President Buhari on Lagos/ Ibadan expressway: Ààrẹ Buhari ni ọdún 2023 ni iṣẹ́ yóò parí lórí òpópónà Eko si Ibadan

Aarẹ Buhari ati Igbakeji rẹ, Osinbajo n ki ara wọn

Oríṣun àwòrán, Tolani Alli

Aarẹ Mohammadu Buhari ti orilẹede Naijiria ti ṣalaye igba ti atunṣe opopona marosẹ Eko si Ibadan to nlọ lọwọ yoo pari.

O ti to ọdun diẹ bayii ti iṣẹ atunṣe ti bẹrẹ lori opopona marosẹ ọlọgọfa kilomita naa ṣugbọn ti ko tii pari.

Aarẹ Buhari ṣalaye nibi ipade apero ayẹwo ibi ti iṣẹ de duro fawọn minisita nilu Abuja pe eto iṣuna idagbasoke ohun amayedẹrun ti aarẹ gbe kalẹ ni wọn yoo fi yanju rẹ.

O ni lasiko iṣejọba oun ni wọn yoo pari rẹ lọdun 2023.

Bakan naa lo sọ pe iṣejọba oun yoo tun pari afara keji lori odo Ọya ti wọn n pe ni Second Niger bridge pẹlu ki iṣejọba oun to kuro lọdun 2023 pẹlu.

Àkọlé fídíò, Olota Of Ota: N kò fara mọ́ ìyapa Nàíjíríà, ìṣèjọba ẹlẹ́kùnjẹkùn ní ọ̀nà àbáyọ

Opopona maroṣẹ naa ati ipo to wa jẹ eyi to ks ọpọlọpọ ọmọ Naijiria lominu ki wọn to bẹrẹ atunṣe rẹ eyi to ti n fẹrẹ kọja ida aadọta bayii.

Opopona ọhun lọpọ gba pe o jẹ opopona ti awọn ọkọ n rin ju lorilẹede Naijiria.