AfDB Akinwunmi Adesina: Ó yẹ kí Naijiria wá ọ̀nà míì láti pa owó wọlé yàtọ̀ sí owó epo nìkan

Akinwumi Adesina

Oríṣun àwòrán, Akinwumi Adesina

Aarẹ banki idagbasoke ilẹ Afrika, AfDb, Akinwunmi Adesina ti bẹrẹ si n kọminu lori bi ijọba Naijiria ṣe n ya owo lawọ orilẹ-ede mii.

O ni iye gbese ti Naijiria n jẹ pọ ju iye owo to n wọle fun lọ ni nnkan bii ida mẹtalelaadọrin.

Ileeṣẹ ijọba apapọ to n ri si ọrọ gbese, DMO, sọ ninu oṣu to kọja pe iye gbese ti Naijiria ti jẹ bayii ti le ni tiriliọnu marundinlogoji.

Ninu eto iṣuna ọdun 2022 to jẹ nnkan bii tiriliọnu mẹrindinlogun, ijọba apapọ ya tiriliọnu mẹta o le diẹ sọtọ lati fi san gbese, eyii to jẹ nnkan bii ida mejilelogun apapọ eto iṣuna ọhun.

Nigba to n sọrọ nibi ipade awọn minista Naijiria to waye l'Abuja, Adesina sọ pe nkan ko ṣenu ire fun eto ọrọ aje Naijiria lẹyin iṣiro iye owo to n wọle ati iye to n jade fun sisan gbese.

Àkọlé fídíò, Latifat Tijani: Ìjọba Naijiria ń ṣèlérí láti mọ́ rírì mi àmọ́ láti 2016, pàbó ló ń já sí

O ni "Naijiria gbọdọ wa ojutu si ọrọ awọn gbese to n jẹ, kii tilẹ n ṣe ọrọ gbẹsẹ yẹn gan ni koko bayii bi koṣe bi Naijiria yoo ṣe san awọn gbese naa pada."

"Iṣoro Naijiria ni bi yoo ṣe maa pa owo wọle ni pato, ṣugbọn owo epo ni Naijiria fi n ṣọrọ bayii, eyii to ko ida marunlọgọrin iye owo to n pa wọle.

"O yẹ ki Naijiria wa awọn ọna mii ti yoo fi maa pa owo wọle yatọ si owo epo nikan."

Adesina rọ ijọba apapọ lati wa gbogbo ọna ti owo yoo fi maa wọle si apo rẹ dipo ko lọ maa ya owo lawọn orilẹ-ede miran.

Lẹyin lo gboriyiun fun ijọba lori akitiyan rẹ lati mu idagbasoke ba eto ọrọ aje awọn aladani atawọn owo to ya sọtọ fun ẹka naa.

Aarẹ AfDB naa pari ọrọ rẹ pe ijọba gbọdọ jawe sobi ipese awọn ohun amayedẹrun ki ara le rọ gbogbo mutumuwa.

Àkọlé fídíò, Olota Of Ota: N kò fara mọ́ ìyapa Nàíjíríà, ìṣèjọba ẹlẹ́kùnjẹkùn ní ọ̀nà àbáyọ