Shot

Titi di akoko yii, awọn alasẹ ko tii mọ ohun to sokunfa ijamba ina naa awọn awọn eeyan kan salaye pe ina ọba ti wọn mu de lojiji lo fa ijamba ina naa.

Iroyin tiẹ fi ye wa pe ọja naa ko ri ina ọba lo fun aimọye ọdun, ki wọn to mu ina pada wa sibẹ.

Ọja Gate to jona

Oríṣun àwòrán, Screen Shot

Ẹnikan ti isẹlẹ naa soju rẹ sọ fawọn akọroyin pe ọjọ pẹ ti iru ijamba ina alagbara bayii ti jo ọja naa gbẹyin.

Amin iyasọtọ kan

Rògbòdìyàn gbòde lọ́jà Bodija torí aṣọ́bodè tó fi tipá kó àpò ìrẹsì tírélà méje lọ

awọn ontaja lọja Bodija

Oríṣun àwòrán, Babalola

Iroyin to n tẹ wa lọwọ ti fidi rẹ mulẹ pe awọn osisẹ asọbode kan ti wọnu ọja Bodija nilu Ibadan laarin oru mọju Ọjọbọ.

Awọn asọbode naa, ni wọn sọ pe wọn gunlẹ sinu ọja ounjẹ naa ni deede aago mejila oru, ti wọn si bẹrẹ si ni fi tipa ja awọn sọọbu to n ta irẹsi.

A o ranti pe ijọba apapọ ilẹ wa ti fi ofin de iwa fayawọ, ti wọn fi n ko irẹsi wọle lati ilẹ okeere.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Nigba ti yoo fi di idaji, awọn osisẹ asọbode naa fi ọja Bodija silẹ pẹlu tirela meje ti apo irẹsi kun inu rẹ.

awọn ontaja lọja Bodija

Oríṣun àwòrán, Babaloja

Nigba to n fi idi isẹlẹ naa mulẹ fun BBC Yoruba, Babalọja fun ipinlẹ Oyo, Alhaji Aderemi Jimoh salaye pe ofifo ni awọn tirela to wọnu ọja Bodija, amọ wọn kun fọfọ fun irẹsi nigba ti wọn yoo fi kuro ni ọja naa.

"Ọpọ sọọbu to n ta irẹsi lawọn asọbode yii ja, to fi mọ tawọn eeyan mi, koda, wọn ko apo irẹsi to to ẹgbẹrun lọna marundinlẹgbẹta 595 ninu sọọbu eeyan mi.

Lẹyin ti wọn ko awọn irẹsi naa tan, wọn tun wa fi agadagodo ti awọn irẹsi wọn ọhun, ti wọn si tun lẹ edidi ileesẹ wọn mọ awọn sọọbu naa lara."

awọn ontaja lọja Bodija

Oríṣun àwòrán, Babaloja

Alhaji Jimoh ni ko si ẹnikẹmi ninu ọja lasiko tawọn asọbode gunlẹ sibẹ loru naa, nigba ti ilẹ mọ, lawọn ontaja irẹsi ri pe ofo ti se awọn.

Lọwọ lọwọ bayii, wọn ko ti le sọ apapọ iye irẹsi tawọn asọbode naa ko lọ tabi iye ti gbogbo owo awọn ọja naa jẹ.

A tiẹ gbọ pe ọpọ awọn on taja naa ni wọn ti ke gbajare lọ si ọọfisi gomina ipinlẹ Oyo, ko le gba wọn ni oko gbese ti wọn jin si ọhun.

Sọọbu

Se ni ọja Bodija kan gbinrin gbinrin loni, tawọn ontaja kan si ti gbe igi da awọn ọna to wọ inu ọja naa pe ko ni si ọja tita kankan rara.