Ikoyi house collapse: Ìjọba ìpínlẹ̀ Eko sọ̀rọ̀ lórí ẹni tó ni ilé alájá 21 tó dà wó ní Ikoyi

Oríṣun àwòrán, LASEMA
Oriṣiiriṣii iroyin lo ti lu ori ayelujara pa lori ẹni to ni ile alaja mọkanlelogun to da wo lagbegbe Ikoyi niluu Eko.
Lati igba ti iṣẹlẹ ọhun ti ṣẹlẹ ni oniruuru awuyewuye ti n lọ lori rẹ.
Bi awuyewuye ti ṣe n waye lori ohun to fa iṣẹlẹ naa, ni awuyewuye waye lori iye awọn to ti ku, awọn ti wọn ti ri gbe jade laaye, ati bẹẹbẹẹ lọ.
- ''Mo ti gbàdúrà fún àànú láti r'ọ́run wọ̀ lẹ́yìn tí mo wà lábẹ́ ilé tó wó ní Ikoyi fún ọjọ́ kan''
- Ìgbéyàwó Lateef Adedimeji àti Bimpe Oyebade fẹ́ ṣẹlẹ̀ lọ́tẹ̀ yìí? Òtítọ́ tí Lateef sọ fún BBC Yorùbá rèé
- Sanwo-Olu ṣèlérí ìrànwọ́ owó fún ètò ìsìnkú tó dára f'àwọn tí ilé alájà 21 wó pa ní Ikoyi
- 'Wọ́n gba irun abẹ́ wa, irun abíyá wa, a lọ búra, ilé "Nylon" la tún ń gbé ni Mali fi ṣe iṣẹ́ aṣẹ́wó'
- "Amẹ́ríkà ni Wale Bob-Oseni ń lọ, ìpè fóònù tó gbà, ló gbe lọ síbi ilé tó dà wó"
- Ǹ jẹ́ o mọ̀ pé Femi Osibona ta bàtà àti aṣọ kóòtù rí, kó tó di akọ́létà?
- Kí ló so Yemi Osinbajo pọ̀ mọ́ ilé alájà púpọ̀ tó dà wó ní Eko?
- Agbo ti Jesu: Wòólì Ajayi kú ní ìlú Agelu, òkú rẹ pòórá, ìjọ sin pósí lásán!
- Ọmọ Nàìjíríà ẹ múra sílẹ̀, ǹkan yóò le ju báyìí lọ lọ́dún 2022- Primate Ayodele sọ tẹ́lẹ̀
Amọṣa lọwọ yii, awuyewuye to n waye ni lori ẹni gan to ni ile naa.
Ninu iroyin rẹ ọjọ kẹrin oṣu Kọkanla ọdun 2021, Sahara Reporters ni "wọn ti rii pe igbakeji aarẹ orilẹede Naijiria, Yẹmi Oṣinbajo ni ajọṣepọ pẹlu ile alaja mọkanlelogun to da wo nipinlẹ Eko".
Iwe iroyin naa tun kọọ pe, awọn alami awọn sọ fun awọn pe Igbakeji Aarẹ Osinbajo lo ra ilẹ naa lọwọ oloye Michael Ade-Ojo, to jẹ oludasilẹ ileeṣẹ Elizade Motors, lẹyin to de ipo igbakeji aarẹ.
Amọ, ileesẹ aarẹ Naijiria ti fi atẹjade sita lori rẹ pe ko si ohun to kan igbakeji aarẹ pẹlu dukia ilẹ ati ile to dawo naa.
Atẹjade kan ti agbẹnusọ fun igbakeji aarẹ, Ọjọgbọn Yẹmi Oṣinbajo, Laolu Akande fi sita sọ pe gbogbo dukia ti igbakeji aarẹ ni lo ti kede fun ijọba gẹgẹ bi ofin orilẹede Naijiria ti ṣe laa kalẹ.
Atẹjade naa ni ko si nkankan ti igbakeji aarẹ ba gomina ipinlẹ Eko tabi oṣiṣẹ ijọba ipinlẹ naa kankan sọrọ nipa yiyọ iwe ti wọn le fi ti ile naa pa ki o to dawo.
Ati pe ko si igba kankan to gbe igbesẹ lati di iṣẹ awọn ajọ to n mojuto ọrọ ile gbigbe nipinlẹ Eko lọwọ.
Bakan naa ni Oloye Ade-Ojo, alaga ileeṣẹ Elizade sọ pe irọ lasan n'iroyin naa ati pe oun ati Igbakeji aarẹ Oṣinbajo ko fi igba kankan ni idunadura lori ilẹ ti wọn kọ ile to da wo naa si.
Oloye Ade-Ojo ni "mo ti n tẹnu mọọ pe mi o fi igba kankan ni ilẹ yii.
"Ko le ye gbogbo eeyan, mo ni dukia kan si ẹgbẹ ile ti a n sọrọ rẹ yii, ti mi o si tii ta, ti mi o dẹ nii lọkan ati ta fun ẹnikẹni."
Amọ, ijọba ipinlẹ Eko ti fidi rẹ mulẹ fun BBC Yoruba pe akọleta, Femi Osibona ti oun naa ba iṣẹlẹ naa lọ lo ni ile ọhun.
Kọmiṣọnna fun eto iroyin, Gbenga Omotosho sọ fun BBC Yoruba pe gbogbo eeyan lo mọ pe Osibona lo ni ile naa.
''Osibona ti oun naa di oloogbe nibi iṣẹlẹ yii naa lo ni ile to da wo ni Ikoyi.
Ṣugbọn o ṣeni laanu pe ẹni to ni ile lo jẹ awọn eeyan logun lẹyin ti eeyan mejilelogoji ba iṣẹlẹ naa lọ.
O dabi ẹni pe awọn eeyan wa ṣa fẹran ki wọn maa sọ ọrọ ikọkọ.
Wọn fẹran lati maa wa ọna lati ṣe ibajẹ ti iṣẹlẹ kan ti ṣẹlẹ lai kaanu awọn ti iṣẹlẹ ọhun ṣẹlẹ si.
Emi ko ro pe ko ro pe ede-ai-yede figba kan wa lori ẹni to ni ile naa.
Content is not available
View content on FacebookBBC kò mọ̀ nípa àwọn ohun tí ó wà ní àwọn ojú òpó tí ó wà ní ìta.End of Facebook post
Igbakeji aarẹ osinbajo gan an ti sọ pe oun yoo gbe ẹnikẹni to ba sọ pe oun loun nile naa lọ si ile ẹjọ.
Awọn eeyan ko ni aanu loju mọ gẹgẹ eniyan, a kan wa huwa bi ẹranko,''Ọgbẹni Omostosho lo ṣalaye bẹẹ.
Kọmiṣọnna Omotosho tun fidi rẹ mulẹ pe awọn oṣiṣẹ iṣẹlẹ pajawiri si n tẹsiwaju lati ṣawari awọn eeyan to ba tun le wa labẹ ogiri alapa ile to da wo naa.
















