Charles Soludo: Àwọn agbébọn kójú ìjà sí gómìnà Bánkì àpapọ̀ tẹ́lẹ̀rí, wọ́n pa ẹṣọ́ rẹ̀ mẹ́ta

Oríṣun àwòrán, Nigeria Police
Gómínà Bánkì àpapọ̀ Nàìjíríà (CBN) tẹ́lẹ̀ rí ọ̀jọ̀gbọ́n Charles Soludo tó n pinu láti dupò gómìnà ìpínlẹ̀ Anambra tí yóò wáye nínú oṣù kọkànlá ọdún yìí, ní àwọn agbébọ̀n gbìyànjú láti kọlù lọ́jọ́rú.
Gẹ́gẹ́ bí àtẹ̀jáde tí kọ́mísọnà ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Anambra Monday Bala Kuryas fọwọ́sí, ó fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé, ọlọ́pàá mẹ́ta tí wọ́n jọ fìjà pẹ́ẹta lásìkò náà padà jẹ́ ọlọ́run nípe, tí wọ́n sì tí gbé òkú wọ́n sí ilé ìkókù sí nílé ìwòsàn
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Wo èèwọ̀ tó so mọ́ ọdún Ẹ̀yọ̀, tí obìnrin kìí ti di Sùkú tàbí wé gèlè
- Tẹlifísàn pásítọ̀ Oyakhilome wọ gàù nílẹ̀ UK torí òfegè ìròyìn
- Afúrasí darandaran tó pa ènìyàn 15, jó ọ̀pọ̀ dúkìá ni Ebonyi ti bọ́ sí àhámọ́ ọlọ́pàá
- Àbọ̀ ìpàdé Seyi Makinde àtàwọn oríadé l‘Oyo rèé, lórí ààbò tó mẹ́hẹ
- Wo àbọ̀ ìwádìí Amẹ́ríkà lórí ìkọlù ológun tó wáyé ní Lekki
- Àwọn tí àkóso ìjọba bọ́ lọ́wọ́ wọn ló ń ti Igboho lẹ́yìn lórí ìdásílẹ̀ Oodua Nation - YWG
- Kí ló dé tí Jaiye Kuti ṣe ń fi omijé ṣe oúnjẹ lọ́pọ̀ ìgbà?
- "Nǹkan tó lé pa màálù 30 lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo lé pa ènìyàn, ẹ̀yin àrá Ondo, ewu ńbẹ"
- Àwọn agbébọn pa ọ̀pọ̀ ọlọ́pàá, ṣọ́jà, wọ́n tún jó ọ̀pọ̀ ọkọ̀ ní Akwa Ibom
Bákan náà ni àtẹ̀jáde fi yéní pé, ọwọ́ sìnkún ọlọ́pàá tí tẹ ẹnikan to níṣe pẹ̀lú ìṣẹ̀lẹ̀ náà, sùgbọ́n wọ́n jí ẹnikan ti wọ́n pè ni onímọ̀-ẹ̀rọ Emeka Ezenwanne tó jẹ́ kọmísọnà ètò ìpèsè amáyédẹrùn gbé lásìkò ìṣẹ̀lẹ̀ náà.
Ó ṣeéṣe kí ìṣẹ̀lẹ̀ náà níṣe pẹ̀lú ọ̀rọ̀ òṣèlú
Soludo tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tó n pète láti díje du ìpo gómìnà nípìnlẹ̀ Anambra, àwọn ẹgbẹ́ kan sì ti ni ó ṣeeṣe kí àwọn olóṣélú máa gbìyànjú láti mú kúrò lọ́nà.
Àjọ INEC tí ṣàgbékalẹ̀ pé ọjọ́ kẹfà oṣù kọkànlá ọdún, 2021 ní ètò ìdìbò ìpínlẹ̀ Anambra yóò wáyé.
"Ǹkan tó ṣẹlẹ̀ sí Soludo ni ọwọ́ òṣèlú nínú ni, ìpinu wọ́n si ni láti da omí tútù sí lọ́kan àti àwọn alátìlẹ́yìn rẹ̀ sáájú àsìkò ìdìbò," èyí jẹ́ ọ̀rọ̀ tí Chinedu Nwoye Glamour tó jẹ́ alága àwọn alátilẹ̀yin fdún Soludo sọ fún BBC

Oríṣun àwòrán, Police
Glamour ni "ìṣẹ̀lẹ̀ náà tó wáye láàrín ààgo mẹ́rin sí aagọ márùn-ún ìrọ̀lẹ́ lẹ́yin ti Soludo ti pari ìfikùlùkù tó bá lọ sí ìlú Isuofia ní ìjọba ìbílẹ̀ Aguata nípìnlẹ̀ náà. Àwọn ẹ̀sọ́ àbò tó n gbìyànjú láti takò wọ́n ni wọ́n kú tí wọ́n sì tún jí ẹni kan gbé.
"Àwọn ọlọ́pàá ń mójú tó ọ̀rọ̀ náà à sì ni ìgbàgbọ́ pé wọ́n yóò mọ àwọn tó ṣe iṣẹ́ ibi náà."
Kò tíi sí ẹnikẹni tó jáde wá láti sọ pé, àwọn làwọ́n wà nídìí ọ̀rọ̀ náà, sùgban èyí tún sẹlẹ̀ láàrin àsìkò tí àwọn agbébọ̀n ń pa ọlọ́pàá ní ẹkùn ìhà gúúsù-ìlà-oorùn.
Láìpẹ́ yìí ni ọlọ́pàá fojú àwọn ọ̀daràn mẹ́rìndínlógún hàn lẹ́yìn tí wan mú wọn ni oníruuru ibi ìṣẹ̀lẹ̀ ni ẹkùn náà tí wọ́n sì fi ẹ̀sùn kàn wọ́n pé wọ́n wọ́n da ojú ìjà kọ àwọn àga ọlọ́pàá tí wọ́n sì pa ọ̀ps ọlọ́paàá pẹ̀lú.
Tani Chukwuma Soludo?
Ọ̀jọ̀gbọ́n Charles Chukuwuma Soludo jẹ́ gómìnà Bánkì àpapọ̀ Nàìjíríà tẹ́lẹ̀ rí.
Ó jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ gbọye ìmọ̀ ètò ọ̀rọ̀ ajé ni fásítì Nàìjíríà Nsukka.
Ó ti ṣiṣẹ́ pẹ̀lú bánkì àgbáyé rí ni ọdún 1993
Sáájú ni Soludo ti kọ́kọ́ ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ìjọba Obasanjo gẹ́gẹ́ bi olùbádámọ̀ràn lórí ètò ọ̀rọ̀ ajé àti alákòso nípa ètò ìlú.
Ní ọdún 2019 ààrẹ Muhammadu Buhbari yan Soludo gẹ́gẹ́ bi ọ̀kan nínú ọmọ ẹgbẹ́ ìgbìmọ̀ olùbádámọ̀ràn (EAC) lórí ètò ọ̀rọ̀ ajé Nàìjíríà
Ní ọdún 2009, ó jáde dupò gómìnà ní ìpínlẹ̀ Anambra lábẹ́ ẹgbẹ́ òṣèlú People's Democratic Party, tí Peter Obi ti All Progressive Grand Alliance (APGA)
Ìròyìn sọ pé ó tún ti kéde pé òun yóò dupò gómìnà lábẹ́ ẹgbk òṣèlú APGA lọ́dún yìí.












