US travel: Orílẹ̀èdè Amẹ́ríkà ti ṣí ibodè wọn padà lẹyìn oṣù ogún

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Bẹrẹ lati ọjọ Ajé, awọn arinrin-ajo to ba ti gba gbogbo abẹrẹ ajẹsara COVID-19 wọn pe yoo lanfaani lati wọ orileede Amẹrika.
Nkan bi ọdun kan ati oṣu mẹjọ sẹyin ni wọn ti ibode ilẹ naa lasiko ti Aarẹ Donald Trump fi ni iṣakoso.
Igbesẹ yi kan awọn ti kìí ṣe ọmọ Amẹrika lati orileede ọgbọn.
Ninu wọn l'awọn to wa lati ilẹ Gẹẹsi ati awọn tó wà lati awọn orileede to wa ni Yuroopu.
Ọpọ ni ko raaye foju kan mọlẹbi wọn, ti ètò ọrọ aje irinajo afẹ si dẹnukọlẹ lasiko naa.
Yatọ si ilana pe awon to ba fẹ wọlé pada gbọdọ ti gba abẹrẹ ajẹsara, awọn ilana mi wa ti Amẹrika gbe kalẹ.
Irufẹ abẹrẹ ajẹsara COVID-19 ti Amẹrika faramọ.
Àjọ to n gbogun ti àjàkálẹ̀ aarun ni Amẹrika, CDC ni ofin lori iru abẹrẹ ajẹsara ti wọn faramọ ki eeyan to le wọ ilẹ wọn.
Awọn abẹrẹ naa re e:
•Johnson & Johnson
•Pfizer-BioNTech
•Moderna
•AstraZeneca,
•Covaxin
•Covishield
•BIBP/Sinopharm
•Sinovac
Ẹ̀rí to fihan pe eeyan ko ni aarun COVID-19 lara naa se pataki.
Yatọ si pe wọn gba abẹrẹ pe, arinrin-ajo gbọdọ mu ẹri to fi hàn pé ayẹwo COVID-19 tọka sí pé wọn kò laarun náà.
Ọjọ mẹta sí igba ti wọn ba rìn irinajo ni wọn gbọdọ ti ṣe ayẹwo yi.
Iwe ẹri yi ko pọn dandan fun awọn ọmọde, ṣugbọn awọn ti ọjọ orí wọn kòbá kọja ọdun meji sí metadinlogun yoo ṣe ayẹwo laarin ọjọ mẹta sí marun un ti wọn ba wọ Amẹrika.
Yato si iwe ẹ̀rí yi, èèyàn lè tún mu ẹri to ṣafihan pe eeyan moribọ lọwọ COVID-19 laarin oṣu mẹta sẹyìn ṣaaju irin-ajo rẹ.
Ki lo yato si ohun tó wà nílẹ̀ tẹlẹ?
Ṣaaju asiko yi Amẹrika fòfin de awọn ọmọ orilẹede wọnyi lati ma ṣe wọ ilẹ wọn nitori COVID-19.
Orileede naa ni:
- Brazil
- China
- India
- Iran
- Ireland
- Schengen (Austria, Belgium, Czech Republic, Denmark, Estonia, Finland, France, Germany, Greece, Hungary, Iceland, Italy, Latvia, Liechtenstein, Lithuania, Luxembourg, Malta, Netherlands, Norway, Poland, Portugal, Slovakia, Slovenia, Spain, Sweden, ati Switzerland)
- South Africa
- United Kingdom
Ohun tó wà nílẹ̀ bayi ni pé kò sí idiwọ mọ, fun awọn eeyan lati awọn orilẹ-ede naa lati wọ Amerika pada.
Bi eeyan ba ṣa ti gba abẹrẹ ajẹsara COVID-19 rẹ pe,kò sí idiwọ lati wọ Amẹrika nisinyii.
















