Sunday Igboho: Àwọn ìkọlù sí mi, ilé àti ìyá mi fihàn pé àwọn kan ń dọdẹ mi

Sunday Igboho

Oríṣun àwòrán, sunday_igboho1/Instagram

Eruku ariwo to sọ lana lori bi ajijagbara ọmọ Yoruba nni, Oloye Sunday Igboho se gba iwe ipe lati ọdọ ọga ọlọpa ni ọjọbọ, ko tii lọ silẹ rara.

Koda, ọpọ eeyan lo si n para poro lori isẹlẹ naa, ati ewu ti wọn lo see se ko wa fun ẹmi ajijagbara naa.

Amọ nigba to n salaye lori idi to fi kọ lati gba iwe ipe naa, to ni awọn gende ọlọpaa mẹẹdogun mu wa sile ohun, Sunday Igboho ni ọrọ naa gbero ni.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Agbẹnusọ fun Igboho, Olayomi Koiki salaye pe iriri to ti waye lati ẹyin wa nilẹ Naijiria lo mu ki awọn ẹsọ ajijagbara naa kọ lati gba lẹta ipe ọhun.

Àkọlé fídíò, Sunday Igboho latest: Sunday Igboho kò gba 'Award'ti a fún un ní Ogo Yorùbá nítorí inú rẹ̀

"Bẹẹ ba gbagbe, lẹta ni wọn wọn mu wa sile Dele Giwa lọdun 1986, to di bọnbu to bu kẹu, eyi to ran gbajumọ akọroyin naa sọrun ọsangangan."

Bakan naa lo fikun pe awọn isẹlẹ afunilara to n waye ni ayika ajijagbara naa to fura si pe wọn n dọdẹ rẹ loju mejeeji.

"Abi ki ni ka ti sọ ti ina ti awọn ọbayejẹ kan sọ si ile Igboho ladugbo Soka nilu Ibadan losu diẹ sẹyin, tawọn osisẹ alaabo to wa ninu asọ Khaki naa si tun da lọna lasiko to n lọ silu Eko."

Àkọlé fídíò, Pure Water Lylon Art: Adejoke ní ohun èlò ta fi ọ̀rá ṣe ń ní àlòpẹ́, kìí tètè jẹ

Ko tan sibẹ, Koiki fikun pe awọn afurasi Fulani kan tun kọlu ile Sunday Igboho lọsẹ diẹ sẹyin, tawọn gende kan to wọ asọ ologun naa si tun wa tọpinpin ile rẹ."

Koiki ni oye lagba n wo, ifura si ni oogun agba, tawọn gende agbofinro ba wa tun mu lẹta wa lati ọdọ ọga agba ọlapaa, eyi to mu ifura lọwọ.

Amin iyasọtọ kan

Gbàjarè! Ọ̀gá ọlọ́pàá fi ìwé ìpè àti géńdé 15 ránṣẹ́ wá mú mi - Sunday Igboho pariwo

Sunday Igboho

Oríṣun àwòrán, Instagram/SundayIgboho

Ajijangbara ati ajafẹtọmọniyan, Sunday Igboho ti ke gbajare si awọn araalu pe ijọba Naijiria n gbiyanju lati fi panpẹ ofin mu oun ni bonkẹlẹ.

Agbẹnusọ fun Sunday Igboho, Olayomi Koiki lo fi ọrọ naa lede ninu atẹjade kan to fisita loju opo Facebook rẹ.

Koiki ni "a fẹ fi to gbogbo araye atawọn ọmọ Naijiria leti pe, ọga agba ọlọpaa fi lẹta kan ranṣẹ si Sunday Igboho, ṣugbọn awọn ẹsọ alabo rẹ kọ lati gba lẹta naa."

O fikun pe Ọjọbọ, Ọjọ Kini, Osu Kẹrin, ọdun 2021 ni wọn mu lẹta naa wa sile Igboho lati ipasẹ ileesẹ igbalode afiweransẹ DHL.

Agbẹnusọ fun Igboho tun salaye pe, awọn ọkunrin mẹfa kan ti wọn pe ara wọn ni ọlọpaa ṣugbọn ti wọn ko wọ aṣọ isẹ, atawọn mẹsan an miran

gunlẹ sile Igboho ni deede aago mẹta ọsan Ọjọbọ naa.

Atẹjade ti Sunday Igboho fisita

Oríṣun àwòrán, Koiki Media

Koiki ni mọto Corolla ni wọn gbe wa sile ajafẹtọ ilu naa, ti wọn si sọ fawọn ẹsọ ile naa pe awọn fẹ ri oloye igboho."

Koiki ṣalaye pe awọn gende ọhun sọ pe ọdọ ọga agba fun ileeṣẹ ọlọpaa Najiria ni awọn ti wa pẹlu lẹta kan lọwọ wọn, ti wọn kọ orukọ Sunday Igboho si lara.

Wọn ni ọga agba ọlọpaa lo ni kawọn fun ni lẹta naa amọ sibẹ ikọ alaabo Sunday Igboho ko tẹwọ gba lẹta ọhun.

Agbẹnusọ fun ajijagbara naa wa n beere ninu atẹjade naa pe Sunday Igboho yoo nifẹ lati mọ idi ti ọga agba yanyan fun ileeṣẹ ọlọpaa yoo ṣe fi iwe pe oun.

Igboho ni ti wọn ba tilẹ fẹ fi iwe pe oun gan, o yẹ ki wọn kọkọ fi iwe pe gbogbo awọn janduku ajinigbe atawọn ọmọ ẹgbẹ Boko Haram, to n da

alaafia Naijiria laamu lati ọjọ yii wa.

Àkọlé fídíò, Sunday Igboho fulani ultimatum: Àwọn ará Kebbi àti Zamfara ló n jínígbé ní Oke Ogun- Serik

Igboho fi kun pe, ti ọga agba ileeṣẹ ọlọpaa ba fẹ ri, n ṣe lo yẹ ko kede nita gbangba dipo ko maa fiwe ipe ranṣẹ si oun nikọkọ.

Koiki pari ọrọ rẹ pe, fifi lẹta ranṣẹ si Igboho ko jẹ itẹwọgba awọn rara, nitori pe, bẹẹ ni ijọba Naijiria ṣe fi lẹta ranṣẹ si ọmọ Yoruba kan ri ni ọpọ

ọdun sẹyin, iyẹn Dele Giwa, eyii to mu ẹmi rẹ lọ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

siluu Eko, lagbegbe Guru Maraji, ṣugbọn ti wọn mu ofo.