Onigbeti: Ọba ìlú Igbeti, Emmanuel Oyekan Oyebisi Afasegbejo I, ti wàjà

Onigbeti of Igbetiland, Oba Emmanuel Oyekan Oyebisi, Afasegbejo III

Oríṣun àwòrán, PAce setters News

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Onigbeti ti ilu Igbeti, Ọba Emmanuel Oyekan Oyebisi, Afasegbejo I, ti jade laye.

Ori ade naa gori itẹ awọn baba nla rẹ lọdun 2004 ko to dagbare faye lẹni ọdun mẹtadinlọgọrin lọdun 2021.

Alaafin ti ilu Oyo, Ọba Lamidi Olayiwola Adeyemi III, ti ba ẹbi ati gbogbo awọn olugbe ilu Igbeti kẹdun iku ọba alaye naa.

Àkọlé fídíò, 'Wọ́n gba irun abẹ́ wa, irun abíyá wa, a lọ búra, ilé "Nylon" la tún ń gbé ni Mali fi ṣe iṣẹ́ aṣẹ́wó'

Ninu atẹjade kan lori Facebok ni Alaafin ti ba ẹbi atawọn eeyan nilu naa kẹdun.

Atẹjade ọhun ni "Alaafin Ọba Adeyemi III ba ẹbi, awọn ọmọ ọba atawọn eeyan ilu Igbeti kẹdun lori iku Ọba Emmanuel Oyebisi Afasegbejo I."

Skip Facebook post

Content is not available

View content on FacebookBBC kò mọ̀ nípa àwọn ohun tí ó wà ní àwọn ojú òpó tí ó wà ní ìta.

End of Facebook post

"A gbadura fun ẹbi ati araalu ti fi silẹ saye lọ ki Ọlọrun tu wọn ninu."

Àkọlé fídíò, Wòólì Alfred kú lọ́dún 1964, ó tún padà wà sí ìlú Agelu f'ọ́jọ́ mẹ́rìnlá!

Ẹwẹ, kọmiṣọna fun ọrọ agbegbe ati ohun amuṣagbara ni ipinlẹ Oyo, Abiodun Oni naa tun ti ba ẹbi oloogbe ọhun kẹdun.

Oni sọ pe ki awọn eeyan ilu Igbeti ma ṣe ba ọkan jẹ nitori oloogbe naa gbe igbe aye rere ko to dagbare faye.

Awọn ẹbi oloogbe ti ni awọn yo kede bi eto isinkun rẹ yoo ṣe lọ laipẹ.

Àkọlé fídíò, Protein Marasmus: Wo èwu tó wà nínú kí ọmọdé má ní èròjà Protein lára