Sale of baby born by mentally challenged wowan: Òṣìṣẹ́ ìjọba méjì tó ta ọmọ aláàrùn ọpọlọ l'Ondo fojú bálé ẹjọ́

- Author, Olumide Owaduge
- Role, BBC Yoruba, Lagos
Awọn olupẹjọ ninu igbẹjọ awọn oṣiṣẹ ijọba meji, Adeyemi Sarumi ati Florence Orisamehin lori ẹsun jiji ọmọ arabirin Deborah Olorundare ti o ni ipenija ọpọlọ ni ipinlẹ Ondo ni wọn ti fi orukọ ẹlẹri mẹwa silẹ lati gbe ẹjọ wọn lẹsẹ.Awọn oṣiṣẹ agba meji naa nile iṣẹ to n mojuto ọrọ awọn obirin ati idagbasoke awujọ nipinlẹ Ondo ni wọn koju ẹsun ilẹdi apo pọ ati ijinigbe leyi ti wọn ni awọn ko jẹbi rẹ.Lẹyin ti wọn ko awọn ẹni afẹsunkan naa de iwaju onidajọ Adeyemi Fasanmi ti ile ẹjọ giga ipinlẹ Ondo to kalẹ si ilu Akure, adari awọn agbẹjọro awọn olupẹjọ, Bunmi Koyenikan, sọ pe ijọba ti ṣetan ẹjọ bi ko ṣe ti iwe ti awọn olujẹjọ beere fun.Koyenikan ni awọn mẹta ninu awọn ẹlẹri ti wọn fẹẹ pe ni wọn wa nile ẹjọ, ti awọn toku si ṣetan lati yọju lakoko ti ile ẹjọ ba ṣetan lati ri wọn.Agbẹjọro awọn afẹsunkan mejeeji, Steve Adebọwale ati Victor Olatoyegun, sọpe wọn ko le tẹsiwaju pẹlu ẹjọ naa nitori pe wọn nilo lati gba awọn iwe akọsilẹ kan latọwọ awọn olupẹjọ lati fi ṣegbe lẹyin ẹjọ wọn.Awọn iwe akọsilẹ naa lofimọ awọn nkan ti olupẹjọ fẹ lo lati fi ṣagbekalẹ ẹjọ wọn, akọsilẹ ẹri awọn olujẹri ti ajọ DSS ati awọn eṣọ alaabo miran fọrọ wa lẹnu wo, papajulọ eyi to tako awọn afẹsunkan .Wọn waa bẹbẹ beeli f'áwọn afẹsunkan naa.Ninu ìdájọ rẹ, onidajọ Fasanmi fun Sarumi and Orisamehin ni beeli miliọnu kan naira ati oniduro wọn ti o gbọdọ jẹ oṣiṣẹ ijọba ti owa ni akaṣọ kejila soke.O fun awọn olujẹjọ ni ọsẹ kan lati ṣe gbogbo eto beeli wọn, o si sun igbẹjọ si ọjọ kejidinlogun oṣu kini odun 2022 ki atotonu le bẹrẹ ni pẹrẹwu.Onidajọ Fasanmi kọ ẹbẹ agbẹjọro Adebowale lati maṣe jẹ ki awọn akọroyin bawọn pejọ fun ẹjọ naa lori ẹsun pe awọn kan lara wọn gbe iroyin kobakungbe nipa awọn afẹsunkan.Ninu ọrọ rẹ "ẹjọ yi jẹ eyi ti o kan ara ilu. Ako le sọpẹ ki awọn akọroyin ma bawa pejọ. Ti wọn ba kọ iroyin ti ko tọ, ẹ pe wọn lẹjọ. Emi ko ni agbara lati paṣẹ lati majẹ ki awọn akọroyin maa wa sile ẹjọ. Bẹẹ ni ẹ ko tii tọka si iroyin kan ti wọn kọ ti o tabuku yin"
Wọ́n ta ìkókó ọmọ mi, wọ́n gbé abirùn ọmọ lé mi lọ́wọ́ - Obìrìn aláàrùn ọpọlọ figbe ta
Fun ẹsun igbimọpọ lati ta ọmọ arabirin kan, Deborah Olorundare to ni arun ọpọlọ, awọn oṣiṣẹ ijọba meji, Adeyemi Sarumi ati Florence Orisamehin ti farahan niwaju ile ẹjọ giga kan niluu Akure.
Awọn oṣiṣẹ ijọba mejeeji yi ni wọn n koju ẹsun ipadi apo pọ ati jiji ọmọ gbe niwaju onidajọ Adeyemi Fasanmi ti ile ẹjọ giga ipinlẹ Ondo.
Ọmọ Deborah ti wọn tọju si ile awọn ọmọ alailobi nipinlẹ Ondo ki iya rẹ fi le gbadun ni awọn afurasi naa ta fun obirin kan ni ọpọlọpọ naira.
- Bó ṣe òṣèlú náà ló gbà, a léè fi wo ọ̀rọ̀ Sunday Igboho - Abubakar Malami
- Wọ́n tún ti yọ òkú èèyàn méjì síi níbi ilé tó wó l'Eko, ó di èèyàn 45 tó kú níbẹ̀ báyìí
- Tí ó kó bá sùn ní aago yìí sí aago yii, àkóbá tí ò ń ṣe fún ìlera ọkàn rẹ nìyìí
- Taa ni arẹ̀wà obìnrin, Emmanuella Ropo tí ìròyìn n sọ pé òun ni ìyàwò K1 tuntun?
- Ìjà bẹ́ sílẹ̀ láàrín ọmọ ìyá méjì ni Yobe, ni wọ́n bá gé ara wọn ní apá jábọ́.
- "Ọmọ kan ṣoṣo tó bí fún mi ni wọ́n gún lọ́dún mẹ̀ta sẹ̀yìn kí wọ́n tó gún òun náà pa báyìí"
- Oluwo ti yó tán, ó ń wá bẹ́kùn bẹ́kùn kiri, àwọn òrìṣà tó ń tàbùkù ṣì ń wò ó lọ́wọ́- Ọba Ogboni ìwásẹ̀
- 'Ẹni kọ̀ọ̀kan tó fẹ́ rà nínú ilé alájà 21 tó wó l'Eko ti ṣàdéhùn láti san N206m sí N1.24bn kó tó wó'
- Àrùn jẹjẹrẹ ló mú ìyàwó mi lọ, àmọ́ gbogbo wa la ó dágbére lọ́jọ́ kan- Pásítọ̀ Odukoya
- Mo gbàgbọ́ nínú Ọlọ́run Mẹ́talọ́kan ló jẹ́ kí n bá Oluwo ti Iwo pé níbi Ọdún Olodumare - Òṣèré Jumoke Odetola
Deborah, to sọ pe ọmọbirin ni oun bi, ni wọn gbe ọmọkunrin kan ti ko gbadun fun lẹyin ti ara rẹ ya tan leyi to mu ko figbe bọnu.
Ajọ ọtẹlẹmuyẹ DSS ni wọn ṣe ọfintoto ọrọ naa ti wọn si fi abọ iwadi wọn ṣọwọ si ijọba leyi to mu ki wọn fa Sarumi ati Orisamehin de waju adajọ.
Awọn to yọju sile ẹjọ laarọ yii ni awọn oṣiṣẹ ijọba meji ti wọn fẹsun kan, agbẹjọro wọn, ẹbi ati awọn agbẹjọro ijọba ti arabinrin Bunmi Koyenikan dari wọn.
Ẹwẹ, ohun ti a gbọ ni pe obinrin ti awọn afurasi yii ta ọmọ naa fun ti tẹkọ leti lọ si oke okun, ti ko si ṣeni to le sọ akoo ti yoo pada wa si Naijiria.
Ki lo ti ṣẹlẹ ṣeyin?
Ọwọ́ tẹ àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba méjì tó ta ọmọ aláàrùn ọpọlọ ní N1m l'Ondo

Oríṣun àwòrán, succo /Pixabay
Ọwọ ofin ijọba ipinlẹ Ondo ti tẹ awọn oṣiṣẹ rẹ obinrin meji kan ti wọn fẹsun kan pe wọn ji ọmọ obinrin to ni arun ọpọlọ, ti wọn si ta ọmọ naa ni miliọnu kan naira.
Awọn obinrin naa, Sarumi Adeyemi ati Orisamehin Florence Bosede jẹ ọga agba nileeṣẹ ijọba to n ri si ọrọ awọn obinrin.
Lẹyin ti ileeṣẹ naa ti kọkọ da seria fun wọn, won tun foju bale ẹjọ giga to wa niluu Akure lori ẹsun iditẹ ati ijọmọgbe.
Gẹgẹ bii ẹjọ ti agbẹjọro ijọba, Bunmi Koyenika, gbe lọ siwaju ile ẹjọ, iya ọmọ naa, Deborah Iretioluwa Olorundare jẹ alarun ọpọlọ lasiko to bi ọmọ ọhun, ko si nile lori, eyi to mu ki awọn ẹlẹyinju aanu gbe lọ sile iowosan MM Catholic Hospital niluu Ondo.
- ''Mo ti gbàdúrà fún àànú láti r'ọ́run wọ̀ lẹ́yìn tí mo wà lábẹ́ ilé tó wó ní Ikoyi fún ọjọ́ kan''
- Bí èsì ìbò gómìnà ṣe ń jáde lọ́wọ́ ní Anambra rèé
- Sanwo-Olu ṣèlérí ìrànwọ́ owó fún ètò ìsìnkú tó dára f'àwọn tí ilé alájà 21 wó pa ní Ikoyi
- Erin wó! Orí Adé kan ti wàjà l'Oyo
- Taaooma tọrọ aforíjìn pé ó bá ìgbákejì ààrẹ ṣèpàdé, èsì Mr Macaroni àtàwọn ọdọ́ rèé
- Àwọn ojíṣẹ́ Ọlọ́run tó yí Buhari ká kò bá a sọ òtítọ́ ọ̀rọ̀- Afenifere
- Alùlùgbayì ọmọ Nàìjíríà tó fI Ìlù kojú ìdẹ́yẹsí ní Amẹ́ríkà rèé
- Màá ṣèrànwọ́ láti dojú ìjà kọ afẹ̀jẹ̀wẹ̀ nílẹ̀ Niger tó pa èèyàn 69 - Buhari
- Ọ̀pọ̀ ẹ̀mí àti dúkìá sọnù sínú ìjàmbá iná Kẹrosínìì l‘Abuja
- Èèyàn 94 kú lásìkò tí wọ́n ń gbọ́n epo bẹntiróòlù
Lẹyin ti ileeṣẹ to n ri si ọrọ awọn obinri n gbọ nipa iṣẹlẹ iya ọlọmọ ọhun ni wọn gbe lọ sile iwosan awọn alarun ọpọlọ, Neuro Psychiatric Hospital, to wa ni Oda Road, l'Akure.
Ṣugbọn lẹyin ti obinrin naa lo oṣu diẹ nile iwosan ọhun lo bẹrẹ si n gbadun, o si bẹrẹ si n bere fun ọmọ rẹ.
Ṣaaju ni wọn ti kọkọ gba ọmọ naa lọwọ rẹ ti wọn si gbe ọmọ ọhun lọ sile awọn ọmọ alaini iya.
Bo tilẹ jẹ pe adehun wa laarin ile iwosan awọn alarun ọpọlọ yii atawọn afurasi lati maa gbe ọmọ naa wa sile iwosan ki iya rẹ le maa ri nitori o le tete jẹ ko gbadun, iroyin ni awọn afurasi naa kọ lati mu ileri wọn ṣẹ.
Lẹyinorẹyin, ara obinrin naa da, o si kuro nile iwosan ti wọn ti n tọju rẹ.
Ẹwẹ, lẹyin to gbadun tan, oun ati ile iwosan bẹrẹ si n bere ọmọ tuntun jojolo naa lemọ-lemọ ni ọrọ gbọna mii yọ.
Iroyin ni awọn afurasi gbe ọmọ kan wa fun obinrin ọhun, ṣugbọn ọmọ okunrin abinrun ni wọn gbe wa fun, eyii to mu ko kọ jalẹ to si n lọgun pe ọmọ oun kii ṣe abinrun, ati pe obinrin ni oun bi.
Lẹyinorẹyin, ileeṣẹ ọtẹmuyẹ DSS da si ọrọ naa lẹyin to fi ọrọ wa iya ọmọ naa, ile iwosan ti ọrọ kan, to fi mọ awọn afurasi lẹnu wo, awọn afurasi ọhun si foju bale ẹjọ.
Ẹsun ti wọn n jẹjọ rẹ niwaju adajọ ile ẹjọ giga niluu Akure ni pe wọn ji ọmọ gbe, wọn si paarọ ọmọ naa pẹlu ọmọ abirun, eyii to waye lọjọ kẹrinla, oṣu Kẹsan an, ọdun 2020.
Iroyin ni iṣẹlẹ yii ti tu aṣiri awọn eeyan kan to maa n ji ọmọ awọn alarun ọpọlọ nileeṣẹ to n ri si ọrọ awọn obinrin nipinlẹ Ondo ge lati ta.
Iwadii DSS fi han pe, lootọ, obinrin ni ọmọ ti a n sọrọ rẹ yii, lootọ si ni awọn afurasi ji ọmọ naa ti wọn si lọ ta fun obinrin kan ti orukọ rẹ n jẹ Toyin Olabiwonninu lẹyin to fun wọn ni miliọnu kan naira.
Ko tan sibẹ, iroyin ni obinrin ti wọn ta ọmọ naa fun, iyẹn Olabinwonnu ti fi Naijria silẹ lọ soke okun, ko si sẹni to le sọ igba ti yoo pada wale.
Wayi o, igbẹjọ ọrọ naa yoo bẹrẹ lọjọ kọkanla, oṣu ti a wa yii ni kootu adajọ A.A Fasanmi nile ẹjọ giga to wa niluu Akure.
















