Aminat Idris, aláboyún oṣù mẹ́jọ tó fi Taekwondo dára ní ìdíje National Sports Festival ni Edo

Oríṣun àwòrán, legit ng
A fi bi idan ori itage ni nigba ti arabinrin alaboyun kan, ti oyun inu rẹ ti pe oṣu mẹjọ, Aminat Idris bori ninu idije Taekwando nibi idije ere idaray gbogboogbo to n lọ lọwọ nipinlẹ Edo.
Obinrin naa to jẹ aṣoju ipinlẹ Eko nibi idije naa kopa ninu ẹka Taekwando ti wọn n pe ni Poomsae.
Poomsae ninu ere idaraya taekwando jẹ ṣiṣe afihan gbogbo ẹka taekwando (ẹṣẹ, iduro, ìpá ati bẹẹbẹẹ lọ) ni ṣiṣẹ n tẹle, lai ṣe aṣiṣe kankan.
Ninu fidio kan to gba ori ayelujara Twitter, a ri Aminat to n pa oriṣiriṣi itú ninu idije ijakadi naa.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 1
Oun ati akẹẹgbẹ rẹ kan, Arowora Roqeeb ti wọn jọ n ṣoju ipinlẹ Eko, lo jọ da ara naa.
Yatọ si pe o gba ami ẹyẹ goolu fun ipinlẹ Eko, Aminat tun gba ami ẹyẹ bàbà ati ìdẹ ni ẹka ti awọn obinrin ati gẹgẹ bi olukopa.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 2
Eyi si mu ko jẹ ọkanlara awọn elere idaraya to gba ami ẹyẹ julọ nibi idije naa.
Igba akọkọ kọ re e ti Aminat Idrees gba ami ẹyẹ ninu idije Taekwondo.
Lọdun 2018, ami ẹyẹ idẹ lo gba nibi idije ere idaraya gbogboogbo ni Naijiria.

Oríṣun àwòrán, lagos state government/twitter
Amọ ṣa, bi awọn kan ṣe n gboriyin fun, ni awọn miran n bu ẹnu ẹtẹ lu u pe idije naa lewu fun ipo to wa gẹgẹ bi alaboyun.















