Niger school fire: Akẹ́kọ̀ọ́ ọmọdé mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n dèrò ọ̀run nínú ìjàmbá iná tó ṣẹlẹ̀ ní yàrá ìkàwé wọn

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Eto isinku ti bẹrẹ fun awọn ọmọde mẹrindinlọgbọn to kú lasiko ti ina jo ile ẹkọ wọn nilu Maradi.
Ọjọ Aje ni ina sọ lara awọn yaara ikẹkọọ wọn ti wọn fi igi ati koriko kọ lorilẹ-ede Niger.
Nibi eto isinku naa, ni awọn minisita ati awọn ọga agba lẹnu iṣẹ ijọba naa peju si.
Ọpọlọpọ awọn ọmọde lo ṣi wa ni ileewosan nibi ti wọn ti n gba itọju nitori ina to jo wọn.
Aarọ kutu ọjọ Iṣẹgun ni awọn obi awọn ọmọ naa pejọ si ileewosan nla to wa ni Maradi, nibi ti wọn gbe oku awọn ọmọ wọn si ṣaaju isinku.
Bakan naa ni ijọba ti kede ọjọ mẹta gẹgẹ bi ọjọ ti wọn o fi ṣọfọ awọn ọmọ naa.
Ọjọ ori wọn wa laarin ọdun mẹta si mẹjọ - ti ọpọ ninu wọn si jona kọja debi pe ko wọn ko ṣe e damọ.
Ko ti si ẹni to mọ nkan to fa ijamba ina ọhun to waye nile ẹkọ alakọbẹrẹ naa.
Ṣugbọn iru ijamba bẹẹ ti waye ri ni ni awọn ile ẹkọ kan ni Niger, to fi mọ olu ilu orilẹ-ede naa, Niamey, to si pa ogunlọgọ ọmọde.
Ni bayii, ijọba ti fi ofin de kikọ awọn akẹkọọ ni awsn yara kilaasi ti wọn fi igi ati koriko ṣe. Ṣugbọn, ko ti i sọ eto miran to ṣe fun awọn kilaasi miran fun wọn.
Ọpọ igba ni ẹnu ti kun ijọba orilẹ-ede naa pe ko pese aabo to peye fun awọn akẹkọọ lẹyin awọn ijamba ina to ti waye sẹyin.
Orilẹ-ede Niger wa lata awọn orilẹ-ede ti eto ẹkọ wọn buru julọ ni agbaye.
Kini ijọba sọ lori iṣẹlẹ ijamba ina yii?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
O kere tan akẹkọọ ọmọde mẹẹdogbọn lo ṣagbako iku lorilẹede Niger ninu ijamba ina to ṣẹlẹ ni yara ikawe wọn lapa guusu orilẹede naa.
Oṣiṣẹ ijọba kan ṣalaye pe awọn ọmọde ọhun ko ju ọdun marun si mẹfa lọ.
Ọpọ eeyan lo farapa yana yana nibi iṣẹlẹ ina ọhun to ṣẹlẹ lasiko tawọn ọmọde naa n gbẹkọọ lọwọ ni yara ikawe wọn ti wọn fi koriko kọ lẹkun Maradi ni Niger.
- Bí mo ṣe ká a sára tí mo gbé òkú ọmọ sínú ọkọ̀ lọ ṣe iṣẹ́ apanilẹ́rìín láì fihàn - Woli Agba Ayo Ajewole
- Ìgbéyàwó Lateef Adedimeji àti Bimpe Oyebade fẹ́ ṣẹlẹ̀ lọ́tẹ̀ yìí? Òtítọ́ tí Lateef sọ fún BBC Yorùbá rèé
- 'Wọ́n gba irun abẹ́ wa, irun abíyá wa, a lọ búra, ilé "Nylon" la tún ń gbé ni Mali fi ṣe iṣẹ́ aṣẹ́wó'
- "Amẹ́ríkà ni Wale Bob-Oseni ń lọ, ìpè fóònù tó gbà, ló gbe lọ síbi ilé tó dà wó"
- Ajínigbé ń bèèrè N10m, codiene, igbó àtí oúnjẹ fún ìtúsílẹ̀ èèyàn mẹ́ta tí wọ́n gbé l'Ogun
- Sanwo-Olu ṣèlérí ìrànwọ́ owó fún ètò ìsìnkú tó dára f'àwọn tí ilé alájà 21 wó pa ní Ikoyi
- Ta ló ni ilé alájá 21 tó wó pa àwọn èèyàn ní Ikoyi gan? Ìjọba Eko ti fèsì
Ko sẹni to ti mọ ohun to ṣe okunfa iṣẹlẹ ọhun titi di asiko ti a kọ iroyin yii.
Lorilẹede Niger, wọn maa n fi igi ati koriko kọ awọn yara ikawe lẹyin ti ile oni bulọọku ko ba gba awọn akẹkọọ mọ.
Adari ijọba ẹkun Maradi, Chaibou Aboubacar, sọ fawọn akọroyin pe yara ikẹkọọ mẹta ni ina yo ninu iṣẹlẹ ọhun.
Ẹnikan ti iṣẹlẹ naa ṣoju rẹ ṣalaye pe oun rii bi wọn ṣe n ko oku awọn ọmọde sinu ọkọ ti wọn si n gbe awọn to farapa lọ si ile iwosan.
O ni ipo to lagbara lawọn ọmọde to farapa ninu iṣẹlẹ naa wa.
Ni bayii, ijọba ti paṣẹ pe ki da igbẹkọ duro ni ile ẹkọ naa.
Ijamba ina lawọn ile ẹkọ ko wọpọ rara ni orilẹede Niger.
Amọ ogun akẹkọọ lo gbẹmi mi ninu iṣẹlẹ ijamba ina to ṣẹlẹ ni ile ẹkọ kan niluu Niamey tii ṣe olu ilu orilẹede sẹyin ninu ọdun yii.
Yara ikẹkọọ ti wọn fi koriko kọ mejidinlọgbọn lo jona ninu iṣẹlẹ naa eleyii to jẹ ki awọn eeyan maa sọrọ.

















