Primate Ayodele: Pásítọ̀ ìjọ INRI sọ tẹ́lẹ̀ pé ọrọ̀ ajé Nàìjíríà yóò dẹnu kọlẹ̀ síi lọ́dún 2022

Primate Babatunde Elijah Ayodele

Oríṣun àwòrán, Facebook/Primate Babatunde Elijah Ayodele

Ọpọ ọmọ orilẹede Naijiria lo n pariwo ilu o fararọ lasiko yii bi gbogbo nkan ṣe wọn gogo lọja ti atijẹ si nira fun ọpọ eeyan.

Amọ alufa ijọ INRI Evangelical Spiritual Church, Primate Elijah Babatunde Ayodele ti sọ pe a ṣẹṣẹ n me ẹyẹ bọ lapo ni.

Primate Ayodele ni nkan yoo le ju bayii lọ fawọn ọmọ orilẹede Naijiria lọdun to n bọ.

Pasitọ Ayodele to sọ tẹlẹ ni ibẹrẹ ọdun yii nipa ile to wo pa awọn eeyan ni Ikoyi niluu Eko sọ pe ọrọ aje Naijiria yoo tubọ dẹnu kọlẹ sii lọdun 2022.

''Oju awọn ọmọ Naijiria yoo ri to lọdun 2022 nitori iyan yoo mu sii.

Ọrọ aje Naijiria tẹsiwaju lati maa dẹnu kọlẹ, koda agbọjẹ oloṣelu kan yoo tun ku lọdun 2022.

Ẹni ti yoo jẹ aarẹ Naijiria gan an ninu idibo 2023 yoo jẹ iyalẹnu fun gbogbo eeyan.

Lori ọrọ aarẹ, mo ti sọ tẹlẹ pe tawọn eeyan apa guusu ko ba fimọ ṣọkan, ara oke Ọya ni yoo tun jẹ aarẹ Naijiria lọdun 2023.

Awọn ipinlẹ kan yoo doju bo ilẹ ni Naijiria, awọn minisita kan to wa ni ijọba Aarẹ Muhammadu Buhari yoo gba idaduro lẹnu iṣẹ.

Bakan naa, o san fun Aṣiwaju Bola Tinubu ko gbaju mọ ipinlẹ Eko ko si gbagbe nipa ipo aarẹ tori awọn oluṣelu tuntun kan ti yoo dide ni yoo gba ijọba Naijiria.

Agbẹjọro agba ati minisita eto idajọ ni Naijiria, Abubakar Malami yoo koju oriṣiiriṣii iṣoro.

Ẹ sọ fun gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde pe ko ye ba igbakeji rẹ ja mọ, bi bẹẹ kọọ, o maa ṣe ara rẹ.

Mi o tii ri ẹni to le la Gboyega Oyetola mọlẹ ninu ẹgbẹ oṣelu PDP fun saa keji ninu ibo gomina nipinlẹ Osun.

Kayode Fayemi gbọdọ ṣe atunṣe ninu ẹgbẹ oṣelu APC l'Ekiti, bi bẹẹ kọ, ko ni wọle fun ipo gomina fun saa keji.