Alaafin: Lẹ́yìn rògbòdìyàn ààfin Ọyọ, ẹ wo bẹbẹ tí Olorì Badra ń ṣe

Olori Badra ati Bobrisky
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Yoruba ni laala to roke, ilẹ lo n bọ, bẹẹ ni aaro kii gbona di alẹ.

Eyi la lee fi se apejuwe ọwọ rogbodiyan to n waye ni aafin Ọyọ nipa ọkan lara awọn ayaba Alaafin Ọyọ, Olori Badrat Olaitan Ajoke Adeyemi, eyi to ti lọ silẹ bayii.

Bẹẹ ba gbagbe Olori Badrat ni ariwo sọ nigba kan pe wọn lo ni ifẹ ikọkọ pẹlu Ọba Fuji,Wasiu Aynde Marshal.

Koda, awọn iroyin kan ti a ko le lee fidi rẹ mulẹ ni Alaafin ti le olori ọhun jade kuro ninu aafin rẹ.

Àkọlé fídíò, Yemen Water Child: Ọmọdé 44 ni Sọ́jà pa, tí 100 míì sì kú látọwọ́ ohun ìjà olóró

Bẹẹ ni awọn eeyan kan n kun kiri pe ilu Eko ni olori Badra wa, to ti bẹrẹ igbe aye tuntun bayii, nitori iriri aye kii ti ni titi, ko ti ni pa, ọgbọn lo fi n kọ ni.

Sugbọn lẹyin rogbodiyan to gba ilu kan nipa olori Badra ọhun, BBC Yoruba lee fidi rẹ mulẹ pe, olori naa ti n dabira pada, to si n ba igbe aye rẹ lọ ni wẹlẹmu.

Ohun ta si lee sọ nipa awọn bẹbẹ ti olori Badra n dawọle ni pe ayaba naa ti gbajumọ isẹ aje rẹ ju ti tẹlẹ lọ, to si mu okoowo rẹ lọkunkundun.

Olori Badrat Olaitan Adeyemi

Oríṣun àwòrán, Instagram/queenola2

Ni ọpọ oju opo ibanidọrẹ Olori Badra lori ayelujara, koko ohun to jẹ logun ni ipolowo awọn ọja aje rẹ, eyi to foju han pe kii se ẹyọ kan ni.

Olori Badra, tii se iya ibeji ni aafin Ọyọ, lo n polowo ọsẹ ati ororo ipara amaradan, agbo to n fa ọrọ kuro ni agọ ara tabi eyi to n se ikun pẹlẹbẹ.

Bakan naa ni Olori Badra tun ti sẹsẹ si sọọbu asọ tita bayii eyi to pe ni Queen Ajoke Closet, bẹẹ lo tun n ba awọn ileesẹ asaraloge miran se ipolowo ọja wọn.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ayaba naa, tii se arẹwa obinrin, ni o ti fi gbogbo rogbodiyan to waye nipa rẹ laipẹ yii se afisẹyin, tii eegun fi asọ, to si n tẹsiwaju nipa aye ati ọrọ aje rẹ.

Àkọlé fídíò, SS3 ní mo wà báyìí, mo sì ti gba àmì ẹ̀yẹ̀ púpò nílé-lóko gẹ́gẹ́ bí onílù - Ayansike

Bi o tilẹ jẹ pe BBC Yoruba ko le sọ pato boya aafin Ọyọ si ni Olori Badra si n gbe abi o ti kuro ninu aafin, gẹgẹ bawọn iroyin kan se n wi kiri.

Amọ ohun to da wa loju ni pe adirẹsi ilu Eko ni awọn ileesẹ aje ayaba naa wa, to si daju pe ilu Eko ni olori naa ti n ri taje se.

Koda, adugbo Ikeja ni adirẹsi sọọbu asọ tuntun ti olori naa sẹsẹ fẹ si bayii, osu Kẹwa to n bọ si lo ni sọọbu naa yoo di sisi.

Nigba to n kede aseyọri rẹ tuntun naa, olori Badra kọ soju opo Instagram rẹ pe ọjọ ti pẹ ti oun ti n gbaa lero lati si ibudo asọ tita, ti inu oun si dun pe ala oun naa papa wa si imusẹ.

Olori Badrat Olaitan Adeyemi

Oríṣun àwòrán, Instagram/queenola2

Sọọbu onibeji, nibi ti wọn yoo ti maa ta asọ ati se ara loge si ni ayaba naa sẹsẹ fẹ si, nibiti wọn yoo ti maa se eekanna, din irun, lu eti, imu ati se irun lọsọ.

Ohun to wa nfoju han gbangba ni pe olori Badra ti n mọ ọpọ gbajumọ nilu Eko, paapa lẹnu ọrọ aje rẹ, to si n fi wsn soju opo ayelujara rẹ.

Sugbọn eyi to jẹ iyalẹnu ni ajọsepọ to wa laarin ayaba Ọyọ naa ati ilumọọka ọkunrin kan to maa n mura bi obinrin, tọpọ eeyan mọ si Bobrisky.

Àkọlé fídíò, Akomolede àti Aṣa: Ọ̀rọ̀ Ẹ̀yán ni Bunmi Femi Amao ń kọ́ wa lórí ètò Akọ́mọlédè àti Àṣà lóri BBC Yoruba

Koda, ninu iwe ifitonileti ti ayaba Badra fisita nipa sọọbu asọ tuntun to fẹ si laipẹ yii, o n kesi awọn ololufẹ rẹ pe ki wọn wa pade oun lọjọ naa nilu Eko, ki wọn si tun wa foju kan Bobrisky, ọkunrin to n mura bii obinrin, ẹni ti oun yoo maa gba lalejo.

Skip Instagram post
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of Instagram post

Ibeere ti ọpọ eeyan si n bi ara wọn ni pe iru ajọsepọ wo lo wa laarin Bobrisky ati ayaba nilu Oyo debi pe yoo maa pe wa sinu ibudo itaja rẹ.

Amọ BBC Yoruba wa n fi akoko yii ki iya Ibeji Alaafin ku oriire nipa ileesẹ aje tuntun rẹ, ta si gbadura pe aje yoo maa wọ igba.