Mesach Oyediran: Ọba ni Dafidi tó ń lu dùùrù, tó sì kọ sáàmù, ta ni èmi tí kò ní le yin
Ọpọ oriade nilẹ Yoruba ni maa n pe ara ni ọlọrun kekere, alasẹ igbakeji orisa, bẹẹ ni wsn kii fi oribalẹ fun ẹnikan.
Amọ ọba alaye kan ree to n fi ori ade tẹ duuru nile ijọsin lai boju wẹyin.
Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ lori idi to se n tẹsiwaju lati maa tẹ duuru nile Ijọsin, Ọba Mesach Oyediran tii se Olulalokun tilu Yakoyo ni oun n fi ọwọ oun yin Ọlọrun logo ni.
- Kàyèéfì! Mo ní àrùn jẹjẹrẹ tẹ́lẹ̀ àmọ mo bí ìbejì lẹ́yìn tí nǹkan oṣù ti dúró - Olorì Olugbon
- A kìlọ̀ fún Sunday Igboho pé kó dákẹ́ àmọ́ kò gbọ́, èébú ló ń bú wa - Ooni Ife
- Ìjọba, ẹ forí jin Sunday Igboho láì wo irú ẹ̀ṣẹ̀ tó le ṣẹ̀ yín - Olota ti Ota
- Kìí ṣe nítorí mi ò ṣ'ètùtù ni olorì méjì ṣe kú, àsìkò wọn ló tó- Oba Onpetu
- Buhari tí mo mọ̀ ní 1983 kọ́ ló wà nípò, mò ń ‘doubt’ rẹ̀ - Olugbon
- Ìjọba mọ̀ pé àwọn Fulani ń wa góòlù ní Owo láì ṣe nǹkan kan si - Olowo
- Alao Akala ló da ìgbìmọ̀ lọ́balọ́ba Oyo rú, àwa ọba kò jìjà àgbà - Onpetu Ijeru
- Ọlọ́run fi ẹ̀mí Sunday Igboho ta gbogbo àwa tókù jí ni, ọ̀rọ̀ yìí ti kọjá ìsòpọ̀ Nàìjíríà - Oba Gbolahan Shomolu
Ọba Oyediran ni ọdun mejidinlọgbọn niyi ti oun ti n lu duuru, baba oun tii se alufa si lo se iwuri isẹ naa fun oun.
Oriade naa ni ọpọ ọrẹ oun lo ti n fapa janu pe o yẹ ki oun ti dẹkun titẹ duuru ni sọọsi gẹgẹ bi ọba alaye amọ ti oun ko da wọn lohun.
O ni ọba naa ni Dafidi to fi n tẹ duuru, to si kọ saamu, ta wa ni oun ti ko ni le tẹsiwaju lati maa fi ọwọ oun yin Ọlọrun logo nitori pe oun jẹ ọba.




