Muhammadu Buhari: Ọ̀pọ̀ ọmọ Naijiria ló ń jìyà nítorí ìwà àjẹbánu tó wà ní ẹ̀ka ètò ìlera - SERAP

Buhari

Oríṣun àwòrán, @TheresaTekenah

Ajọ to n ja fun ẹtọ ọmọniyan nidi ọrọ aje ati ijiyin isẹ iriju ẹni, SERAP, ti pe Aarẹ Muhhamadu Buhari lẹjọ lori ikuna rẹ lati ṣe iwadii owo to le ni biliọnu mẹta abọ naira ti wọn la kalẹ fun ẹka eto ilera to poora.

SERAP ni owo naa ti iye rẹ jẹ ₦3,836,685,213.13 ni wọn la kalẹ fun ileeṣẹ to n ri si eto ilera, awọn ile iwosan ijọba, awọn ile ẹkọ ẹkọṣẹ iṣegun ati ajọ to n mojuto lilo ati akoso ounjẹ ati oogun ni Naijiria, NAFDAC.

Ninu atẹjade kan ti ajọ naa fi lede, eyii ti igbakeji adari rẹ, Kolawole Oluwadare buwọlu, o ni awọn n pe Aarẹ lẹjọ lẹyin ti abajade iwadii ti ọọfisi akapo agba Naijiri ṣe fi han pe owo naa ti poora.

Ipẹjọ yii lo n waye lẹyin ti ẹgbẹ awọn dokita ni Naijiria gunle iyanṣelodi lori owo oṣu ti ijọba jẹ wọn, awọn ajẹmọnu to yẹ ki wọn gba lasiko ajakalẹ arun Covid-19, atawọn ajẹmọnu miran.

SERAP n fẹ ki ile ẹjọ kan an nipa fun Aarẹ Buhari lati ṣe iwadii bi owo naa ṣe rin.

Buhari

Oríṣun àwòrán, @festusdada1

Bakan naa ni SERAP tun n fẹ ki ijọba apapọ ṣe ọfintoto iwa ajẹbanu ti wọn sọ pe o n waye lawọn ile iwosan ijọba, awọn ile ẹkọ ẹkọṣẹ iṣegun ati ni ajọ NAFDAC.

Àkọlé fídíò, Mobile Wash: iṣẹ́ fífọ́ mọ́tò tà ni mó yàn láààyò- Slay Mama

Ajọ naa sọ pe awọn ọmọ Naijiria ti ko rọwọ họri n jiya nitori iwa ajẹbanu to sodo si ẹka eto ilera.

Wọn ko tii sọ ọjọ ti igbẹjọ naa yoo bẹrẹ.

Bi ẹ ko ba gbagbe, Aarẹ Muhammadu Buhari wa niluu London nibi to ti lọ gba itọju.

Ọpọ ọmọ Naijiria lo si ti n fi erongba wọn lede lori ipinnu Aarẹ lati lọ ṣayẹwo ara rẹ niluu London lasiko ti awọn dokita gunle iyanṣelodi ni Naijiria.

Àkọlé fídíò, Pure Water Lylon Art: Adejoke ní ohun èlò ta fi ọ̀rá ṣe ń ní àlòpẹ́, kìí tètè jẹ