Zamfara: Ilé aṣòfin dá aṣòfin méjì dúró fún pé 'wọ́n n ṣagbátẹrù àwọn agbébọn'

Oríṣun àwòrán, other
Ile aṣofin ipinlẹ Zamfara ti da aṣofin meji duro nitori ẹsun pe wọn n fi ọwọ sowọpọ pẹlu awọn agbebọn nipinlẹ naa.
Atẹjade kan ti agbẹnusọ ile aṣofin naa, Mustapha Jafaru Kaura fi sita lọjọ Iṣẹgun sọ pe, oṣu mẹta ni wọn fi da awọn aṣofin naa duro titi iwadii lori ẹsun ti wọn fi kan wọn yoo fi pari.
Bakan naa lo sọ pe wọn awọn asofin mejeeji naa yoo farahan niwaju igbimọ to wa fun ihuwasi nile aṣofin ati awọn ileeṣẹ eto aabo fun iwadii.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ìgbésẹ̀ tà ń gbé rèé lórí ìlera Sunday Igboho àti ìtúsílẹ̀ rẹ̀ - Ilana Ọmọ Oodua
- "Bí ń kò sún mọ́ Sunday Igboho, ogun abẹ́lé kò bá ti wáyé ní Nàíjíríà"
- Wo ìjìyà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ tó bá yọ kọ́ndọ́mù lásìkò ìbálòpọ̀ láì sọ
- "Ẹ tètè gbé Sunday Igboho lọ fún ìtọ̀jú lókè òkun, kó tó pẹ́ jù"
- Buhari, dáríjin Igboho àti Kanu láti fòpin sí ìjìjàgbara ní Naijiria - Bíṣọ́ọ́bù ìjọ Elétò
- Òbí kan kó jàńdùkú lọ ká olùkọ́ tó na ọ̀mọ̀ rẹ̀ mọ́ iléẹ̀kọ́
Awọn meji ti wọn da duro ni Yusuf Muhammad Anka, to n ṣoju ijọba Anka, ati Ibrahim Tukur to n ṣoju ijọba ibilẹ Bakura.
Amọ, awọn aṣofin mejeeji ọhun ko si nile aṣofin lasiko ti wọn kede ẹsun ati idaduro wọn.
Ẹnikan lara awọn aṣofin ile naa, Yusuf Alhassan Kanoma, to n ṣoju ijọba ibilẹ Maru North lo bẹrẹ ijiroro lori ọrọ awọn aṣofin ti wọn da duro.
O ni idi ni pe lasiko ti awọn agbebọn ji baba olori ile aṣofin naa, Oloogbe Mu'azu Magarya, n ṣe ni Anka ati Tukur n se ajọyọ rẹ.
O tun sọ pe awọn mejeeji naa lo wa nidi bi wọn ṣe pa aṣofin kan, Muhammad Ahmad lati ijọba ibilẹ Shinkafi.
Awọn aṣofin sọ pe awọn mejeeji ni wọn fun awọn agbebọn ni aṣiri bi wọn ṣe le ri aṣofin naa pa.
Ọkan lara wọn, Yusuf Muhammad Anka sọ fun BBC pe ọrọ naa lọwọ oṣelu ninu, nitori pe awọn gbiyanju lati yọ olori ile aṣofin naa nipo.

















