Protein Marasmus: Wo èwu tó wà nínú kí ọmọdé má ní èròjà Protein lára

Àkọlé fídíò, Protein Marasmus: Wo èwu tó wà nínú kí ọmọdé má ní èròjà Protein lára

Kii se ohun titun, ka maa ri awọn ọmọde ti ikun wọn yoo se kindinrin, ti ori wọn yoo tobi, ti ẹsẹ wọn yoo si tiirin.

Ni ọpọ igba, ọmọ naa yoo maa se aisan, ti ko si ni ni ilera to peye, eyi tawọn obi rẹ ati ẹbi yoo di ẹbi rẹ lori isẹ aye.

Amọ iwadii BBC nipa isẹlẹ yii ti fihan pe aisi eroja asaraloore ti wọn pe Protein lo n sokunfa iru aisan ati aidape ara fawọn irufẹ ọmọde bẹẹ.

Ọpọ obi to ni iru awọn ọmọ bayii, to ba BBC Yoruba sọrọ lo ni ọwọ aye lo wa lara awọn ọmọ naa.

Bakan naa ni iwadi wa fidi rẹ mulẹ pe ọrọ aje ọpọ idile to ni awọn ọmọ yii, lo ti dẹnu kọlẹ, paapaa ti ọwọja arun Coronavirus gan si da kun ohun to n se ọ̀rọ aje wọn.

Ọpọ ninu irufẹ awọn idile yii si lo jẹ pe eroja afaralokun bii ẹba, fufu, amala ati irẹsi nikan ni wọn n fun awọn ọmọ wọn jẹ.

Sugbọn awọn onisegun oyinbo to ba BBC sọrọ lori igbesẹ yii ni aini imọ ati aito eroja asaraloore lo n fa isẹlẹ yii lara ọmọde.

Ẹkunrẹrẹ iwadiii BBC ree lori ọrọ naa.