Mr Macaroni, Taaooma, Woli Agba, Adeyemi Elesho sọrọ lórí ìpè láti ṣèpàdé pẹ̀lú ìgbákéjì ààrẹ Yemi Osinbajo

Osinbajo, Taaooma, Woli Agba

Oríṣun àwòrán, Woli Agba

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Awọn gbajugbaja apanilẹrin bii Debo Mr Macaroni, Taaooma, Woli Agba Ayo Ajewole ati Adeyemi Elesho to jẹ ọmọ agba oṣere, Elesho ti fi ọrọ sita lori ipade kan ti wọn pe wọn si pẹlu igbakeji aar Naijiria, Yemi Osinbajo eyi to di ariwo lori ayelujara lẹnu awọn ọdọ Naijiria.

Maryam Apaokagi ti ọpọ mọ si Taaooma ti sọrọ pe oun tọrọ aforijin pe oun jẹ ipe naa lati lọ ṣepade pẹlu igbakeji aarẹ, Ọjọgbọn Yemi Osinbajo.

Ninu ọrọ aforijin rẹ to fi sita fawọn ọmọ Naijiria, o ṣalaye pe oun ko fẹ kọkọ gba lati lọ fun ipade naa ṣugbọn oun tun daa ro pe yoo fun oun lanfani lati sọ ero rẹ lori awọn ọrọ to n gbona janjan ni Naijiria.

Àkọlé fídíò, 'Wọ́n gba irun abẹ́ wa, irun abíyá wa, a lọ búra, ilé "Nylon" la tún ń gbé ni Mali fi ṣe iṣẹ́ aṣẹ́wó'
Aforijin Taaooma

Oríṣun àwòrán, Taaooma

Alaye Taaooma

Oríṣun àwòrán, Taaooma

Taaooma ṣe eyi lẹyin ti ibẹwo rẹ ọhun bẹrẹ si ni fa ariwo lori ayelujara ti awọn eeyan n gbaa bi ẹni n gba igba ọti.

Bi awọn ọmọ Naijiria mii ṣe n kan sara si awọn to lọ fun ipade naa ni awọn mii n tabuku wọn ti wọn si n gboriyin fun apanilẹrin Mr Macaroni to kọ lati lọ ni tirẹ to si ṣalaye.

Àkọlé fídíò, Taooma: Ìbáṣepọ̀ mi pẹ̀lú àwọn òbí mi yàtọ̀ sí bí mó ṣé n polongo nínú fídíò mi

Wọn ni lilọ wọn jẹ lati ṣe igbelarugẹ fun iṣẹ wọn ti wọn yan laayo ni kii ṣe lati sọrọ lorukọ awọn ọdọ Naijiria gẹgẹ bi wọn ṣe jẹ ki awọn eeyan gbagbọ.

Kii ṣe awọn Naijiria nikan lo fesi amọ awọn adẹrinpoṣonu naa ti ọrọ kan gaan ti sọ ero ọkan wọn nipa rẹ.

Esi awọn ọmọ Naijria

Ọkan lara awọn gbajugbaja ajafẹtọ ọmọniyan, Aisha Yesufu sọ fun Taaooma pe ko tilẹ nilo lati tọrọ aforijin lọwọ ẹnikẹni tori pe oniruuru ọna leyan le gba ṣe amuṣẹ nkan.

Bẹ naa ni mọ Naijiria kan Mankwat Nisa fesi pe "mo lero pe ẹ ko lọ ṣoju emi nibẹ, to ba ri bẹẹ, ko kan mi".

Esi awọn ọmọ Naijiria

Oríṣun àwòrán, Aisha Yesufu

Esi awọn ọmọ Naijiria

Oríṣun àwòrán, Rinu Oduala

Àkọlé fídíò, Wòólì Alfred kú lọ́dún 1964, ó tún padà wà sí ìlú Agelu f'ọ́jọ́ mẹ́rìnlá!

Ẹwẹ, bi awọn wọnyii ṣe ni ki wọn ka ọrọ awọn eeyan to n bu wọn si yinyin agbado sẹyin igba, awọn ọmọ Naijria mii ni iṣẹ ara wọn ni wọn ba lọ.

Esi awọn ọmọ Naijiria

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Esi awọn ọmọ Naijiria

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Mr Macaroni ti ko lọ fun ipade naa

Gbajugbaja apanilẹrin ti ko ba wọn pe nibi ipade naa, Debo Adebayo ti ọpọ mọ si Mr Macaroni ni tirẹ ṣalaye idi ti ko fi lọ to si ni oun ko ni ki awọn to lọ ma lọ.

Ninu ọrọ to fi sita, o ni idi ti oun ko fi lọ ni pe inu oun ko dun si awọn adari oṣelu oun ko si f ni nkan ṣe pẹlu wọn.

O ni o dara bi awọn to ku ba gbagbọ pe biba ijọba joko sọrọ yoo mu ayipada ba awọn nkankan, "ki ẹnikẹni ma si gbe ọbẹ si wọn lọrun pe wọn lọ".

Esi awọn ọmọ Naijiria

Oríṣun àwòrán, DeboMacaroni

Lara awn adẹrinpoṣonu mii to lọ fun ipade naa ni Ayo Ajewole ti ọpọ mọ si Woli Agba.

Skip Instagram post, 1
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of Instagram post, 1

Adeoye Adeyemi Elesho to jẹ ọmọ agba oṣere, Elesho to ni gbogbo igba ti awọn ba n ṣe ifẹhonuhan, oun ti maa n woye ọjọ kan ti oun yoo lanfani lati sọrọ fun awọn adari ijọba lojukoroju.

Skip Instagram post, 2
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of Instagram post, 2

Lara awọn to lọ ni Taooma; Josh Alfred (Josh2funny); Ayo Ajewole (Woli Agba); Adebamiro Adeyanju (Mr Hyenana) ati Adeoye Adeyemi Elesho (Yemi Elesho).