Ire Poly Student: Akẹ́kọ̀ọ́ Poly kú l'Osun "lẹ́yìn tó ti ilé ọ̀rẹ́kùnrin rẹ̀ dé

Awọn akẹkọ Osun Poly to n kawe

Oríṣun àwòrán, Osunpoly

Iroyin to tẹ wa lọwọ lati ipinlẹ Osun sọ pe akẹkọọbinrin kan nile ẹkọ gíga gbogbonṣe to wa ni ilu Iree ti dero ọrun, lẹyin to ṣe abẹwo sí ile ọrẹkunrin rẹ.

Akẹkọọ naa ti wọn pe orukọ ni Wumi, ni a gbọ pe o bẹrẹ si ni pọ ẹjẹ ati itọ lẹnu lẹyin to pada de lati ile ọrẹkunrin rẹ.

Iroyin sọ pe wọn gbe akẹkọọ naa digba digba lọ si ile iwosan to wa nitosi amọ ile iwosan ko gba a nigba ti wọn ri bi o ṣe n ṣe.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Wumi ni a gbọ wí pe o jẹ Ọlọrun nipe ni irọlẹ ọjọ Abamẹta to kọja, ki wọn to gbe e dé ile iwosan mii.

Agbẹnusọ ile ẹkọ giga gbogbonṣe ilu Iree, Tope Abiola to fidi iṣẹlẹ ọhun múlẹ ṣalaye pe ọrẹkunrin akẹkọọ naa kii ṣe ọmọ ile ẹkọ ọhun.

Àkọlé fídíò, Olugbon Twins: Ọba Alao àti Olorì rẹ̀ bí ìbejì lẹ́yìn tí nǹkan oṣù ti dúró lẹ́ni ọdún 53

Ọgbẹni Abiola ṣalaye pe ko sí ẹni to mọ ohun to ṣe okunfa iku ọmọbinrin naa titi di akoko yii.

O ni ileeṣẹ ọlọpaa si n ṣe iwadii lori iṣẹlẹ naa.

Ọgbẹni Abiola ni ipele akọkọ (ND 1) ni akẹkọọ naa wa nibi to ti n kẹkọọ nipa iṣẹ akọroyin.

Ṣugbọn akẹkọọ kan to ba awọn akọroyin sọrọ fidi rẹ múlẹ pe ọmọ ile ẹkọ naa ni ọrẹkunrin rẹ n ṣe.

Akẹkọọ ọhun fikun ọrọ rẹ pé awọn ọlọpaa ti mu ọrẹkunkunrin Wumi lẹyin iku rẹ.

O ni wọn ti gbe oku Wumi lọ sí mọṣuari niluu Ikirun bayii.

Ẹwẹ, agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Osun, Yemisi Opalola ni iwadii ti bẹrẹ lori iṣẹlẹ naa.

Àkọlé fídíò, Sunday Igboho Aide: Omiyale ni DSS rọ̀jọ̀ ibọn sí Igboho, wọ́n wá pa ni àmọ́ ó bọ́