Sallah: Ẹyin ará Ondo, Eko, Ogun, Osun, Ọyo, ẹ gbàdúrà ò!

Oríṣun àwòrán, Google
Gomina ipinlẹ Ondo, Rotimi Akeredolu ti kesi awọn ọmọ Naijiria lati lo asiko ọdun salah yii lati fi gbadura fun alaafia lorilẹede Naijiria.
Akeredolu ninu atẹjade to fi lede sọ wi pe adura nikan lo le sẹgun eto aabo to mẹhẹ lorilẹede Naijiria, eleyii ti o ti jasi iku awọn ẹlomiran ni awujọ.
Ninu ọrọ tirẹ, Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu ni ki awọn ọmọ Naijiria lo asiko yii lati fi wa ilọsiwaju orilẹede Naijiria, ki wọn si sọra fun ọrọ agan to le fa iyapa ati ẹlẹyamẹya lorilẹede Naijiria.
Bakan naa ni Gomina ipinlẹ Ogun, Dapo Abiodun, Gomina ipinlẹ Ọyo, Seyi Makinde naa pe fun ki awọn ọmọ Naijiria ati awọn ẹlẹsin musulumi lo asiko Sallah yii lati fi kọ ẹkọ pataki lara ojisẹ Allah, Ibrahim to ni ibẹru Ọlọrun, to si pa ofin rẹ mọ titi ọjọ aye rẹ ninu ifẹ.
Gomina ipinlẹ Ọyo ni tire wa rọ awọn ọmọ Naijiria lati gbe igbe aye mimọ, ifẹ, ododo, ibẹru Ọlorun ati ise ore, gẹgẹ bi awọn ohun amuyanga ti eniyan le ko ninu igbe aye Ojisẹ Ibrahim nigba aye rẹ.
- Ilééjọ́! Ẹ yọ mí látìmọ́lé DSS, ó lòdì s'ẹ́tọ̀ọ́ mi- Ṣowore
- Èèyàn mẹ́rìnlá tí ọpọlọ wọ́n pé la buwọ́lù bíi kọmísọ́nà l‘Oyo - Olórí ilé aṣòfin kan sáárá
- Àwọn ọmọ Nàìjíríà kan ń dá ẹ̀bi, òmíràn ń dárò, lórí bí ológun ṣe pa ọlọ́pàá mẹ́ta
- Ẹgbẹ́ òṣèlú AAC fi ọwọ́ òsì júwe ilé fún Ṣowore!
- Ìpànìyàn, ìjínigbé ti gbàkóso ilẹ̀ Yorùbá, Buhari, tètè kéde pé ètò ààbò kò fararọ - Soyinka










