Doctors strike: Awọn Dokita 'NARD' da iṣẹ silẹ lati bere ẹtọ wọn lọwọ ijọba

Lonii ni ẹgbẹ awọn Dokita nile iwosan nla to jẹ tijọba, 'National Association of Resident Doctors of Nigeria', NARD jakejado orilẹede Naijiria gunlẹ iyanṣẹlodi lẹyin gbogbo ipade ti wọn ṣe pẹlu ijọba apapọ.
Awọn aṣoju ẹgbẹ naa ṣe alaye wi pe ikuna ijọba apapọ lori i gbogbo adẹhun ti o ṣe fun awọn Dokita naa lo ṣe okunfa iyanṣẹlodi ti wọn gunle.
Wọn ni gbedeke ti wọn fun ijọba tẹlẹri lati dahun awọn ibeere wọn ni ọjọ kọkanlelọgbọn oṣu kẹta ọdun, ṣugbọn ọjọ naa ti rekọja lọ lai gbọ nnkan kan lati ọdọ ijọba.
- Oluwo, tí wọ́n bá rán ọmọ níṣẹ́ ẹrú, kó fi t'ọmọ jẹ - Gani Adams
- Rògbòdìyàn gbòde lọ́jà Bodija torí aṣọ́bodè tó fi tipá kó àpò ìrẹsì tírélà méje lọ
- Àwọn òṣèré tó ti bàjẹ́ láti ilé, ló kó ìbàjẹ́ wọ agbo tiata débi a'ṣọ ìhòòhò - Dele Odule
- Wo nọ́mbà ìpè pàjáwìrì tíjọba Oyo fi síta fún ẹni tó bá wà nínú ewu
Lara awọn nnkan ti awọn Dokita naa n beere fun ni pe ki ijọba san gbogbo owo oṣu ati ajẹmọnu wọn, atungbeyẹwo owo iṣẹlẹ pajawiri kuro ni ẹgbẹrun marun un naira ti o wa bayii, sisan ajẹmọnu owo itọju aarun COVID-19
ati awọn ajẹmọnu to ni i ṣe pẹlu awọn ile ẹkọ giga ti o jẹ ti ijọba.Awọn Dokita ti o jẹ ọmọ ẹgbẹ naa nile iwosan UCH ilẹ Ibadan naa darapọ mọ awọn akẹgbẹ jakejado orilẹede Naijiria ninu iyanṣẹlodi to bẹrẹ lonii.

BBC Yoruba ṣe abẹwọ si ile iwosan nla fasiti ilẹ Ibadan, UCH lowurọ oni, paroparo sini ọfisi awọn Dokita naa da.
Botilẹ jẹ wi pe pupọ ninu awọn alaisan to n bẹ ninu ọgba ile iwosan naa ko ti i ni imọlara iyanṣẹlodi naa, ohun ti o ṣeeṣe ni pe ki wọn bẹrẹ sini ke irora bi iyanṣẹlodi naa ba pẹ ju botiyẹ lọ.
Adari ẹgbẹ Dokita nile Iwosan UCH, Dr Zakariyau Temitope Hussein ṣe alaye fun akọroyin wa wi pe iyanṣẹlodi ti o bẹrẹ lonii ko ti i ni ọjọ ti yoo pari nitori ki iyanṣẹlodi naa to bẹrẹ ni ijọba ti mọ gbogbo ohun ti wọn n beere
fun lati ọdun kan sẹyin.

O ni, "Nile le iwosan UCH nikan, awọn Dokita ti ijọba jẹ lowo to ọọdunrunlelaadọrin(370). Nitori wọn naa ni a fi n ṣe iyanṣẹlodi".
O ni ọjọ ti ijọba ba da wọn lohun gbogbo nnkan ti wọn n beere fun ki iyanṣẹlodi naa to wa si opin.

Awọn nnkan ti awọn alakoso ẹgbẹ awọn Dokita naa fi ẹnu ko lati beere fun ni;
Ki gbogbo owo ati ajẹmọnu ti ijọba jẹ awọn ọmọ ẹgbẹ naa di sisan, atungbeyẹwo owo iṣẹlẹ pajawiri and sisan owo itọju aarun COVID-19 sisan ajẹmọnu ọdun 2014-2016.












