Rwanda electric motorcycles: Rwanda lèwájú nínú lilo ọ̀kadà tó n lo iná ẹ̀lẹ́tíríkì

Oríṣun àwòrán, Ampersand
O ti to nkan bii ọdún méjìlá tí Didier Ndabahariye ti n fi ọkada rẹ ko ero kaakiri igboro Kigali, lorilẹ-ede Rwanda.
Ọkan lara àwọn ọlọkada tawon eeyan mọ sí moto nilu naa lo jẹ.
Laipẹ yi lo paarọ okada rẹ pẹlu orisi mii to jẹ ọkan lára àwọn akọkọ alupupu igbalode to n lo ina ẹlẹtiriki ni Africa.
"Nigba ti mo kọkọ bẹrẹ, nkan nira diẹ nitori iru ọkada yii ko mọ mi lara ati pe ẹmẹẹwa lo maa n pana"
"Amọ lẹyin asiko diẹ, mo mọ bi o ṣe n ṣiṣẹ ati gigun rẹ. Mo si bẹrẹ sí ní ri owo fi pamọ sii."

Oríṣun àwòrán, Ampersand
O wa lara awon ọgọta ọlọkada to n gun ọkada to n lo ina ẹlẹtiriiki lati ileeṣẹ Ampersand ni Rwanda.
"Mo nifẹ si awọn okada tuntun yi tori o máa n ṣiṣẹ pẹ daada lai sí wàhálà bi awọn eleyi to n lo ẹnjini. Wọn máa n rin daada loju popo, ti won kò sí kí n yọnu"
Ileesẹ tuntun Ampersand lo wa nidi iyipada yi ti wọn sì ni ìgbàgbọ pé laarin ọdún marun-un si asiko yii, gbogbo ọlọkada ni Rwanda yóò ti darapọ mọ lilo iru okada yi.
- Ìjọba àpapọ̀ kéde ètò “Operation Feed Yourself” láti pèsè ọ̀pọ̀ oúnjẹ yanturu
- Wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ ètò ìsìnkú àwọn akẹ́kọ̀ọ́ 26 tó jóná mọ́ yàrá ìkẹ́kọ̀ọ́ wọn
- Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ olórí pátápátá fún àwọn ajínigbé kan l'Ekiti
- Tóo bá ń múra láti jápaa, wò ìlànà tuntun tí Amerika gbé kalẹ̀ fáwọn tó bá fẹ́ wọ ilẹ̀ wọn báyìí
- Sanwo-Olu ṣèlérí ìrànwọ́ owó fún ètò ìsìnkú tó dára f'àwọn tí ilé alájà 21 wó pa ní Ikoyi
Afojusun yi jẹ eleyi to lagbara lati ṣe nitori o to egberun marundinlọgbọn ọlọkada èrò to n ṣe iṣẹ ni Kigali, ti won a sì máa rí irin to to wakati mẹwàá lojumọ.
Iyatọ to wa laarin ọkada to n lo ina ati eyi to n lo epo bẹtiro
Ọgá ileesẹ Ampersand, Josh Whale so iyatọ to wa laarin alupupu elépo ati eleyii to n lo ina ẹlẹtiriki.
O ni lootọ awọn elépo le rín to ọgọrun kilomita lojumọ, ṣugbọn èéfín tí wọn n tu sita kọja àfaradà.
Ṣugbọn, ko si nkan to jọ bẹẹ fun awọn to jẹ ẹlẹtiriki.
Bakan naa lo sọ pe gbigba ina si ara ọkada to n lo ẹlẹtiriki dinwo ju rira bẹtiro lọ.
Orilẹ-ede Rwanda ṣe agbekalẹ awọn nkan ìwúrí kọọkan ti yoo jẹ ki lilo ọkada ẹlẹtiriki gbooro sí.
Lara rẹ ni pe wọn mu adinku ba owo ina.

Oríṣun àwòrán, Ampersand
Ipese aaye ọfẹ fun ibi ti àwọn ọlọkada yóò ti maa gba ina sara okada wọn.
Bi ilu Eko, ni orilẹ-ede Naijiria ṣe ya ọna sọtọ fawọn ọkọ BRT, Rwanda náà se ọna tí àwọn ọlọkada ẹletiriki yóò máa rin loju popo.
Awọn ileesẹ irinna mii si ti n fifẹ han sí didarapo mọ igbesẹ yi.
Ileesẹ bi Volkwagen ni Rwanda ati Siemens ti n d'owo pọ láti ṣe awọn ọkọ ayọkẹlẹ to n lo ina.













