Àṣìṣe márùn ún tí àwọn lọ́kọláyà ńṣe nípa owó àti níní ìmọ̀ nípa ara wọn

Ọkọ ati iyawo kan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Jijiroro lori iṣuna ati eto inawo jẹ ohun kan to n fa ọpọlọọ wahala fun awọn eeyan paapaajulọ awọn lọkọlaya.

Bi a ba wo ọrọ gbogbo, iṣoro eto inawo ati iha ti koowa n kọ si ọrọ owo lee fa oniruuru nnkan fun ọpọlọpọ eyan eleyi to mu ki sisọrọ nipa rẹ o fẹ nira pupọ.

O ṣe pataki ki a sọrọ nipa ọna ti a le gba ṣe amojuto owo tabi iṣuna wa pẹlu awọn ọkọ tabi iyawo wa ki o ma baa fa wahala ni ọjọ iwaju. Amọṣa, bi o ko ba tii ni anfani lati ṣeto ijiroro yii bayii, o dara ki o tete wa aye fun.

Ninu iṣẹ iwadii ijinlẹ kan to waye laipẹ yii, lori awọn ohun to n fa wahala laarin awọn lọkọlaya, ohun marun un lo jẹyọ lori ohun ti awọn lọkọlaya n koju nipa ọrọ owo ati ọna ti wọn le gba yanju rẹ.

1.Aisi asiko fun ijiroro lori inawo ninu igbeyawo tabi ifẹ:

Ọpọlọpọ nnkan to ṣe pataki fun igbesi aye wa, gẹgẹ bi riri dokita tabi akọṣẹmọṣẹ nipa itọju eyin; bẹẹ gẹgẹ ni o yẹ ki a maa ṣe lori ọrs owo.

Sisọrọ nipa owo ati inawo lee nira pupọ, ṣugbọn o ṣe pataki fun igbeyawo lati kogoja.

aworan akara oyinbo igbeyawo kan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ṣe eto asiko to dara julọ fun iwọ ati ololufẹ rẹ lati jiroro nipa inawo yin. Maṣe duro de igba ti ẹnikan ninu ẹyin mejeeji ba na owo to gọbọi lati ra ohun kan tabi nigba ti iṣoro iṣuna ba waye.

Ohun to ṣe pataki ni pe ki ẹ joko sọrs lori inawo yin, o lee da lori bi ẹ ṣe n nawo si, ohun ti ẹ n san owo fun, bi iṣuna ṣe n ri tabi fifi owo pamọ fun ohun kan to ṣe pataki. Ohun to ṣaa ṣe pataki ni pe ki ẹ fi asiko silẹ lati jiroro lori owo.

Aworan ọkọ igbeyawo kan

Oríṣun àwòrán, Thinkstock

2.Aisi imọ nipa eto inawo ọkọ tabi iyawo rẹ

Ọna ti o ba gba na owo rẹ lawọn asiko kan sẹyin lee ni ipa lori ọna ti o o gba na owo rẹ lasiko yii, eyi si ni idi ti lọkọlaya lati mọ ipo ti eto inawo ọkọ tabi iyawo wọn wa.

Bi o ba lee mọ nipa ilana inawo atẹyinwa ololufẹ rẹ, yoo ran ọ lọwọ pupọ lori bi ẹ ṣe n na owo yin lọwọlọwọ.

Bi ololufẹ rẹ ba wa lati idile ti o lowo, ti owo kii ṣe iṣoro fun, o ṣeṣe ki ọna ti o gba n fowopamọ o ma dun mọ ọ ninu pupọ.

aworan akara oyinbo igbeyawo kan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

3.Kikuna lati gbe ilana kan naa kalẹ lori iṣuna

Ni kete ti o ba ti mọ itan nipa iṣuna ololufẹ rẹ, nibẹ loo ti le mọ nipa ilana ti wọn fi n na owo ti yoo si ran ọ lọwọ lati maṣe bọ sọwọ aṣiṣe owo.

Lasiko ti ẹ ba n ṣeto afojusun inawo yin, iwọ ati ololufẹ rẹ gbọdọ joko jiroro lati mọ awọn ohun gan ti ẹ fẹ gan ni pato.

Ọpọ awọn lọkọlaya lo maa n gba pe ololufẹ wọn fara mọ ohun ti wọn fẹ nipa iṣuna lai sọrọ rẹ rẹ. Lẹyin o rẹyin ni wọn yoo wa rii pe irọ ni wọn n pa.

Àkọlé fídíò, Latifat Tijani: Ìjọba Naijiria ń ṣèlérí láti mọ́ rírì mi àmọ́ láti 2016, pàbó ló ń já sí

4.E maa ṣe eto iṣuna ti ẹyin mejeeji ko fara mọ

Gẹgẹ bi lọkọlaya, ẹyin mejeeji nilo lati jiroro lori awọn idojukọ yin nipa inawo, dukia ti ẹ ni ati iye owo oṣu ti ẹni kọọkan yin n gba.

Lẹyin eyi, ṣe ilakalẹ inawo yin bii owo ori, sisan owo san an diẹdiẹ lori ọkọ rira. Nitori pe dandan ni sisan awọn owo wọnyii, o rọrun lati tete bẹrẹ si ni ṣeto iṣun alori wọn.

Aworan ifẹ

Oríṣun àwòrán, Alamy

5.Maṣe faye gba ẹnikẹni ninu yin lati fi 'owo'pamọ

Lọpọ igba ni edeaiyede yoo maa waye lori iṣuna yin bi ọkan ninu awọn lọkọlaya ba n yọ ninu aṣuwọn ajumọni wọn lati nawo fun ohunkohun.

Nitori eyi, o ṣe pataki ki ẹyin mejeeji ṣe eto lori bi ẹ o ṣe maa na owo lsna ti ko ni ṣokunkun si ẹni keji.

Àkọlé fídíò, Olota Of Ota: N kò fara mọ́ ìyapa Nàíjíríà, ìṣèjọba ẹlẹ́kùnjẹkùn ní ọ̀nà àbáyọ

Fifi ara pamọ fun ololufẹ rẹ lori ọrọ owo, kaadi igbowo ATM rẹ ati awọn ohun tuntun ti o n gbero lati ra lewu pupọ. Ohun to ṣe pataki naa ni ki ẹyin mejeeji jẹ olootọ si ara yin.

Bi o ba ti n di pe ẹyin mejeeji ko lee ṣalaye ohun ti ẹ n ra fun ara yin nitori ero pe ẹnikeji rẹ ko ni fọwọsi ohun ti o fẹ ra naa, a dara ki ẹ jumọ joko jiroro pọ lori rẹ