Ridwan Scorpion Oyekola: October 30 ni màá tún ìjà jà láti gba belt mi padà àmọ́ kò sí onígbọ̀wọ́

Àkọlé fídíò, Ridwan Oyekola: October 30 ni màá tún ìjà jà láti gba belt mi padà àmọ́ kò sí onígbọ̀wọ́

Ridwan Scorpion Oyekola tun ti ba BBC Yoruba sọrọ lori ohun to jẹ ẹdun kan rẹ lọwọ lọwọ bayii, eyi to si le se akoba fun ẹsẹ kikan to yan laayo.

Oyekola ni lẹyin osu mẹfa ti oun gba ami ẹyẹ bẹliti agbaye, lo yẹ ki oun tun ija miran ja lati tun bẹliti naa gba.

O ni osu kẹfa ọdun 2021 lo yẹ ki ija keji naa ti waye, amọ ko si onigbọwọ fun oun eyi ti ko tii jẹ ki ija naa waye.

Akansẹ agbaye naa ni ajọ to n se kokari idije naa ti n yọ oun lẹnu, ti wọn si ti fi ọjọ ija naa si ọgbọnjọ osu Kẹwa taa wa yii.

Amọ o ni titi di akoko yii, onigbọwọ kankan ko tii si fun oun lati ja ija naa, to si n ke si aarẹ mMuhammadu Buhari atawọn ọlọrọ lorilẹede yii, lati wa se iranwọ fun lori ika oun.

Oyekola ni lai si onigbọwọ, wọn le gba bẹliti agbaye naa lọwọ oun, eyi to le se akoba fun ẹsẹ kikan to yan laayo, ti yoo si da omi tutu si lọkan.