Coronavirus doctor's diary: Ìtàn àwọn arúgbó ẹni àádọ́rùn ún ọdún méjì tó di lọ́kọ-láyà lẹ́yìn ìbáṣepọ̀ ọgbọ̀n ọdún

Trevor Hirst ati Lily Abbot

Eto gbigba abẹrẹ ajẹsara COVID-19 ti bẹrẹ ni orilẹede Gẹẹsi. Awọn arugbo ti ọjọ ori wọn ti ju ọgọrun ọdun lọ atawọn oṣiṣẹ eto ilera ni wọn kọkọ n gba abẹẹrẹ ajẹsara naa fun.

Awọn arugbo meji kan ti wọn maa n ba ara wọn jo ki wọn to di lọkọlaya bayii lẹni aadọrun ọdun wa lara awọn ti wọn kọkọ pese abẹrẹ ajẹsara naa fun ni ilu Bradford nibi ti Dokita John Wright ti ileewosan Ọba Bradforford Royal Infirmary ti gbọ nipa wọn.

Awọn mejeeji yii pade ni ibudo ijo kan ni ọgbọn ọdun sẹyin nibi ti wọn ti di ọrẹ ti wọn si jumọ n rinrin ajo lọ sawọn ode ijo kaakiri pẹlu awọn ọkọ ati iyawo wọn nigba naa.

Trevor Hirst ati Lily Abbot ni orukọ awọn mejeeji yii.

Trevour padanu iyawo rẹ, Rita ni ọdun mẹfa sẹyin, Lily pẹlu padanu ọkọ rẹ ni ọdun 2006 lẹyin igbeyawo ọdun marundinlọgọta.

Àkọlé fídíò, 'Mo kàn máa ń lọ́ ayẹyẹ kiri torí ijó láì ṣe pé wọ́n pe mí ló sọ mí di DJ olórin Fuji nìkan'

Ọdun 2020 yii ni awọn mejeeji yii pe ẹni aadọrun ọdun bi o tilẹ jẹ wipe Lily fi ọjọ mẹfa ju Trevor lọ, a maa pe e ni "Toy boy" o ni iyẹn tumọ si ọmọ iṣere oun.

Fun ọpọlọpọ ọdun ni wọn fi n da gbe lọtọọtọ ti awọn ọrẹ wọn si n rọ wọn lati kuku maa gbe pọ gẹgẹ bii tọkọtaya.

Lily ni idahun oun ni ọpọ igba ni pe ko si idi fun igbepọ awọn nitori awọn mejeeji ti fi igba kan ri igbeyawo nitori naa wọn ko nilo igbayawo miran mọ. Awọn mejeeji yii ni wọn si ti ni ọmọ-ọmọ ati ọmọ-ọmọ-ọmọ.