Sunday Igboho latest: Sunday Igboho kò gba 'Award' ti a fún un ní Ogo Yorùbá nítorí inú rẹ̀ kò dún sóhun tó ń ṣẹlẹ̀ sí ìran Yorùbá
To ba buru ju, Wale máa bọ ni Ibadan- Sunday Igboho ati awọn eeyan rẹ
Ogbeni Wale Adeoba ti ọpọ mọ si Mr Packaging ti kan si BBC Yoruba.
O ke gbajare sita pé oun n gba awọn ipe oriṣirisi to n dẹru ba ni lasiko yii lẹyin igba ti oun ti ṣe oludari eto Ogo Yoruba ti oun ṣe gbẹyin.
O fidi ẹ mulẹ pe Oloye Sunday Adeyemo ti ọpọ mọ si Sunday Igboho gan an ti ọrọ kan ko wa gba ami ẹyẹ ọmọ Yoruba to n ṣe daadaa ti Ogo Yoruba fẹ fun un.
O ni lati igba ti oun ti ṣeto naa tan ni orisiirisii wahala ti n ṣẹlẹ si oun bii ki awọn kan ti oun ko mọ ri deedee wa oun wa si ile.
- Wo ohun tí Professor Peller wí tó kó bá a tí wọ́n fi rí i pa, ìyàwó rẹ̀, Lady Peller tú u síta
- Ilé ẹjọ́ tú ìgbéyàwó ọlọ́mọ mẹ́jọ ká nítorí pé ọkọ rí àwọn òbí ìyàwó fín
- Wo ìgbésẹ̀ tí àwọn lọ́balọ́ba, ọlọ́pàá àti Seyi Makinde fẹ́ gbé lórí áàwọ Ibarapa
- Sunday Igboho wà lọ́nà Ibarapa, Seriki Fulani ní àwọn kó níbiì lọ, àrọ̀wà ló kù fúnwà
- Sunday Igboho yarí, ó fohùn ránsẹ́ sáwọn èèyàn tó ń pẹ̀gàn rẹ̀
- Ògo ilẹ̀ Yorùbá ní Sunday Igboho jẹ́, ẹ́ kò gbọdọ̀ jẹ́ kí ìràwọ rẹ̀ wọlẹ̀ - OPC
- Báyìí ni àwa àti Sunday Igboho ṣe rìnrìn àjò láti Ibadan lọ sí Igangan"
- Orí mi wú báwọn oríadé ṣe ní kò sí ààyè mọ́ láfi fi ọmọ Yorùbá ṣètùtù Nàìjíríà - Sunday Igboho
- Ìfẹ́ Yorùbá ló mú mi fi ẹ̀mí wéwu láti kojú ajínigbé ní Kishi - Sunday Igboho
Wale Adeoba to jẹ agbatẹru eto ifami ẹyẹ dani lọla Ogo Yoruba ni Ibadan ni awọn miran a pe oun ni ipe ijaya ti ẹru si n ba oun ki nkankan ma lọ ṣẹlẹ si oun laida.
O ni Koda, Oloye Sunday Igboho ko gba ami ẹyẹ naa nitori pe inu rẹ ko dun si ohun to n ṣẹlẹ si iran Yoruba lasiko yii ṣugbọn o wa sibi eto naa lati yẹ iran Yoruba si ni.
Bakan naa ni Wale Adeoba salaye pe Sunday Igboho ko lo eto naa lati fi ba ẹnikeni jẹ tabi tabuku oloselu kankan.
O salaye idi ti wọn ṣe gbe eto Ogo Yoruba Award ka lẹ fun idagbasoke iran Yoruba ati igbelarugẹ ede ati aṣa Yoruba ni.
Bẹẹ, Sunday Igboho ti ni to ba buruju ki oun maa bọ ni Ibadan ati pe oun ko tii fi to awọn agbofinro leti nigba ti BBC beere pe ki lo de, o ni ẹru n ba oun ni.
Wale Adeoba, Mr Packaging sọ ohun to ṣẹlẹ gangan nibi eto naa ati abajade rẹ bayii.
E gbọ ohun to sọ funra rẹ ninu fọnran oke yii.
- Wo ibi tí o ti lè fi orúkọ síìmù rẹ sílẹ̀ tàbí gba nọ́mbà tuntun tí síìmù rẹ bá sọnù
- Àwọn ará abúlé kan ṣàwàrì àlùmọ́ọ́nì gòólù ní wọ́n bá kígbe síta ní Ọlọ̀pàá bá yi wọn ká!
- Àwọn ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa Sadiq Daba 'Inspector Waziri' nínú sinimá October 1 tó jáde láyé rèé
- Báwo ní Ọba Rilwan Akiolu tí ìlú Eko ṣe ní $2 million àti N17 million sí inú àfin rẹ̀?
- Ewé atòó, eegun ẹranko àti ǹkan mìí ní Yorùbá fi ń to egungun tó kán- Adimula Akinfenwa Topátosẹ̀





