Ogun kidnap: Ajínigbé ń bèèrè owó ìtúsílẹ̀ N10m, Codiene, igbó àtí oúnjẹ fún ìtúsílẹ̀ èèyàn mẹ́ta tí wọ́n gbé

Oríṣun àwòrán, Others
Awọn janduku agbebọn to ji eeyan mẹta gbe nipinlẹ Ogun ti beere fun miliọnu mẹwaa naira ati oogun oloro fun itusilẹ wọn.
Ohun ti a gbọ ni pe awọn janduku ajinigbe naa yinbọn fun ẹnikan to n ṣagidi pẹlu wọn ṣugbọn ẹni naa pada moribọ lọwọ wọn.
Awọn ajiigbe ọhun ni iroyin sọ pe wọn sa pamọ sinu igbo lagbegbe Obada-Oko niluu Abeokuta nibi ti wọn ji awọn ọmọ ijọ alaṣọ funfun kan gbe ni bii ọsẹ meloo sẹyin.
- Ṣé lóòtọ́ ni Lateef Adedimeji àti Bimpe Oyebade fẹ́ ṣègbéyàwó lọ́tẹ̀ yìí lóòtọ́? Lateef bá BBC Yoruba sọ̀rọ̀
- 'Wọ́n gba irun abẹ́ wa, irun abíyá wa, a lọ búra, ilé "Nylon" la tún ń gbé ni Mali fi ṣe iṣẹ́ aṣẹ́wó'
- ''Mo ti gbàdúrà fún àànú láti r'ọ́run wọ̀ lẹ́yìn tí mo wà lábẹ́ ilé tó wó ní Ikoyi fún ọjọ́ kan''
- Sanwo-Olu ṣèlérí ìrànwọ́ owó fún ètò ìsìnkú tó dára f'àwọn tí ilé alájà 21 wó pa ní Ikoyi
- "Amẹ́ríkà ni Wale Bob-Oseni ń lọ, ìpè fóònù tó gbà, ló gbe lọ síbi ilé tó dà wó"
- Wo ọ̀rọ̀ tí gómìnà ìpínlẹ́ Ogun sọ lẹ́yìn tó ṣàbẹ̀wò sí bàbá Femi Osibona tó kọ́ ilé tó dà wó l'Eko
- Ẹ má ṣe ẹ̀dà ọ̀rọ̀ mi o àmọ́ ṣe ó dáa yín lójú pé Nàìjíríà yóò ṣì wà lọ́dún 2023? - Adeboye
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, DSP Abimbola Oyeyemi, to fidi iṣẹlẹ ọhun sọ pe awọn agbofinro ti mu ọkan lara awọn afurasi ajinigbe naa.
Abimbola ni ogbontarigi ninu awọn ajinigbe ọhun ni ileeṣẹ ọlọpaa mu.
O ni ileeṣẹ ọlọpaa ti bẹrẹ iwadii lori iṣẹlẹ ọhun, bakan naa lo fi da araalu loju pe gbogbo wọn lọwọ ọlọpaa maa tẹ.
Nigba ti o n ṣalaye bi ori ṣe ko o yọ lọwọ awọn janduku ajinigbe ọhun, Razaq Lasisi, sọ pe nibi iṣẹ ojọọ oun loun ti n pada lọ ile laago mẹsan an alẹ.
Agbegbe kan ti wọn n pe ni Ogba Kehinde ti ko jina si ile mi ni wọn ti gbiyanju lati ji mi gbe.
Lasisi ni ''ọkan lara wọn yinbọ fun mi lẹẹmeji bi mo ti n tiraka lati salọ, omiran tun di mi mu ṣugbọn mo gba iyẹn ni ẹṣẹ eleyii to jẹ ko fi mi silẹ.
Niṣe ni ẹjẹ bo mi bi mo ti n sare lọ, ile aladugbo mi kan ni mo sare wọ.
Kete ti mo de ibẹ ni mo sọ fun wọn pe ki wọn gbe mi lọ si ile iwosan Aro ti wọn ti n ṣe itọju awọn alarun ọpọlọ.''
Koda, awọn janduku ajinigbe ọhun ti pe lati beere fun miliọnu mẹwaa naira gẹgẹ bi owo itusilẹ fawọn ti wọn jigbe lọ.
Bakan naa ni wọn tun beere fun oogun codeine, marijuana, omit ati ounjẹ gẹgẹ bi ohun ti wọn tun fẹ gba fun itusilẹ awọn ti wọn jigbe lọ.
''Ṣugbọn lẹyin ti bẹ wọn tan, wọn gba pe ki a mu miliọnu kan ati aabọ wa fun owo itusilẹ.
Amọ, wọn ni a o gbọdọ maa mu oogun codiene, igbo, ounjẹ ati omi,'' Lasisi lo ṣalaye bẹẹ.














