Ekiti Assembly election violence: Omijé ẹkún ṣàn níbi ìsìnkú sájẹ́ǹtì ọlọ́pàá táwọn tọ́ọ̀gì òṣèlú pa l'Ekiti

Wọn ti sin oku obinrin ọlọpaa ti awọn janduku ṣekupa lasiko atundi ibo sile aṣofin to waye ni ipinlẹ Ekiti lọjọ Satide to kọja.
Arabinrin ọlọpaa naa ti orukọ rẹ n jẹ Bukọla Ọlawoye-Ogundeji wa lara awọn eeyam mẹrin tawọn janduku oṣelu pa lasiko atundi ibo naa ni Omuo Ekiti.
Ile rẹ ni ilu Ikẹrẹ Ekiti ni wọn sin in si.
Ọkọ rẹ, Ignatius Ogundeji ati ẹgbọn rẹ, lalekan Ọlawoye daro iku rẹ ti wọn si rọ ileeṣẹ ọlọpaa lati ṣe eto to ts fun itọju ati amojuto ẹkọ awọn ọmọ ti oloogbe naa fi silẹ.

Arabinrin Alice Ẹlẹmọṣọ to mu bi iya pẹlu Ọmọlayọ Ọlawoye to jẹ iya rẹ gangan ṣalaye pẹlu omije loju pe olu smọ awsn ni wọn padanu naa.
Kọmiṣọna ọlọpaa ni ipinlẹ Ekiti, Tunde Mobayo ranṣẹ si ibi isinku naa pẹlu ileri pe ileeṣẹ ọlọpaa ati ijsba ipinlẹ Ekiti yoo kede awsn ẹtọ to wa nikalẹ fun awọn ọms oloogbe naa atawọn obi rẹ.

ọmọ ọdun mẹtalelọgbọn ni arabinrin ọlọpaa Bukọla Ọlawoye-Ogundeji, Sajẹnti si ni ipo rẹ ki o to pade iku rẹ lsiko to lọ mojuto eto idibo si ile aṣofin ipinlẹ naa ni ogunjọ oṣu kẹta ọdun 2021.








