Squash: Dele Oladejo ní iṣẹ́ ńlá ni eré ìdárayá Squash, olówó àti akọni ẹ̀dá ló ń gbá a
Dokita Oludele Oladejo tii se ololufẹ ere idaraya Squash ti parọwa si ijọba apapọ pe ko se agbelarugẹ awọn ere idaraya miran yatọ si ere bọọlu nikan to gbaju mọ.
Oladejo, ẹni to se agbatẹru idije ere idaraya Squash laipẹ yii fun awọn ọjẹ wẹwẹ akẹkọọ to nifẹ si ere idaraya yii, wa fọwọ gbaya pe owo nla wa nidi ere idaraya naa.
Lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ nibi asekagba idije Squash fawọn ọjẹ wẹwẹ elere idaraya naa, Oladejo ni awọn akọni ati olowo lo n se ere idaraya Squash.
- Wo ọ̀pọ̀ àǹfààní tó wà nínú eré ìdárayá Squash fún àgbéga ìlera àti ọrọ̀ ajé rẹ
- Kamaru Usman fi ẹ̀ṣẹ́ da orí Jorge Masvidal rú láti gba ife ẹ̀yẹ
- Wenger àti Mourinho ti parí ìjà
- N kìí gbádùn ara mi tí ń kò bá jà lọ́jọ́ kan- Ango Argungun
- Wo bí o ṣe lè ṣe eré ìdárayá tí yóò fún ọ ní adùn àti okun fún ìbálòpọ̀
- Mama Arsenal ṣeé débi èrè, ẹgbẹ́ kan ti fún màmá l'ẹ̀bùn owó
- Lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọdún, ìjọba Kwara fẹ́ sọ orúkọ Rashidi Yẹkini di mánigbàgbé
Bakan naa lo fi ọwọ gbaya fun ijọba pe yoo maa ri owo ori gba nidi agbega ere idaraya Squash, ti awọn araalu yoo si tun ri isẹ oojọ se nidi ere idaraya yii.
Onimọ nipa ilera ẹda naa tun ni ere idaraya Squash maa n jẹ ki ounjẹ tete da, ti yoo si tun fun awọn ọmọ ni okun.





