Pastor Adeboye on 2023 Election: Wọ́n bi mi pé ta ni yóò di ààrẹ Nàìjíríà lọ́dún 2023

Oríṣun àwòrán, PAstor E.A Adeboye/Facebook
"Mo ni bawo lo ṣe da ọ loju pe Naijiria yoo wa lọdun 2023" Mo gbadura ko wa o tori naa, ẹ ma ṣi ọrọ mi gbọ ṣugbọn ṣe o da ọ loju?"
Adari ijọ irapada eyi ti ọpọ mọ si Reedeem Church of God ni Naijiria, Pasitọ Enoch Adejare Adeboye ti ju ibeere nla kan kalẹ nipa ibo fun aarẹ Naijiria ti yoo waye lọdun 2023.
Lasiko ti Adeboye n ṣe iwaasu ọjọ isinmi idupẹ ti oṣu kọkanla eyi ti wọn maa n ṣe loṣooṣu ni olu ijọ naa to wa ni Ebute Meta, Eko ni ọrọ naa jade lori boya Naijiria yoo ṣi wa tabi ko ni si mọ lọdun 2023.
O ni awọn eeyan wa bi oun pe "baba, ta ni yoo di aarẹ orilẹede lọdun 2023, mo si bere pe aarẹ orilẹede wo, wọn ni ti Naijiria, mo da wọn lohun pe ṣe Naijiria gan yoo ṣi wa lọdun 2023".
Pasitọ Adeboye ni ki ẹnikẹni ma ṣe yi ọrọ ohun mọ nkankan o amọ o tun tun un sọ pe ṣe o daa yin loju pe orilẹede Naijiria yoo ṣi wa lọdun 2023?
Adeboye ni awọn kan n wa iyi ati ipo ohun agbara oṣelu ni gbogbo ọna ti wọn si ṣetan lati pa ara wọn lori ibo ọdun 2023.
O ni awọn bẹẹ ko mọ boya wọn yoo tilẹ di ọla tori "ko sẹni to mọ nibi taa wa yii ati iwọ to n wo wa boya oo di ọla".
"Wọn o tilẹ mọ boya ọdun 2022 gan yoo wa. Bi 2023 ba tilẹ wa wa, wọn o mọ boya awọn gan yoo ṣi wa laye. Ko sẹni to lee sọ daju pe oun yoo wa laye lọla".
Adeboye ni Ọlọrun nikan lo n ṣe ipinu ẹni ti yoo wa laye lọdun 2023. "Ẹni kan n bi mi pe tani mo ro pe yoo di aarẹ".
Ṣaaju ibẹrẹ isin naa ni Pasitọ Adeboye ti gbadura fun gbogbo awọn onile ati ayalegbe pe Ọlọrun yoo jẹ ki ẹmi wọn gun lati jere iṣẹ wọn.
O kẹdun pẹlu gbogbo awọn to padanu mọlẹbi wọn ninbi ile alaja mọkanlelogun to dawo ni Ikoyi, ipinlẹ Eko o si gbadura fun wọn.
Adeboye ni bi ko ba tii kan ọ, oo le mọ ohun ti awọn to padanu eeyan to sunmọ wọn n la kọja. "Mo ti ni iriri temi nibẹrẹ ọdun yii, mọ si mọ bo ṣe ri". A kò ní pe Ọlọ́run ní ẹjọ́ lórí ìkú ọmọ wa, Dare Adeboye - Ẹbí Adeboye
Gẹgẹ bi Adeboye ṣe sọ, Ọlọrun nikan lo ni igbega lọwọ tori bo ṣe gbe eeyan kan ga lo lee rẹ ẹlomiran silẹ. "Jẹ ki ireti rẹ wa lori bibọ Jesu Kristi lẹẹkeji.
Bo ba wu u lati gbe ọ ga yoo gbe ọ ga amọ wa Ọlọrun na". Eyi lo fi kadi ọrọ rẹ to si ni ki awọn eeyan gbadura pe ohunkohun ti ko ni mu wọn de ọrun ki Ọlọrun maṣe fun wọn rara.
















