Babatunde Olatunji: Alùlùgbayì ọmọ Nàìjíríà tó fìlù kojú ìdẹ́yẹsí ní Amẹ́ríkà

Babatunde Ọlatunji ni ẹnu iṣẹ ilu lilu

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ọdun mẹta ṣaaju igbesẹ Rosa Parks lati fẹhonu han ninu bọọsi akero gẹgẹ bi ara ọna ẹhonu tako idẹyẹsi awọn alawọ dudu, alulugbayi ọmọ Naijiria nni, Babatunde Ọlatunji naa ti fẹhonu han tako idẹyẹsi ẹlẹyamẹya lẹkun guusu orilẹede Amẹrika. O jẹ ọkan lara awọn iran adulawọ akọkọ to ko ipa manigbagbe ninu titako idẹyẹsi ẹlẹyamẹya lorilẹede Amẹrika- to si tun tẹsiwaju lati maa ṣe bẹẹ ti doni.

"Awọn aṣiwaju lawọn ọdun 1950 si 1969 fun mi ọpọlọpọ iwuri," Ajafẹtọ ọmọniyan Opal Tometi, to jẹ ọkan lara awọn oludasilẹ ẹgbẹ Black Lives Matter movement lo ṣalaye bẹẹ fun BBC.

Nigba ti Martin Luther King Jr ka ọrọ apilẹkọ manigbagbe rẹ to pe akori rẹ ni Mo ni ala rere (I have a dream) lasiko iwọde to waye ni ilu Washington lọdun mẹtadinlọgọta sẹyin, ẹgbẹrun lọna ọtalelẹgbẹrun o din mẹwa eeyan lo kopa ninu iwọde naa ninu eyi ti a ti ri James Baldwin, Harry Belafonte ati Sidney Poitier.

Àkọlé fídíò, 'CAC Agbala Itura ni mo ti bẹ̀rẹ̀ ìlú lílú kí ń tó máa bá Janet, àbúrò Michael Jackson lù Gangan àti Omele'
Àkọlé fídíò, Scrabble: Yorúbà Scrabble ni àkọ́kọ́ ní èdè abínibí nílẹ̀ Afrika

Lara awọn eeyan pataki to wa nibẹ ni eeyan kan ti ọpọ ko lee lero pe yoo wa nibẹ - ayan onilu ọmọ Naijiria ti orukọ rẹ n jẹ Babatunde Ọlatunji.

Ọdun 1927 ni a bii sinu mọlẹbi Yoruba kan ni ipinlẹ Eko. Ọlatunji si janfani ẹkọ ọfẹ lati lọ kawe nileewe Morehouse College ni Atlanta lọdun 1950.

O di eekan onilu pẹlu awo orin mẹtadinlogun, awo orin rẹ akọkọ to gbe jade lọdun 1959 pẹlu akọle "Drums of Passion" ti ọpọ gboṣuba fun gẹgẹ bi eyi to pe akiyesi awọn alawọfunfun si orin rẹ.

Ọrọ Babatunde Ọlatunji

Lootọ, Ọlatunji ti fi ogun rere lelẹ nipa ti iṣẹ orin ninu eyi ti a ti ri mimu ti wọn mu orukọ rẹ ranṣẹ fun ami ẹyẹ Grammy ati awọn orin to gbe kalẹ fun awọn sinima ni Broadway ati Hollywood, ṣugbọn iwọnba lawọn eeyan mọ nipa ilakaka rẹ gẹgẹ bii afọnrere ija fun ẹtọ ọmọniyan.

"O jẹ olufọkansin fun ẹtọ ọmọniyan lawujọ ni gbogbo ọjọ aye rẹ," ni ọrọ kan ti Robert Atkinson, to ba ọlatunji ṣiṣẹ pọ lori kikọ iwe itan igbesi aye rẹ ti wọn gbe jade ni ọdun meji lẹyin iku rẹ lọdun 2005 pẹlu akọle 'The beat of My Drum."

"Ẹni to yẹ lati maa ṣe iranti rẹfun ipa to ko lori ijafẹtọ aparo kan o ga jukan lọ lorilẹede Amẹrika ni, koda o ti bẹrẹ ṣaaju ki eyi ọwọja iwọde ijafẹtọ naa to gbẹrẹgẹjigẹ ni."

Àkọlé fídíò, Protein Marasmus: Wo èwu tó wà nínú kí ọmọdé má ní èròjà Protein lára

Ayọ rẹ ninu aṣa ilẹ Afirika

Gẹgẹ bi akẹkọ ileewe Morehouse, ọpọlọpọ ahesọ to da lori aini imọ to to nipa Afirika ni Ọlatunji dojukọ, ti o si ni lati tiraka da awọn akẹkọọ ẹgbẹ rẹ lẹkọ nipa orin, aṣa ati iṣe ilẹ Afirika.

Lasiko faaji lọgba fasiti rẹ lo ti kọkọ bẹrẹ si ni kọ ori ilẹ Afirika, pẹlu awọn are onilu kaakiri awọn ile ijọsin adulawọ atawọn alawọ funfun jakejado Atlanta.

Babatunde Ọlatunji ati iyawo rẹ Ammiebelle Bush lasiko igbeyawo wọn lọdun 1957

Oríṣun àwòrán, Olatunji family

Àkọlé àwòrán, Babatunde Ọlatunji lọsi orilẹede Amẹrika lọdun 1950 lati kọ ẹkọ o si ṣe igbeyawo pẹlu Ammiebelle Bush lọdun 1957

"Baba lo tan imọlẹ si iyi ati ẹyẹ jijẹ adulawọ laarin awọn adulawọ ọmọ ilẹ Amẹrika nipa ṣiṣe agbatẹru ifọnrere aṣa ilẹ Afirika eyi to ṣe koriya ati amuṣẹya fun igbedide iji iwọde ẹtọ ọmọniyan," gẹgẹ bi Atkinson ṣe sọ.

Lasiko to jẹ wi pe ijọba to wa lode gan fọwọ si idẹyẹsi ẹlẹyamẹya lorilẹede Amẹrika, Ọlatunji ko ṣai tete mọ pe idẹyẹsi ẹlẹyamẹya wa, ti o si bẹrẹ si ni ko awọn akẹkọọ jọ lati dide kọju ija si ofin idẹyẹsi ẹya ti wọn n pe ni "Jim Crow lawọ" nigba naa lẹkun gusu orilẹede naa.

Lọdun 1952, ọdun mẹta ṣaaju ki Rosa Parks to gbe igbesẹ to fa iwọde kikọ lati wọn bọọsi akero Montgomery, (Montgomery Bus Boycott) ni Alabama, Ọlatunji ṣe iwọde tirẹ ninu awọn bọọsi akero lẹkun gusu orilẹede naa.

Lasiko kan, oun atawọn akẹkọọ kan wọ wọ aṣọ ilẹ Afirika kan wọ bọọsi akero kan ninu eyi ti iwa idẹyẹsi ti maa n jẹyọ daadaa lasiko igba naa ni Atlanta. Wọn fi aye gba wọn lati joko si aye to wu wọn ninu ọkọ naa nitori pe wọn ko da wọn mọ gẹgẹ bii adulawọ ọmọ Amẹrika to jẹ pe nigba naa ẹyin ọkọ ni wọn maa n fi aye ijoko wọn si.

Iyaafin Ammiebelle Ọlatunji

Ni ọjọ keji, wọn wọn ọkọ bọọsi kan naa pẹlu aṣọ oyinbo lọrun wọn, wọn si faake kọri pe awọn ko ni joko si aye ẹyin ninu bọọsi naa nigba ti awakọ naa paṣẹ pe ki wọn lọ ree joko si ọwọ ẹyin. Ọlatunji atawọn akẹgbẹ rẹ tẹsiwaju lati maa tako idẹyẹsi yii lọna yii lai naani ihalẹ pe wọn yoo ju wọn si ẹwọn.

Ọlatunji ṣi ṣalaye lori iwọde yii pe, "A bẹrẹ ifẹhonuhan naa ni bonkẹlẹ," O ni, "a jẹ ọkan lara awọn to bẹrẹ ipe fun ominira ni ibẹrẹ ọdun 1950.

Ṣiṣe alabapade Martin Luther King ati Malcolm X

Iyawo Ọlatunji, Iyaafin Ammiebelle Ọlatunji to jẹ ẹni aadọrun ọdun ṣalaye fun BBC pe Ọlatunji ni wọn maa n pe"lati wa bomi pa wahala lawọn ileto gbogbo", bii asiko ti iwọde to gbona janjan n waye lọdun 1965 lawọn ileto tawọn alawọ dudu n gbe ni Watts ni Los Angeles.

"O ri ara rẹ gẹgẹ bii ajafẹtọ ilẹ Adulawọ to n ṣetan ni gbogbo igba lati mu iṣọkan ba awọn ọmọ ilẹ Afrika atawọn ọmọ Amẹrika to jẹ adulawọ." Gẹgẹ bi Iyafin Ọlatunji ṣe sọ nipa ọkọ rẹ.

Babatunde Ọlatunji pẹlu Malcolm X

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Babatunde Ọlatunji pẹlu Malcom X nibi ayẹyẹ kan lati sami ominira Naijiria kuro labẹ ijọba amunisin ilẹ Gẹẹsi ni Harlem lọjọ kini oṣu kẹwaa ọdun 1960

Ọlatunji di aarẹ ẹgbẹ awọn akẹkọọ nileewe giga Morehouse, eyi lo si mu ki o ṣe alabapade ọpọlọpọ awọn ajafẹtọ ọmọniyan nigba naa bii Martin Luther King Jr ati Malcolm X.

Afẹfẹ ijijagbara lọwọ ijọba amunisin to n fẹ kaakiri ilẹ Afirika laarin ọdun 1950 si 1969, ninu eyi ti oun pẹlu ti kopa, lo ṣe atọna fun ikopa Ọlatunji ninu iwọde ijafẹtọ ọmọniyan ni Amẹrika.

Ni ọdun 1958, o rinrinajo lọ si ilu Accra lati kopa nibi ipade apapọ awsn ọmọ ilẹ adulawọ, All African People's Conference, ti adari orilẹede Ghana lasiko igbominira rẹ, Kwame Nkuruma gbe kalẹ.

Ipade apapọ yii ko awọn aṣiwaju ija fun igbominira kaakiri ni Afirika atawọn aṣoju jọ lati orilẹede mejidinlọgbọn kaakiri ilẹ Afirika lati fi ọgbọn kun ọgbọn lori ọna ati tubọ tẹmpẹlẹ mọ atako ijọba amunisin awọn alawọnfunfun Yuroopu nigba naa.

Awọn eekan ajafẹtọ lorilẹede Amẹrika bii Claude Barnett, oludasilẹ ileeṣẹ itẹwe iroyin Associated Negro Press to wa ni Chicago ati Alphaeus Hunton, to jẹ akọwe igbimọ to n ṣe kokari ọrọ Afrika nigba naa.

Ọjọgbọn Louis Chude-Sokei, oludari ẹka ẹkọ imọ nipa ilẹ Afirika ati Amẹrika ni fasiti Boston, ṣalaye pe ifọrọwerọ ati ifimọ we imọ n waye laarin awọn ọmọ ilẹ Afirika atawọn ọmọ orilẹede Amẹrika to jẹ wi pe ominira awọn orilẹede bii Ghana ati Naijiria nigba naa lo n ṣe koriya fun wọn.

O tun ṣalaye fun BBC pe, "Pẹlu bo ṣe jẹ pe afojusun kan naa ni wọn ni nipa ijijagbara lọwọ iwa ẹlẹyamẹya, kii ṣe babara mọ lati ri awọn ọmọ ilẹ Afirika atawọn ọmọ orilẹede Amẹrika to jẹ adulawọ ti wọn n jọ n ṣe aṣepọ lori aṣa ati awọn ọrọ miran to jẹ mọ ominira ati ijijagbara"

Imunisin ati idẹyẹsi

Lọdun 1957, Martin Luther King Jr, gba iwe ipe lati wa ba orilẹede Ghana ṣe ajọyọ ominira rẹ, nibẹ lo si ti pade. Ipade ye ni ipa manigbagbe lara King, ẹni to ri ọpọlọpọ iwuri mu jade fun igbesẹ jija fẹtọ ọmọniyan to gbe dani pẹlu eto ijijagba ominira orilẹede Ghana.

"Orilẹede Ghana ni ẹkọ lati kọ wa" gẹgẹ bi ọrọ ti Luther King Jr sọ ninu iwaasu rẹ akọkọ lẹyin to pada de latorilẹede Ghana. "Ẹkọ naa si ni pe...ko si amunisin to n fẹ fun ẹni to n sin in ni ominira bọrọbọrọ. Iṣẹ aṣelaagun lo gbọdọ ṣe."

Martin Luther King (lapa alaafia) ati Malcolm X (lapa ọtun)

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Babatunde Ọlatunji sunmọ Martin Luther king to wa lapa alaafia ninu aworan yii ati Malcolm X to wa lapa ọtun- awọn mejeeji wa ninu fọto yii ni igba kan ṣoṣo ti wọn jijọ pade nigba aye wọn ldun 1964

Ni ọdun 1962 nibi ipade apapọ awọn adari to jẹ alawọ dudu nilẹ Amẹrika, iyẹn American Negro Leadership Conference, Luther King Jr tunbọ yannana ibarẹpọ to wa laarin ijọba amunisin ni Afirika ati iwa idẹyẹsi ni Amẹrika, to si wi pe awọn mejeeji fẹ fi ara pẹra nitori gbogbo abalọ-ababọ rẹ naa ni ijẹgaba, fifi agidi munisinlu lọna oṣelu ati tẹmbẹlu ọmọniyan."

Amọ, akẹgbẹ Luther King, Malcolm X ni tirẹ fara mọ awọn igbesẹ idoju ija kọ awọn amunisin bi o ṣe n waye pẹlu awọn ọmọ ẹgbẹ Mau Mau lorilẹede Kenya, pẹlu igbagbọ pe lilo lara awọn igbesẹ wọn lee ran wọn lọwọ lati dẹkun awọn ẹgbẹ Ku Klux Klan ni Amẹrika.

Babatunde Ọlatunji ni ẹnu iṣẹ ilu lilu

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Awọn ọmọ rẹ obinrin ni Ọlatunji lo ṣe awokọṣe fun ọpọ olorin Jazz, ko si fi iṣẹ ṣere

Bakan naa lo pade omilẹgbẹ awọn aṣiwaju ilẹ Afirika lati jiroro lori ijijagbara awọn smọ ilẹ Amẹrika to jẹ adulawọ, ki o si ri atilẹyin gba lọwọ aarẹ akọkọ lorilẹede Tanzania, Julius Nyerere. Lọdun 1964, Nyerere ran Malcolm X lọwọ lati rọ awọn aṣiwaju ilẹ Afirika lati buwọlu afẹnuko kan nibi ipade apapọ ajọ iṣọkan awọn orilẹede Afirika, OAU to rọ ilẹ Amẹrika pe ko fopin si idẹyẹsi ati iwa ẹlẹyamẹya lorilẹede naa.

Malcolm X tun ba awọn awọn ọmọ ilẹ Afirika lorilẹede Amẹrika sọrọ, nibẹ loun ati Ọlatunji si ti pade to si rọọ pe ko wa lu ilu nibi iwọde awọn ajijagbara nibẹ.

Gẹgẹ bi ọrọ ti Atkinson sọ, "O ni ajọṣepọ to dan mọran pẹlu Martin Luther King ati Malcolm X,"

"Baba jẹ alarinna laarin igun meji nigba naa: King jẹ ẹni to di opo alaafia mu, bẹẹni Malcolm kii fi gbogbo igba fara mọ iru ọna bẹẹ."

Ohun to nifẹ si to si mumu ni ookan aya rẹ

Ọlatunji ṣe ọpọlọpọ ere fun ẹgbẹ NAACP ati ile ijọsin Souther Christian Leadership Conference to jẹ ti Luther King. Ni ọdun 1960, o farahan nini awo orin onijo Jazz fun ẹtọ ọmọniyan ti wọn pe akọle rẹ ni "We Insist! Pẹlu akọwe ere oniṣe ni Oscar Brown Jr ati Max Roach.

Omidan Tometi ti ẹgbẹ Black Lives Matter

"Bi baba mi ṣe maa n fara si ere gbogbo to ba n ṣe nibi to ti maa n ṣe afihan ifẹ to ni si iṣe, ọrọ ẹkọ inu iṣẹ ọna rẹ atawọn ololufẹ rẹ a maa ya mi lẹnu pupọpupọ," Fọlaṣade, ọkan lara awọn ọmọ rẹ mẹrin lo sọ eyi fun BBC.

O ni, "Ẹmi itẹpamọṣẹ rẹ ga pupọ, eyi lo si fi kọ gbogbo awọn ọmọ rẹ atawọn to sun mọ ọ."

Ọmọbinrin rẹ kekere, Modupẹ naa fi kun un pe: "Titi to fi jade laye ko fi ẹmi ifara jin fun iṣẹ naa silẹ"

Ni ọdun 2003 ni baba wọn ku nigba to ku ọjọ kan ko pe ọmọ ọdun mẹrindinlọgọrin. Ogun orin kikọ ati jijafẹtọ smọniyanto fi silẹ ṣi n tẹsiwaju lati iran de iran, paapaajulọ laarin awọn ọmọ ilẹ Afirika to wa ni orilẹede Amẹrika bayii, ti wọn n fi igbe aye rẹ ṣe awokọṣe pẹlu bi o ṣe duro gẹgẹ bi alarena laarin ilẹ Afrika ati gbogbo agbaye yoku.

"A ti tẹwọ gba iṣẹ naa lọwọ awọn iran to ti kọja lọ, awa naa si n tẹsiwaju pẹlu ire ije naa ti wọn bẹrẹ," ni ọrọ ti Omidan Tometi ti ẹgbẹ BLM sọ nipa rẹ.

Ẹni to kọ iwe itan igbesi aye Ọlatunji fi kun un pe: "Asiko to dara gan niyi fun awọn eeyan lati mọ nipa Baba.

Awọn iwọde fun idajọ odod wọnyi jẹ tuntun to si tun lagbara ju eyi ti baba kopa ninu rẹ lọgọta ọdun sẹyin.