Sunday Igboho: Àwa ni à ń ná 95% owó ẹjọ́ láti tú Igboho àtàwọn ajìjàgbara míì sílẹ̀ látìmọ́lé

Sunday Igboho

Oríṣun àwòrán, Ilana Omo Oodua

Ẹgbẹ ajijagbara ilẹ Yoruba, Ilana Ọmọ Oodua ti sọ pe awọn ko dakẹ tabi kawọ gbera lori aisan to n ṣe oloye Sunday Igboho ati bo ṣe maa gbadun.

Akọwe gbogbogbo ẹgbẹ naa, Opeoluwa George Akinola lo fi ọrọ naa lede ninu ifọrọwerọ kan pẹlu BBC Yoruba.

Akinola ni bo tilẹ jẹ pe ẹgbẹ awọn kii ṣe ẹgbẹ dokita, ṣugbọn gbogbo ilakaka awọn ni pe ki ijọba fi Igboho silẹ ninu ahamọ to wa ni Benin.

O ni "Ki ijọba Naijiria ma baa kabamọ lori ọrọ yii, ati ki ijọba Benin ma baa fi ika hanu lori ọrọ ti ko mọ ọwọ-mẹse ninu rẹ, o yẹ ki wọn fi Sunday Igboho silẹ ko maa lọ ni alaafia."

"Lootọ ni pe Ilana Ọmọ Oodua kii ṣe dokita, ṣugbọn ohun ti a n ṣe ni pe ki a maa pariwo sita pe ki wọn fi Sunday Igboho silẹ nitori awọn ọmọ ẹgbẹ wa kii ja, bẹẹ si ni a ki n ṣe jagidijagan ki wọn to kọlu Igboho."

Àkọlé fídíò, Sunday Igboho‘s Birthday: Àwọn olólùfẹ́ Igboho rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí ìjọba Benin láti túu sílẹ̀,

"Ohun ti a n sọ fun ijọba ni pe, ẹni ẹlẹni to n ja fun ominira ilẹ Yoruba lọna to ba ofin mu, o yẹ ki wọn fi silẹ ko maa lọ layọ ati alaafia."

Akinola sọ pe oorekore ni ẹgbẹ Ilana Ọmọ Oodua maa n kan si Igboho ninu atimọle to wa.

Ni ti pe Ilana Ọmọ Oodua ti pada lẹyin Igboho lati igba to ti wa ni atimọle, o ni ko si ohun to jọ bẹẹ.

Gẹgẹ bii ohun to sọ, lati igba ti Igboho ti darapọ mọ ẹbẹ Ilana Ọmọ Oodua, awọn ko pada lẹyin rẹ.

O ni "Ọmọ ọkọ Yoruba ni wa, a kii ṣe ọmọ ale, lati igba ti Igboho ti wa ni ahamọ, a ko fi silẹ, bẹẹ si ni gbogbo awọn ọmọ wa ti wọn ko l'Eko lasiko iwọde Yoruba Nation lọjọ kẹta, oṣu Keje, gbogbo wọn ni a ja fun."

Akọwe ẹgbẹ naa sọ siwaju si pe awọn lo na owo to pọ ju ninu awọn owo ti wọn fi ṣe ẹjọ Igboho ati gbogbo awọn ilẹ Yoruba ajijagbara mii ti ijọba Naijiria fi ṣikun ofin mu lọna aitọ."

Àkọlé fídíò, Ridwan Oyekola: October 30 ni màá tún ìjà jà láti gba belt mi padà àmọ́ kò sí onígbọ̀wọ́

O ni "Gbogbo awọn ọmọ wa ni a n ja fun, akaimoye awọn amofin ti a gbe dide ni Naijiria ati ni Benin republic ti wọn n ja fun ominira Sunday Igboho."

"Ilana Ọmọ Oodua lo na ida màrúndínlọ́gọ́rùn ún gbogbo owo ti wọn fi n ja fun ominira awọn ti wọn wa ni atimọle."

"A ṣi n ri Igboho lojojumọ ti a ba fẹ ri wọn, gbogbo awọn agbẹjọro wa lati orilẹ-ede France ati kaakiri agbaye lo n ṣiṣẹ lojojumọ lati ri daju pe Igboho atawọn mii to wa ni atimọle ni wọn gba itusilẹ."

O pari ọrọ rẹ pe "Ijan yii kii ṣe ija Sunday Igboho nikan, kii sii ṣe ija baba Akintoye nikan, ija gbogbo wa ni."

"Ohun ti a dẹ n fẹ ni ki a kuro lara Naijiria, a ko fẹ atunto kankan, ni ṣe ni a fẹ da duro."

Àkọlé fídíò, Olota Of Ota: N kò fara mọ́ ìyapa Nàíjíríà, ìṣèjọba ẹlẹ́kùnjẹkùn ní ọ̀nà àbáyọ