Nomthi Odukoya: Pásítọ̀ Odukoya pàdánù ìyàwó rẹ̀ ẹlẹ́ẹ̀kejì lẹ́yìn ikú Bimbo Odukoya lọ́dún 2005

Oríṣun àwòrán, pastornomthi
Wọn ti kede eto isinku iyawo Pasitọ Agba ijọ Fountain of Life Church, Nomthi Odukoya.
Ninu ikede kan ti ọkọ rẹ, Taiwo Odukoya fi sori ayelujara Instagram rẹ ni eyi ti jẹyọ.
Ọjọ Aje, ọjọ kẹjọ, oṣu Kẹwaa, ọdun 2021, ni Simangele Rosemary Nomthansazo Odukoya jade laye.
Ẹni ọdun mẹtadinlaadọta ni.
Aisan jẹjẹrẹ si ni ẹbi rẹ sọ pe o pa a, lẹyin to ba a finran fun ọdun meji.
Bi eto naa yoo ṣe lọ niyii:
Aṣalẹ orin ati idaro yoo waye ni ọjọ Aje, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Kọkanla, ọdun 2021.
Eto isinku yoo waye ni ọgbọn ọjọ, oṣu Kọkanla bakan naa.
Ile ijọsin ọkọ oloogbe, Fountain of Life Church, to wa ni adugbo Ilupeju, nipinlẹ Eko, ni awọn eto naa yoo ti waye.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post, 1
Ọmọ orilẹ-ede South Africa ni Nomthi.
O si fi ọmọ meji saye lọ.
Àrùn jẹjẹrẹ ló mú ìyàwó mi lọ, àmọ́ gbogbo wa la ó dágbére lọ́jọ́ kan- Pásítọ̀ Odukoya
Ijọ Fountain of Life Church ti kede iku iyawo Pasitọ Agba wọn, Pasitọ Nomthi Odukoya.
Ijọ naa kede ninu atẹjade kan ti wọn fi sita lori ayelujara wọn.
Gẹgẹ bi atẹjade naa, Pasitọ obinrin Nomthi Odukoya ku nitori aisan jẹjẹrẹ to ba a finra fun ọdun meji.
- Kí ló mú Princess Comedian máa wa ẹkún mu láàrọ̀ kùtù?
- Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ olórí pátápátá fún àwọn ajínigbé kan l'Ekiti
- Ayé òò! Ọmọ ilé ẹ̀kọ́ alákọ́bẹ́ẹ̀rẹ̀ mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n jóná mọ́ yàrá ìkẹ́kọ̀ọ́ tí wọn fi igi àti koríko kọ́
- Ajínigbé ń bèèrè N10m, "Codiene", igbó àtí oúnjẹ fún ìtúsílẹ̀ èèyàn mẹ́ta tí wọ́n gbé l'Ogun
- Ṣé lóòtọ́ ni Lateef Adedimeji àti Bimpe Oyebade fẹ́ ṣègbéyàwó lọ́tẹ̀ yìí lóòtọ́? Lateef bá BBC Yoruba sọ̀rọ̀
- 'Ọba Yorùbá kìí ṣe aláṣẹ ìkejì Orìṣà mọ́ látòní lọ! Krìstẹ́nì, Mùsùlùmí àti Àbáláyé yóò máa ṣe ayẹyẹ pọ látòní'
"Aisan jẹjẹrẹ ba a finra fun ọdun meji, o duro lori ọrọ Ọlọrun, o si ja fitafita."
"A fẹran rẹ pẹlu gbogbo ọkan wa, ṣugbọn taa ni wa lati kọju ija si ifẹ Ọlọrun."
"Otitọ ibẹ ni pe gbogbo wa la o dagbare fun aye. Nitori naa, titi ti a o tun fi pade, o dabọ Pasitọ Nomthi."
Pasitọ Nomthi Odukoya ni iyawo keji Pasitọ Taiwo Odujkoya, to jẹ oludasilẹ ṣọọṣi Fountain of Life Church.
Nomthi fẹ Pasitọ Taiwo Odukoya ni oṣu Kinni, ọdun 2010, lẹyin ti iyawo rẹ akọkọ, Bimbo Odukoya kú ninu ijamba baalu kan ni ọjọ kẹwaa, oṣu Kejila, ọdun 2005.
Ọmọ orilẹ-ede South Africa ni Nomthi jẹ́.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post, 2
Ọdun mọkanla ni igbeyawo wọn, wọn si bi ọmọ meji funra wọn.
Titi di igba to ku, ipo Igbakeji Pasitọ Agba lo wa ninu ijọ naa, nibi to ti n ran ọkọ rẹ lọwọ lati ṣe amojuto ṣọọṣi naa to ni to ẹgbẹrun mẹwaa ọmọ ijọ.
Awọn eekan ilu ba Pasitọ Taiwo Odukoya kẹdun
Aarẹ orilẹ-ede Naijiria, Muhmaamadu Buhari ti ranṣẹ ibanikẹdun si Pasitọ Taiwo Odukoya, lori iku iyawo rẹ Nomthi.
Ọjọ Iṣẹgun ni Nomthi jade laye, lẹyin to ba aisan jẹjẹrẹ finra fun ọdun meji.
Oluranlọwọ fun Aarẹ Buhari lori eto iroyin, Femi Adesina, sọ ninu ikede kan to fi si ori Facebook pe Buhari gbadura ki ọlọrun ti Pasitọ Taiwo Odukoya ninu.
Content is not available
View content on FacebookBBC kò mọ̀ nípa àwọn ohun tí ó wà ní àwọn ojú òpó tí ó wà ní ìta.End of Facebook post, 1
"Aarẹ ba pasitọ naa, ṣọọṣi rẹ ati gbogbo Kristiẹni lapapọ kẹdun lori iṣẹlẹ naa, to si ṣapejuwe rẹ gẹgẹ bi iṣẹlẹ to ba ni lọkan jẹ."
O rọ Pasitọ Odukoya lati gba iṣẹlẹ naa mọra, pẹlu igbagbọ pe ko si nkan to le ṣẹlẹ, lai jẹ pe Ọlọrun mọ si.
Bakan naa ni Igbakeji Aarẹ nigba kan, Atiku Abubakar sọ pe ibanujẹ nla ni ilu Pasitọ Nomthi Odukoya jẹ fun oun. O ni oun gbadura pe ki ẹni to ku sun re o.
Content is not available
View content on FacebookBBC kò mọ̀ nípa àwọn ohun tí ó wà ní àwọn ojú òpó tí ó wà ní ìta.End of Facebook post, 2
















