Femi Fani-Kayode: Àlàyé rèé lórí bí wọn ṣe lò mí láti bá Sunday Igboho sọ̀rọ̀ èyí tó dènà ogun abẹ́lé

Femi Fani-Kayode ati Sunday Igboho

Oríṣun àwòrán, real_ffk/Instagram

Ilumọọka oloselu to sẹsẹ lọ lati inu ẹgbẹ oselu PDP bọ si APC, Oloye Femi Fani-Kayode ti sọrọ lori ọna ti ijọba apapọ fi doola ogun abẹle ti ko ba waye ni Naijiria lati ipasẹ ẹlẹya mẹya.

Bakan naa ni Fani-Kayode tun sọrọ nipa awọn ajọsepọ rẹ pẹlu gbajumọ ajijagbara fun ilẹ Yoruba, Oloye Sunday Igboho, to fi mọ awọn ohun ti wọn dijọ gbe inu yara sọ.

Oloye Femi Fani-Kayode sisọ loju awọn ọrọ yii lasiko to n kopa lori eto tẹlifisan AIT kan, Talking Violence, ti wọn gbe sori afẹfẹ lalẹ ọjọ Isẹgun.

Fani-Kayode kede pe ogun abẹle ko ba waye ni Naijiria amọ wọn tete doola rẹ ni ko fi seese, ti Ọlọrun si lo oun ati gomina ipinlẹ Kogi, Yahaya Bello lati pa ina isẹlẹ naa.

O ni Igboho ti di ilumọọka laarin awọn ọmọ Yoruba lori ayelujara lasiko to fun awọn Fulani to wa nilẹ Yoruba ni gbedeke pe ki wọn palẹ ẹru wọn mọ nilẹ, to si se amusẹ ọrọ rẹ.

Nigba to n sisọ loju ohun to pa ohun ati Sunday Igboho pọ ati idi to fi sun mọ Igboho, Fani Kayode ni isẹlẹ kan lo waye, ti wọn pe oun si lati lọ ba igboho sọrọ.

Àkọlé fídíò, FFK: Buhari ló ń fún àwọn Fulani láàyè láti máa pa ènìyàn'

Gomina Kogi, Yahaya Bello lo pe mi lati da si bi Igboho se le awọn Fulani nilẹ Yoruba:

Fani-Kayode ni lalẹ ọjọ kan ni oun gba ipe kan ni oru lati ọdọ gomina ipinlẹ Kogi, Yahaya Bello, ẹni ti awọn ti dijọ n ni ajọsepọ lasiko igba naa.

O ni oun lọ jẹ ipe rẹ, asiko yii si ni awọn ontaja to n ko ounjẹ wa lati ẹkun ariwa wa si ẹkun guusu Naijiria fi aake kọri lati ko ounjẹ wa silẹ Yoruba.,

O ni asiko ti laasigbo bẹ silẹ ni agbegbe Shasha nilu Ibadan ni ọrọ naa waye eyi to mu ẹmi awọn ọmọ Yoruba ati Hausa kan lọ.

Fani Kayode fikun pe gbogbo aayan ni wọn ti sa saaju lati jẹ ki awọn o0ntaja ounjẹ naa maa ko ounjẹ pada wa si ẹkun guusu amọ ti wọn faake kọri, idi si ree ti Bello fi ke si oun.

Fani-Kayode salaye pe aarẹ Muhammadu Buhari ti kesi gomina Yahaya Bello pe ko wa ọna lati pari aawọ naa laarin ọjọ mẹta, ki kiko ounjẹ wọle si pada si ẹkun guusu Naijiria.

"Idi ti Yahaya Bello se fẹ ki n wa lara ikọ ti yoo duna dura naa ni pe awọn eeyan ẹkun ariwa ti n dunkooko pe awọn yoo bẹrẹ si ni pa awọn eeyan ẹkun guusu.

Igbesẹ naa si lo ti foju han pe yoo bẹrẹ laipẹ ti a ko ba tete wa nnkan se si, ohun ti wọn si n fẹ ni pe ki n ba Sunday Igboho sọrọ.

Wọn fẹ ki Igboho fi ọwọ sọya pe tawọn eeyan ẹkun ariwa ba bẹrk si ko ounjẹ wa si ilẹ Yoruba pada, aabo yoo wa fun ẹmi ati dukia wọn.

Ni asiko yii, awọn eeyan lati ariwa Naijiria ti n ko aasa wọn lọpọ yanturu kuro ni ẹkun guusu Naijiria, ti wọn si pada sile."

Àkọlé fídíò, Sunday Igboho fulani ultimatum: Àwọn ará Kebbi àti Zamfara ló n jínígbé ní Oke Ogun- Serik

Mo sun mọ Sunday Igboho pupọ ni wọn se ni ki n ba sọrọ:

Fani-Kayode wọn mọ pe oun sun mọ Sunday Igboho bii isan ọrun ni wọn se ke si oun lati lọ ba sọrọ pe iwa igbẹsan kankan ko ni waye.

O ni awọn eeyan ariwa naa salaye pe lootọ ni ẹmi awọn eeyan awọn kan ti ba isẹlẹ naa lọ lasiko ti rogbodiyan kan waye ladugbo Lekki, nibi ti wọn ti sun sọọbu awọn Hausa.

Bakan naa si lo ni wọn sọ pe awọn tun padanu awọn eeyan Ariwa lasiko lasiko laasigbo to waye ni adugbo Shasha nilu Ibadan.

"Yahaya Bello wa sọ nkankan to fọwọ ba mi lọkan, o ni ijọba apapọ to ja fitafita lati ri daju pe isẹlẹ ipaniyan naa ko waye, to si n daabo bo ẹmi awọn eeyan guusu Naijiria lapa oke ọya.

A wa pada sinu yara, nibẹ si ni mo ti pe Sunday Igboho, mo si sọ fun pe mo wa lọdọ gomina Kogi, to si n gbọ gbogbo ohun ta fẹ sọ.

Sunday Igboho fi ọwọ gbaya pe oun yoo lewaju awọn eeyan Ariwa to n ko ounjẹ bọ lai si ewu:

Fani-Kayode ni oun salaye fun Igboho nipa ohun ti oun fẹ ko se, eyi ni pe ko fi ọwọ gbaya pe ijamba kankan ko ni se awọn eeyan Ariwa to n ko ounjẹ wa silẹ Yoruba.

"Igboho da mi lohun pe to ba jẹ pe nnkan ti mo fẹ niyẹn, o wa fọwọ gbaya pe funra oun gan ni oun yoo lewaju wọn ls sibi ti wọn yoo ti ja ounjẹ wọn silẹ, ti mimi kankan ko si ni mi wọn.

Bakan naa ni Igboho ba gomina Yahaya Bello sọrọ funra rẹ ati awọn eeyan jankan jankan mẹrin miran ti wọn wa nibẹ.

Ni kete ti Igboho si fi ọwọ idaniloju yii sọya ni idunkooko to n waye lati apa oke ọyape awọn yoo maa pa awọn ara guusu lọ silẹ patapata."

O fikun pe ni kete tawọn eeyan yii gbọ ohun Sunday Igboho ni skunrin to wa nidi igbesẹ lati maa kọlu awọn eeyan guusu Naijiria jade sita pe awọn ko ni gbe igbesẹ naa mọ.

Ko tan sibẹ, Fani-Kayode ni awọn tun ba awọn gomina kan nilẹ Yoruba sọrọ lati jẹ ki wọn mọ awọn igbesẹ ti awọn gbe naa, ti gbogbo wọn si fi ọwọ si.

O wa fi ọwọ gbaya pe, ti oun ko ba sun mọ Igboho, bawo ni yoo ti seese lati ba sọrọ, ti alaafia yoo si jọba, eyi to dena ogun abẹle ti ko ba waye ni Naijiria.

Àkọlé fídíò, Ridwan Oyekola: October 30 ni màá tún ìjà jà láti gba belt mi padà àmọ́ kò sí onígbọ̀wọ́