Eid-il Kabir: Iléẹjọ́ f'òfin de Oluwo pé kò gbọdọ̀ darí ìrun ní 'EID' lọ́dún Iléyá

Oríṣun àwòrán, Facebook/Emperor Abdulrasheed Adewale Akanbi
Ileẹjọ giga ipinlẹ Oṣun ti paṣẹ pe Ọba Oluwo ti ilẹ Iwo, Oba AbdulRasheed Adewale Akanbi ko gbọdọ irun Jimọh tabi ayẹyẹ ọdun Sallah ati ayẹyẹ ọdun musulumi kankan niluu Iwo.
Aṣẹ ileẹjọ naa yoo duro titi digba ti igbẹjọ lori idaduro Baṣọrun Musulumi ilẹ Iwo. Oloye Abiola Ogundokun.
Oloye Ogundokun lo rọ ileẹjọ lati paṣẹ naa fun Oluwo, o si tun pa awọn aṣoju moṣalaṣi aringbungbun ilu Iwo sọrọ naa nileẹjọ.
- Ilééjọ́! Ẹ yọ mí látìmọ́lé DSS, ó lòdì s'ẹ́tọ̀ọ́ mi- Ṣowore
- Ẹgbẹ́ òṣèlú AAC fi ọwọ́ òsì júwe ilé fún Ṣowore!
- Lórí ìmọ̀ràn Sunday Igboho, Ẹlẹbubọn ní yóò dára kí Yorùbá padà sí àmúlò èròjà ìbílẹ̀ fún ààbò
- Ìpànìyàn, ìjínigbé ti gbàkóso ilẹ̀ Yorùbá, Buhari, tètè kéde pé ètò ààbò kò fararọ - Soyinka
- Ààrẹ Buhari ti lọ sí ìlú Daura fún ọdún Sallah
Adajọ A.O. Ayoola ka aṣẹ naa jade lọjọ Ẹti pe Ọba AbdulRasheed Adewale Akanbi ko gbọdọ dari eto irun lọjọ Jimọh tabi nibi ayẹyẹ ọdun awọn musulumi kankan fun asiko yii.
Agbẹjọro fun Oloye Ogundokun, Opeyemi Adewale Esq. tun rọ ileẹjọ lati fofin fe Oluwo lori awọn nnkan miiran.
Ṣugbọn ilẹjọ ti sun igbẹjọ siwaju si ọjọ kọkandinlogun oṣu kẹjọ ọdun yii.
Nigba ti BBC Yoruba kan si Oluwo lori aago, Ọba Oba AbdulRasheed Akanbi kọ lati sọrọ si aṣẹ ileẹjọ.










