Ondo fees hike: Àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ wọlé nìkan ni àfikún owó náà kàn - UNIMED

Rotimi Akeredolu Aketi

Oríṣun àwòrán, Rotimi Akeredolu Aketi

Awọn akẹkọọ kan ni fasiti ẹkọṣẹ iṣegun ijọba ipinlẹ Ondo, UNIMED, ti sọrọ lẹyin ti ijọba ipinlẹ naa ṣafikun iye owo ile ẹkọ naa ni nnkan bii ida ọgọrun un o le.

Lara awọn akẹkọọ ọhun to ba BBC Yoruba sọrọ sọ pe iroyin afikun owo ile ẹkọ naa da bi ẹni to gbọ iku baba rẹ lai ro tẹlẹ lo ri lara oun.

Awọn akẹkọọ naa to n kẹkọọ nipa iṣẹ dokita sọ pe ko rọrun lati ri owo ti awọn n san tẹlẹ, anbelete bayii ti wọn ṣẹṣẹ fi kun owo ile ẹkọ naa.

O ni "A fẹ ẹ ya were nigba ti a gbọ pe ijọba ti fikun owo ile ẹkọ wa... ẹru ba wa a ko si mọ nnkan ti a le ṣẹ nitori awọn alaṣẹ ile ẹkọ naa ko gba fun wa lati ṣe ẹgbẹ akẹkọọ ti yoo maa ja fun wa."

Bo tilẹ jẹ pe wọn ko fẹ ki a fi orukọ wọ lede, awọn akẹkọọ ọhun ni nnkan ko rọrun fun wọn, ibanujẹ nla si ni afikun owo ile ẹkọ naa jẹ.

Ọkan lara wọn sọ pe "Inu mi ko dun rara nitori baba to n tọ mi nilẹ ẹkọ yii n ṣiṣẹ ko si ri owo oṣu gba."

"Ti mo ba ti pari ni kilaasi bayii, ni ṣe ni mo maa tun lọ sinu oko lati lọ kọ ẹgẹ, ẹ jọwọ ẹ bawa bẹ gomina Rotimi Akeredolu ko ba din wa owo naa ku."

Àkọlé fídíò, 'Wọ́n gba irun abẹ́ wa, irun abíyá wa, a lọ búra, ilé "Nylon" la tún ń gbé ni Mali fi ṣe iṣẹ́ aṣẹ́wó'

Ki ni awọn alaṣẹ UNIMED sọ?

BBC Yoruba kan si awọn alaṣẹ fasiti naa lati mọ eredi afikun owo ọhun.

Agbẹnusọ ile ẹkọ naa, Ọgbẹni Temitope Oluwatayo ṣalaye fun BBC pe lootọ ni UNIMED ṣafikun owo ile ẹkọ naa, amọ ki ṣe gbogbo awọn akẹkọọ ni ọrọ naa kan."

Gẹgẹ bii ohun to sọ, awọn akẹkọọ to ṣẹṣẹ fẹ wọ ile ẹkọ ọhun nikan ni yoo san iye owo ti wọn kede rẹ.

O ni "Kii ṣe gbogbo awọn akẹkọo wa ni ọrọ afikun naa kan o, bikoṣe awọn to ṣẹṣẹ fẹ wọ fasiti naa bii akekọọ tuntun."

"Kii si ṣe pe a kan dede pinnu lati ṣafikun owo naa, ṣugbọn a wo bi ohun gbogbo ṣe ri ni akoko yii, a ko si fẹ ki ile ẹkọ rẹyin lawujọ, a ni lati bẹgbẹ pe."

"Kii ṣe owo perete ni wọn fi n kọ ẹkọ nipa imọ iṣẹgun, a ko si fẹ ki awọn akẹkọọ wa jẹ purutu lawujọ ẹgbẹ wọn, idi ree ti a ṣe fi kun owo ọhun."

Ki lo ti ṣẹlẹ sẹyin?

Akeredolu ṣàfikún owó fásitì ìpínlẹ̀ Ondo sí ₦2.245m

Rotimi Akeredolu Aketi

Oríṣun àwòrán, Rotimi Akeredolu Aketi

Ijọba ipinlẹ Ondo ti ṣe afikun iye owo ile ẹkọ ẹkọṣẹ iṣegun to wa niluu Ondo, University of Medical Sciences, UNIMED.

Awọn alaṣẹ ile ẹkọ naa lo kede afikun owo tuntun naa loju opo lori itakun agbaye.

Pẹlu afikun tuntun yii, iye owo ti awọn ti kii ṣe ọmọ ipinlẹ Ondo yoo maa san ti ni afikun to le ni ida aadọta ju iye owo ti awọn akẹkọọ to jẹ ọmọ ipinlẹ Ondo yoo maa san.

Ikede naa tun fi han pe awọn akẹkọọ eto imọ iṣegun ti kii ṣe ọmọ ipinlẹ Ondo yoo maa san ₦2.245m lọdun nigba ti awọn ọmọ onilu yoo maa san owo ti iye rẹ ko din ni ₦1.320m lọdun.

Awọn akẹkọọ lati ipinlẹ Ondo to n kẹkọọ bii Biochemistry ati Physiology yoo maa san ₦350,000 lọdun nigba ti awọn akẹkọọ lati ipinlẹ miran yoo maa san ₦400,000.

UNIMED school fees

Oríṣun àwòrán, Oladokun Bolu Samuel

Wayi o, awọn eeyan kan ti bẹrẹ si n bu ẹnu atẹ lu ijọba ipinlẹ Ondo fun afikun owo ile ẹkọ naa, paapaa lasiko ti eto ọrọ aje Naijiria dẹnukọle yii.

Lara awọn eeyan naa ni agbẹnusọ ẹgbẹ oṣelu PDP l'Ondo, Kennedy Peretei to sọ pe ijọba to wa lode l'Ondo ko kọbi si irufẹ iya to n jẹ awọn araalu.

Àkọlé fídíò, Wòólì Alfred kú lọ́dún 1964, ó tún padà wà sí ìlú Agelu f'ọ́jọ́ mẹ́rìnlá!

Peretei lo sọ ọrọ naan ninu atẹjade kan to fi ṣọwọ si awọn akọroyin.

Lasiko to n gba awọn obi ti wọn ko le san owo naa nimọran lati mu awọn ọmọ wọn kuro nile ẹkọ ọhun, o ni Akeredolu kuna lati ri pe ko si iṣẹ ni ipilẹ Ondo, ati pe ọpọ obi awọn akẹkọọ naa lo jẹ oṣiṣẹ ijọba ti ko gba owo oṣu dede.

Bakan naa lo tun ṣapejuwe iye owo ti wọn n san lawọn ile ẹkọ ijọba to yi ipinlẹ Ondo ka, bii Ekiti ati Ogun.

O ni o yẹ ki ijọba Rotimi Akereolu gbe ọrọ naa yẹwọ ko to maa fi aye ni awọn eeyan lara.

Ẹwẹ, kii ṣe iga akọkọ ree ti ijọba ipinlẹ Ondo yoo ṣafikun owo ile ẹkọ.

Ṣaaju Akeredolu lo ti kọkọ ṣafikun owo ile ẹkọ fasiti Adekunle Ajasin, to wa niluu Akungba-Akoko, eyii to mu ki ọpọ awọn akẹkọọ ọhuntu si igboro fun ifẹhonuhan lọdun 2019.