Niger Republic killings: Buhari ṣèlérí ìrànwọ́ láti dojú ìjà kọ agbésùnmọ̀mí láwọn ilẹ̀ tó yí Nàijíríà ká

Aarẹ Muhammadu Buhari

Oríṣun àwòrán, Facebook/Bashir Ahmad

Aarẹ Muhammadu Buhari ti bu ẹnu ẹtẹ lu iṣẹlẹ ipaniyan to ṣẹlẹ ni orilẹede Niger Republic.

Aarẹ Buhari sọrọ yii lọjọ Ẹti lori bi iṣẹlẹ igbesunmọmi ṣe n gbilẹ si to si n tan kalẹ kaakiri.

Eeyan bii mọkandinlaadọrin lawọn agbesunmọmi pa ni ifanna faṣu laarin ibode Niger ati Burkina Faso.

Ninu atẹjade ti oludamọran Aarẹ Buhari, Garba Shehu fi sita, aarẹ ṣeleri iranwọ fun orilẹede Niger atawọn orilẹede to yi Naijiria ka lati doju ija kọ awọn agbesunmọmi nibẹ.

Buhari ṣe apejuwe iṣẹlẹ ipaniyan naa gẹgẹ bi eyi to ba ni lọkan jẹ pupọ.

Àkọlé fídíò, Protein Marasmus: Wo èwu tó wà nínú kí ọmọdé má ní èròjà Protein lára

''Ibanujẹ ni o jẹ bi awọn agbesunmọmi ṣe da awọn eeyan loro kaakiri apa iwọ oorun ilẹ Afirika.

A gbọdọ sa gbogbo agbara wa lati ri pe a ṣegun awọn agbesunmọmi lapa iwo oorun Afirika.

Ọrọ igbesunmọmi kii ṣe ohun ti a le maa fi oju iṣẹlẹ abẹle wo mọ.

Igbesunmọmi dabi ina inu ọyẹ to n ran kaakiri bayii lapa iwo oorun ilẹ Afirika.

Asiko ti wa to bayii lati wa egbo dẹkun fawọn agbesunmọmi to n ṣakoba fun ọrọ aje awọn orilẹede lapa iwọ oorun Afirika,'' Buhari lo ṣalaye bẹẹ ninu atẹjade ti ileeṣẹ aarẹ fi sita.