#RevolutionNow: Ṣowore ké pe ilééjọ́ láti yọọ́ látìmọ́lé DSS nítorí ó lòdì s'ẹ́tọ̀ọ́ rẹ̀

Omoyele Sowore

Oríṣun àwòrán, Facebook/Omoyele Sowore

Àkọlé àwòrán, #RevolutionNow

Oludije fun ipo aarẹ fẹgbẹ oselu The African Action Congress to sun ṣagbatẹru iwọde RevolutionNow, Ọmọyẹle Sowore ti ke pe ileẹjọgiga l'Abuja lati yi aṣẹ to pa pe ki ile iṣẹ ọtẹlẹmuyẹ DSS tii mọ le fun ọjọ marundinlaadọta.

Ṣowore to sọrọ yii nipaṣẹ agbẹjọro rẹ, Femi Falana ni bi ajọ DSS ṣe ti oun mọ le lodi si ẹtọ oun gẹgẹ bi iwe ofin orilẹede Naijiria ṣe laa kalẹ.

Idi mọkandinlogun ni Falana kọ ti ileẹjọ ni lati fi Ṣowore silẹ lahamọ.

Àkọlé fídíò, Sunday Igboho: Fulani kò leè dúró, táa bá lo ohun ta jogún lọ́dọ̀ àwọ̀n bàbá wa
Àkọlé fídíò, ''Ọjà ẹran àgbò kò yá bí ti ọdún tó lọ''

Ṣowore ni idajọ ileẹjọ to fun ile iṣẹ DSS laṣẹ lati ti oun mọ le fun ọjọ marundinlaadọta tumọ si pe ki eeyan sọ ohun to lodi sofin di ohun to tọna labẹ ofin.

Ọjọ Abamẹta to lọ ni awọn DSS mu Ṣowore ṣaaju iwode #RevolutionNow protest.

Ẹsun pe o fẹ doju ijọba bo lẹ ati pe of fẹ da alaafia ru kaakiri orilẹede Naijiria ni wọn fi kan an.

Ẹwẹ, ẹgbẹ oselu The African Action Congress ti le Sowore ati awọn mejidinlọgbọn miran fun ẹsun wi pe wọn dojuti ẹgbẹ oselu naa.

Ẹgbẹ Oselu AAC gbe igbesẹ yii ni ipade gbogboogbo ti wọn se ni ilu Owerri, ni ipinlẹ Imo.