Kidnap Students: Aláàfin Oyo fa àwọn ọmọ tí wọ́n jígbé lé àwọn òbí wọn lọ́wọ́

Aláàfin Oyo fa àwọn ọmọ tí wọ́n jígbé lé àwọn òbí wọn lọ́wọ́

Oríṣun àwòrán, Oba Adeyemi/facebook

Aláàfin Oyo, Ọba Lamidi Adeyemi kẹta ti so àwọn ọmọ méjì tí wọ́n jigbé ni ìpínlẹ̀ Ogun pọ̀ pada pẹ̀lú ẹbí wọn.

Wọ́n jí àwọn ọmọ náà gbé ni àgbègbè Alágbado ní ìpínlẹ̀ Ogun.

Nínú àlàyé àwọn ọmọ náà lásìkò tí wọ́n ń fi ọ̀rọ́ wá wọn lẹ́nù wò lórí bi wọ́n ṣe dé Oyo ni wọ́n tí sọ pé àwọn géndé mẹ́ta kan ló jí wọn gbé.

Àkọlé fídíò, 'Wọ́n gba irun abẹ́ wa, irun abíyá wa, a lọ búra, ilé "Nylon" la tún ń gbé ni Mali fi ṣe iṣẹ́ aṣẹ́wó'

Àwọn ọmọbinrin méjì náà, Zaina Rafiu ẹni ọdún méjìdínlógún àti Kehinde Adeogun ọdún mẹ́rìndínlógún láti ilé ìwé Odewale Community High School Ojuurin Agbado ni ìpínlẹ̀ Ogun.

Àwọn méjèèjì ní àwọn ń lọ sí ilé ìwé wọn ni ọjọ́ náà nígbà tí mọ́tò àjèjì kan dúró ni ẹ̀gbẹ́ wọn tí wọ́n sì pàsẹ fún àwọn ọmọbinrin náà láti wọ inú ọkọ̀ lẹ́yìn tí wọ́n na ìbọn sí wọn.

Títí dí àsìkò tí àwọn ọmọ náà ń sọ̀rọ̀ wọ́n ko mọ bí wọ́n ṣe dé ìpińlẹ̀ Oyo láti ọ̀nà ilé ẹ̀kọ́ wọn.

Wọ́n ni èdè Yorùbá ni àwọn ajínígbé náà ń sọ títí tí wọn fi gbé wọn de inú igbó tí wọ́n sì di àwọn mọ́lẹ̀ tí wọ́n sì lọ.

Àkọlé fídíò, Wòólì Alfred kú lọ́dún 1964, ó tún padà wà sí ìlú Agelu f'ọ́jọ́ mẹ́rìnlá!

Ọ̀kan nínú àwọn ajínígbé náà sọ pé àyé àwọn yóò tó dópin sínú igbó ọ̀hún, lẹ́yìn tí wọ́n lọ tán ni Kehinde tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tí wọ́n jí gbé náà gbìyànjú láti tú àra rẹ̀ sílẹ̀ pẹ̀lú èyín lẹ́yìn náà ló tú ọ̀rẹ́ rẹ̀.

Kíá ni wọ́n ń sálọ, láì mọ ibi ti wọ́n ń sálọ, wọ́n ni ó tó wákàtí méjì tí wọ́n fi rìn nínú igbó kìjikìji kí wọ́n tó jásí ìgboro, lẹ́yìn tí wọ́n bèrè lọ́wọ́ àwọn ènìyàn tó ń kọja ni wọn mọ̀ pé, ìlú Oyo ni awọn wa.

Nínú ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nùwò ní wọ́n ti mọ̀ pé ọmọ Oyo ni Kehinde ṣùgbọ́n ko mọ agbo ile wọn nílùú Oyo, ọ̀dọ olónjẹ kan ni Kehinde ti ya fóònù to fi pe àwọn òbí rẹ̀ nílùú Abeokuta ki wọ́n le mọ ibi ti ó wà.

Àṣẹ̀yìnwá, àṣẹ̀yìn bọ̀, ọ̀rẹ́ bàbá Kehinde tó n jẹ Alahaji Ogunsola lọ kó wọn ni ìbi ti wọ́n wà lọ sí Ààfin ọba Adeyemi.

Lẹ́yìn ti wọ́n ko wọ́n de ọ̀dọ̀ Aláàfin ni ikú bàbá yèyé pé ilé iṣẹ́ ọ̀tẹlẹ̀múyẹ (DSS) láti mọ nǹkan ti ó ṣẹlẹ.

Ní báyìí Àláàfin ti fa àwọn ọmọ náà le àbúrò bàbá rẹ̀ Quasim Wasiu lọ́wọ́ ni ààfin ọba Lamidi Adeyemi.