Operation Feed Yourself: Ìjọba Naijiria kéde ọ̀nà láti pèsè ọ̀pọ̀ oúnjẹ láàrín ìlú

Oríṣun àwòrán, Tolani Ali
Ijọba Naijiria ti kede eto ti yo mu ki ounjẹ pọ yanturu laarin ilu lọna ati gbogun ti iṣoro aito ounjẹ aṣaraloore.
Igbakeji Aarẹ, Ọjọgbọn Yemi Osinbajo lo kede eto naa nibi ipade kan to waye nile Aarẹ niluu Abuja.
Osinbajo sọ pe ijọba apapọ yoo ṣiṣẹ papọ pẹlu awọn ajọ kan lati ṣe agbekalẹ oko igbalode atawọn oko etile.
- 'Ọba Yorùbá kìí ṣe aláṣẹ ìkejì Orìṣà mọ́ látòní lọ! Krìstẹ́nì, Mùsùlùmí àti Àbáláyé yóò máa ṣe ayẹyẹ pọ látòní'
- Kí ló mú Princess Comedian máa wa ẹkún mu láàrọ̀ kùtù?
- Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ olórí pátápátá fún àwọn ajínigbé kan l'Ekiti
- Ajínigbé ń bèèrè N10m, "Codiene", igbó àtí oúnjẹ fún ìtúsílẹ̀ èèyàn mẹ́ta tí wọ́n gbé l'Ogun
- Wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ ètò ìsìnkú àwọn akẹ́kọ̀ọ́ 26 tó jóná mọ́ yàrá ìkẹ́kọ̀ọ́ wọn
- Ṣé lóòtọ́ ni Lateef Adedimeji àti Bimpe Oyebade fẹ́ ṣègbéyàwó lọ́tẹ̀ yìí lóòtọ́? Lateef bá BBC Yoruba sọ̀rọ̀
- 'Bí ẹni gbọ́ ikú bàbá rẹ̀ ló rí lásìkò tí a gbọ́ pé Akeredolu gbé owó ilé ẹ̀kọ́ wa sí ₦2.245m'
- Tóo bá ń múra láti jápaa, wò ìlànà tuntun tí Amerika gbé kalẹ̀ fáwọn tó bá fẹ́ wọ ilẹ̀ wọn báyìí
- Ta ló ni ilé alájá 21 tó wó pa àwọn èèyàn ní Ikoyi gan? Ìjọba Eko ti fèsì
Lara awọn to wa nibi ipade naa ni igbakeji akọwe apapọ ajọ iṣọkan abaye, UN, Amina Mohammed; awọn gomina ipinlẹ; awọn aṣoju ajọ iranwọ bii UNICEF; Bill and Melinda Gates Foundation, ajọ Aliko Dangote Foundation, atawọn ajọ agbaye mii.

Oríṣun àwòrán, Tolani Ali
Nibi ipade naa ni Osinbajo ti kede eto kan ti wọn pe ni "Fun Ara Rẹ Lounjẹ," Operation Feed Yourself, eyii ti yoo ran ijọba lọwọ lati pese ọpọ ounjẹ fun awọn araalu.
O ni "Awọn ọna kan wa ti awọn ipinlẹ ati ijọba apapọ le gba laarin asiko yii si oṣu mejila" ti yoo mu ki awọn araalu le jẹ ajẹyo ati ajẹṣẹku.
Igbakeji Aarẹ sọ pe eto naa yoo wa ni oniruru ipele bii idasilẹ awọn oko nla-nla ati oko kekeke lawọn igberiko ati lẹba ile.
Gẹgẹ bii ohun to sọ, eto naa yoo mu ki awọn araalu bii ẹnikọkọọkan, to fi mọ awọn ile ẹkọ lati da oko ti wọn silẹ.
Osinbajo sọ pe "Yatọ si pe eto yii yoo ran onikaluku atawọn idile lọwọ lati jẹ ajẹyo ati ajẹṣẹku, yoo tun fun Naijiria lanfani lati maa ko ounjẹ lọ silẹ okeere."














