Abubakar Shekau: Ìyá olórí Boko Haram banújẹ́ lórí bí ọmọ rẹ̀ ṣé ṣeọ̀pọ̀ èèyàn níbi

Abubakar Shekau ati iya rẹ

Oríṣun àwòrán, Screen shot

Yoruba bọ wọn ni ko sí bi a o ṣe peri aja, ti a ko ni pe ori ikoko ta fi se e.

Eyi lo difa fun Falmata Abubakar to jẹ iya olori ẹgbẹ agbesunmọmi Boko Haram, Abubakar Shekau to figbe ta fun araye.

O ni ibanujẹ ọkan lo jẹ foun pe ọmọ ti oun bi lo n fa irora fun ẹgbẹlẹgbẹ awọn eeyan ti ko mọwọ ti mẹsẹ.

Eyi ni igba akọkọ ti iya Shekau yoo sọrọ lati igba ti iroyin kan gbe jade pe o ti ku.

Falmatu sọrọ yii ninu ifọrọwerọ kan lori ileeṣẹ amohunmaworan Trust TV nibi to ti sọ pe oun ko le sọ ni pato bo ya Shekau bimọ ko to faye silẹ lọ.

Abubakar Shekau

Oríṣun àwòrán, AFP

"Ohun kan ti o pa awa mejeeji pọ ni pe emi ni mo bi i lọmọ, o tan!

Mi o le sọ nipa iku rẹ gan an nitori ọdun mejidinlogun ni mo ri soju gbẹyin.

Ọrọ Shekau maa n fun mi ni ọgbẹ ọkàn, Ọlọrun nikan lo maa ṣe idajọ to tọ fún un pẹlu gbogbo nkan to ti ṣe.

Shekau kuku dagba labẹ mi gẹgẹ bí ọmọ ṣe maa n dagba labẹ obi.

Àmọ́, nigba to lọ si ilu Maiduguri, tíì ṣe olu ilu ipinlẹ Borno, lati lọ kẹkọọ nipa ẹsin islam lo ya iyakuya.

Níbẹ lo ti pade Muhammad Yusuf to jẹ oludasilẹ ẹgbẹ Boko Haram," Iya Shekau lo sọ bẹẹ.

Iya Abubakar Shekau

Oríṣun àwòrán, VOA

Ẹgbẹ agbesunmọmi mii, ISWAP lo kede iku Shekau ninu fọnran kan to fi lede lọjọ karun ùn oṣu mẹfa ọdun 2021 yii.

Iroyin sọ pe Shekau fi ado oloro pa ara rẹ lẹyin tawọn ọmọ ẹgbẹ ISWAP lọ ka mọ Ibudo rẹ.

Ọdun 2009 ni Shekau di olori Boko Haram lẹyin ti Yusuf ku si atimọle awọn ọlopaa tan.

Bi awada bi ere ni Shekau bẹrẹ si ni dari ẹgbẹ naa lọjọ naa lọhu,n ki o to wa tan kalẹ dé ibi gbogbo ila oorun ariwa orilẹ ede Naijiria bayii.

Labẹ aṣẹ Shekau, Boko Haram ti ran ọpọ eeyan lọ sí ọrun ọsan gangan, wọn n ju ado oloro kaakiri ilu.

Wọn n ji awọn eeyan gbe, wọn si n tun ṣe ikọlu si ọgba ẹwọn níbi tí wọn ti n tu awọn ẹlẹwọn silẹ.

Shekau n fa itiju fawọn eeyan ilu rẹ

Lẹyin ti Shekau di ilúmọọka tan laarin ninu ẹgbẹ agbesunmọmi Boko Haram, awọn eeyan ilu rẹ maa n tiju lati b'awọn eeyan to wa lati awọn ilu mii nipinlẹ Bornu ṣe ajọṣepọ.

Wọn ni oju ọdaran l'awọn eeyan maa n fi wo awọn lawujọ.

Yusuf Harun to jẹ ọmọ ilu Shekau ṣalaye fún BBC pe ni gbogbo igba loju maa n gba oun ti nitori ọrọ Abubakar Shekau.

Harun ni itiju nla lo jẹ pe "ọmọ ilu Shekau ni mi tori iwa buruku ti Shekau n wu.

Ọpọ ọmọ ilu wa ni kii le sọ pe ọmọ ilu Shekau ni awọn nitori oju tawọn eeyan maa fi n wo wọn lawujọ."

Isa Sani to jẹ olugbe ipinlẹ Bornu ni ọpọ ọmọ ilu Shekau lo maa n sọ pe ilu miran ni awọn ti wọn wa tori itiju.

O ni Shekau ti fun ilu rẹ ni orukọ buruku eleyii ti o si le ma yipada láéláé.

Àkọlé fídíò, Mesach Oyediran: Ọba ni Dafidi tó ń lu dùùrù, tó sì kọ sáàmù, ta ni èmi tí kò ní le yin