Odunlade Adekola: Ẹgbẹ́ Mùsùlùmí korò ojú sí sinimá kan tí Odun gbé jáde tí wọn ló ń fi Islam tayín

Ọjọ́ méje péré ní afún ọ kí o fi yọ sínímọ́ IKU NI lójú òpó Youtube bíbẹ̀ẹ́ kọ́.... Ẹgbẹ́ THURIST

Ẹgbẹ́ ajàfẹ́tọ mùsùlùmí kan tó ń jẹ́ Ta'awunu Human Right of Nigeria (THURIST) ti ké gbàjarè pé, òṣèrè tíátà, Odunlade Adekola n fi ọ̀rọ̀ ẹsin Musulumi tayín.

Nínú àtẹ̀jáde kan ti adarí ẹgbẹ́ náà, Amofin Sulaymon Tadese fi síta lójú òpó Facebook ẹgbẹ́ náà, ló tí sọ pé Odunlade Adekola gbé fọ́nrán sinimá kan síta, níbi tó tí n fí àwọn obìnrin ẹlẹ́hà kan ṣe yẹyẹ láàrín àwùjọ.

Gẹ́gẹ́ bí ó ṣe kọ " Wọ́n ti pe àkíyèsí wa sí simina àgbéléwò kan tí mo ni ìgbàgbọ́ pé gbájúgbàjà òṣèré Odunlade Adekola lo gbe síta, èyí tí èròngbà fi yé ni pé, ó n gbìyànjú láti fi àwọn obìnrin músùlùmí ẹlẹha ṣe yẹ̀yẹ́."

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

THURIST ni nínú fọ́nrán náà tó pe àkọlé rẹ̀ ni "Iku ni", ni wọ́n ti ṣe àfihàn obìnrin ẹlẹ́hà kan tó wọkọ̀ èrò, tí ó sì n ń sọ fún onímótò pé, ìyànà ọ̀run ni òun ti fẹ́ sọ̀kalẹ̀.

O ni irú èyí n fí obìnrin ẹlẹ́hà náà ṣe yẹ̀yẹ́ ni, nítori pé kò sí ìbì kankan tó n jẹ́ ìyànà ọ̀run níbikibi ni Nàìjíríà.

Àkọlé fídíò, Ebun Oloyede Olaiya Igwe sọ ohun tí ojú rẹ̀ rí lásìkò àìsàn kídìnrín tó yọ ọ́ lẹ́nu

"Kò tán síbẹ̀, olùkọ ìtàn náà tún ṣe àfihàn òbìnrin ẹlẹ́hà náà gẹ́gẹ́ bi wèrè, tí ó sì ń gbìyànjú láti sọ àwọn òbìnrìn tó lo ẹ̀há bi ẹni ti ko tọ́ láwùjọ.

Àìní ìfàradà ẹ̀sìn nínú sinima náà dé orí góngó nígbà tí olùkọtàn ọ̀hún ṣàfihàn obìnrin tó lo ẹhá náà, níbi to ti gbé àdá sókè, tó sì fẹ́ ṣá ẹnikẹ́ni tó bá wa ni àyíká rẹ̀ pa."

THURIST ni nítorí ìdí èyí, ni àwọn ṣe n ké pé ẹgbẹ́ TAMPAN àti ọ̀gbẹ́ni Odunlade Adekola láti gbé àwọn ìgbéṣẹ̀ yìí lẹ́yọ-osọkà.

"Láti fi òpin sí ṣíṣe fíìmù "IKU NI", ki wọ́n si yọ́ kúrò lórí gbogbo ìkànni ìwòràn tó fi mọ́ Youtube láàárin ọjọ́ méje."

Ẹhonu ẹgbẹ THURIST lori sinima ti Ọdunlade Adekola gbe jade

Oríṣun àwòrán, THURIST Facebook

Bakan naa ni Thurist n fẹ kí ẹgbẹ́ fi ọgbẹ́ni Odunlade Adekola si abẹ ìbáwí ní ìlàna ofin ẹgbẹ́ TAMPAN.

Ẹgbẹ́ THURIST tún ké pe àjọ tó n mójú tó sinima tí wọn n gbé jáde láti dènà irú àwọn sinimá bẹ́ẹ̀ láti mase jáde si àwùjọ.

Bákan náà ni wọ́n ni pe kí ẹni to gbe sinima náà jáde kọ iwé ìtọ̀rọ aforíjì sí àwọn àjọ musulumi, kí wọn sì gbe jáde lójú òpó ti gbogbo ènìyàn yóò ti ri, pèlú ìdániloju pe àwọn ti yọ fọ́nran náà kúrò láàrín ọjọ́ méje.

"Bí o bá wá kọ̀ tí kò ṣe èyí, égbẹ́ náà ni àwọn ṣetán láti tẹ́síwájú láti pe TAMPAN lẹjọ́ lórí ọ̀rọ̀ náà.

Ẹhonu ẹgbẹ THURIST lori sinima ti Ọdunlade Adekola gbe jade

Oríṣun àwòrán, THURIST Facebook

Gbogbo igbiyanju BBC Yoruba lati kan si Odunlade Adekola, ka le gbọ tẹnu rẹ lori isẹlẹ yii lo ja si pabo.