Stealthing: Kí ni ìdí táwọn orílẹ̀-èdè kan ṣe rí yíyọ Kọ́ńdọ́mù láìsọ bíi ìfipábánilòpọ̀?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọpọlọpọ ọkunrin ni Naijiria lo ṣe e ṣe ko jẹbi iwa yiyọ kọndọmu kuro lara nkan ọmọkunrin wọn lasiko ibalopọ pẹlu ololufẹ wọn.
Wọn le ṣe eyi, paapaa lasiko ti wọn ba n ni ibalopọ 'to dun' pẹlu obinrin kan.
Igbagbọ iru awọn eniyan bẹẹ ni pe ibalopọ lai lo kọndọmu lo dun ju ki ọkunrin lo rọba idaabobo lọ nitori ẹran ara ti yoo maa kan ara.
- Wo oríṣiríṣi ìgbádun ibálòpọ̀ láwọn orílẹ̀èdè mìíràn
- Ọmọ ìkókó yìí bẹ̀rẹ̀ ǹkan oṣù l'ọ́mọ oṣù mẹ́rin, ó tún kojú àìsàn jẹjẹrẹ ilé ọmọ
- Genevieve ṣàlàyé ànfààní tó wà nínú ìbásùn òwúrọ̀ kùtù fáwọn lọ́kọ láya
- Wo ohun tó yẹ kí o ṣe sí ojú abẹ́ rẹ, ''vagina'' lẹ́yìn ìbálòpọ̀
- Wo ohun mẹ́rin tó lè mú ikú wá lásìkò ìbálòpọ̀
- Ṣé irúfẹ́ oúnjẹ tí ò ń jẹ́ lè jẹ́ kí o gbádùn ìbálòpọ̀ rẹ síi?
- Kí làwọn nǹkan tó lè rán ọkùnrin sí ọ̀run alákeji lásìkò ìbálòpọ̀ pẹ̀lú obìnrin?
- Ẹ̀mi arákùnrin yìí kò gbé e, ó bá aláṣẹ́wò lò dórí ìgbà ìkéje ló bá ré sálákeji
Amọ, njẹ o mọ pe titẹ ẹtọ ọmọniyan loju ni ti o ba fi ọgbọn yọ kọndọmu kuro lori nkan ọmọkunrin rẹ lasiko ibalopọ lai sọ fun obirin naa tabi pe o fọwọ si i.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Aṣẹwo kan loyun airotẹlẹ nitori onibaara rẹ yọ kọndọmu lasiko ibalopọ
Ni ọdun diẹ sẹyin, Maxine Doogan to n ṣiṣẹ aṣẹwo lasiko kan sadeede loyun.
Ko pẹ to bẹrẹ iṣẹ naa to fi loyun.
Oun ati onibaara rẹ kan ni wọn jọ n ni ibalopọ nile itura kan ni Anchorage, Alaska, lo ba ṣakiyesi pe ọkunrin naa ti fa kọndọmu yọ kuro lori nkan ọmọkunrin rẹ lai sọ fun.
Maxine sare wọ ile-iwẹ lọ, ṣugbọn nigba ti yoo fi jade pada, ọkunrin naa ti salọ.
Oriṣiriṣi ayẹwo lo ṣe nileewosan lẹyin iṣẹlẹ naa lati mọ boya o ti ko arun ibalopọ lara ọkunrin naa.
Lootọ ni ko ni arun kankan, ṣugbọn lẹyin ọsẹ mẹfa, oyun lo ri. Eyi to mu ko ṣẹ oyun naa.
Nkan ti ọkunrin yii ṣe fun obinrin aṣẹwo yii ni wọn n pe ni 'stealthing' ni ede Gẹẹsi.
Kini wọn n pe ni stealthing?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Alaye ti a le ṣe lori 'stealthing' ni pe o jẹ igbesẹ ki ọkunrin yọ tabi mọọmọ ba kọndọmu jẹ lasiko ibalopọ lai sọ fun ẹnikeji.
O le yọri si kiko arun ibalopọ, oyun airotẹlẹ, to si tun jẹ titẹ ẹtọ ọmọniyan mọlẹ.
Aṣa yii ko jẹ tuntun rara. O ti wa fun ọpọlọpọ ọdun.
Ṣugbọn o ti wa di ilumọọka lasiko yii nitori ẹkọ odi tawọn eeyan n kọ nipa rẹ lati ori ayelujara.
Eyi ko ṣẹyin bi awọn to ma n hu iwa yii ṣe n kọ awọn ẹlomii lori ayelujara, bi wọn ṣe le yọ kọndọmu laijẹ ki ẹnikeji wọn mọ.
Ni ọdun 2019, abajade iwadii kan ti wọn fi sinu National Library of Medicine sọ pe ìdá mejila awọn obinrin ti ọjọ ori wọn wa laarin ọdun mọkanlelogun si ọgbọn ọdun lo ti ni iriri 'stealthing'.
Ni ọdun naa bakan naa, awọn oluwadii ni Fasiti Monash ni Australia sọ pe obinrin kan ninu mẹta, ati ọkunrin kan ninu marun-un to n ni ibalopọ pẹlu ọkunrin, lo ti ni iriri yii.
Ṣe ẹṣẹ ni 'stealthing'?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Oriṣiriṣi ilana ofin ni awọn orilẹ-ede ni fun aṣa yiyọ kọndọmu lai sọ fun ẹni ti o n ba lopọ.
Lootọ ni ko si ofin kankan to tako iwa yii ni orilẹ-ede Naijiria, ṣugbọn awọn orilẹ-ede kan tako o.
Ni orilẹ-ede Germany, ọlọpaa kan lọ si ẹwọn oṣu mẹjọ fun pe o yọ kọndọmu lasiko ibalopọ pẹlu obinrin rẹ. O si tun san ẹgbẹrun mẹta Pọun owo itanran fun obinrin naa, ati Pọun mẹrindinlọgọrun fun lati fi ṣe ayẹwo aarun ibalopọ nileewosan.
Ẹsun ifipabanilopọ ni wọn fi kan.
Ni New Zealand bakan naa, ni ibẹrẹ ọdun yii, ẹwọn ọdun mẹta ati oṣu mẹsan-an ni wọn ju ọkunrin kan si nitori o yọ kọndọmu lasiko ibalopọ pẹlu aṣẹwo. Ẹsun ifipabanilopọ ni wọn fi kan.
Ifipabanilopọ naa ni iwa bẹẹ ninu ofin UK, Canada ati Switzerland.
Laipẹ yii ni gomina ipinlẹ California lorilẹ-ede America, Gavin Newsom, buwọlu ofin to tako 'stealthing'.
Ohun si ni ipinlẹ akọkọ nilẹ America to ṣe iru ofin naa.

















