Ondo disability day: Ijọba ẹ gbà wá ní ariwo tí àkàndá ẹ̀dá ń pa
Folajogun Akinlami: Ko si idile ti ko ni akanda ẹda lọdọ
Oriṣiriṣi ere idaraya lo waye nibi eto ti awọn ajọ ti kii ṣe tijoba ati ijọba ipinlẹ Ondo geb kalẹ fawọn akanda ẹda.
Awọn ere idaraya yii ni wọn kopa ninu rẹ lati mu inu ara wọn dun si ki wọn mọ pe ko si nkan ti awọn naa ko le ṣe lọna ara ọtọ.Kò sẹ́ni tó wù láti jẹ́ àkàndá, ẹ má dẹ́yẹ sí wọn mọ́- Fola
Ogbẹni Peter Olugbenga to jẹ aṣoju awọn akanda ati Ilesanmi Olatunji ṣalaye ni kikun diẹ lara ipenija to n koju awọn akanda ẹda ati ọna iranlówọ ti awujọ le ṣe
Folajogun to da ẹgbẹ arannilọwọ silẹ ati Arabinrin Ruth Olowo okere to jẹ iyaloja Akure naa sọrọ lori bi ijọba ati ẹlẹgbẹjẹgbẹ ṣe le maa ran awọn akanda ẹda lọwọ lasiko yii.