Nkechi Blessing: Blessing ní ìkébé òun tóbí ju ohun tí òun lè dọwọ́ bò lọ, gbogbo èèyàn ló mọ̀

Oríṣun àwòrán, Instagram/NkechiBlessingSunday
Yoruba bọ, wọn ni ọla abata lo n mu odo ṣan an, ọla baba ọmọ ni mu ọmọ yan.
Eyi lo difa fun gbajugbaja oṣere tiata Yoruba, Nkechi Blessing to sọ fawọn akọroyin pe ikebe ti Eleduwa fi jinki oun tobi ju ohun ti oun le dọwọ bo lọ.
Blessing ni gbogbo eeyan lo mọ pe Ọlọrun pari iṣẹ si ẹyin oun, o ni awọn to ni ipenija oju kan to ba sun mọ oun le mọ bi ikebe oun ṣe tobi to.
- Oluwo kọ̀ láti sọ̀rọ̀ lórí àwọn afọbajẹ tó fẹ́ yọ ọ́ nípò, aráàlú fọ́n síta láti fẹ̀hónú hàn
- Ìdùnnú subú layọ̀ nípìnlẹ̀ Ọyọ́, àwọn tó dé láti Lebanon sọ ọmọ wọn ní Seyi
- Mo ṣetán láti ṣe Paulo Costa bí ọṣẹ sẹ ń ṣojú lọ́la- Israel Adesanya
- Èèmọ̀! Àwọn adigunjalè yabo ṣọ́ọ̀ṣì, fipá bá obìnrin kan lòpọ̀, yìnbọn fún òmííràn
Gbajugbaja oṣere naa ni o jẹ iyalẹnu fun oun pe awọn kan n sọ kaakiri wi pe oun maa n ju idi oun fun ṣe ki a ri mi ṣugbọn o sọ pe ọrọ ko ri bẹẹ rara.
Blessing ni aṣiṣe nla lawọn to n sọ pe oun ju idi kiri ki awọn aye le maa sọrọ ṣe nitori iṣu Ọlọrun ti ko ṣe fọwọ bo ni ikebe naa jẹ foun.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post, 1
O tun mẹnu idi ti o fi n gbaruku ti Laycom nile Ẹlẹgbọn Agba iyẹn Big Brother Naija.
Gbajugbaja oṣere Yoruba naa ni ọlọpọ pipe ni Laycom, eyi lo jẹ ki oun maa dibo fun un.
O ni oriṣiiriṣii ẹbun ni Eleduwa fi jinki Laycom eyi to jẹ ko ni ọpọlọpọ ololufẹ to n fẹran rẹ bi oju.
''Ọrọ yii kii ṣe nipa bi oju eeyan ba ṣe gurege si tabi dunwo si nitori ọpọ arẹwa obinrin atawọn ọkunrin ni wọn jọ wa nile Ẹlẹgbọn Agba, ṣugbọn nkankan wa to jẹ ki ọpọ eeyan fẹran Laycom yatọ,'' Blessing lo woye bẹẹ.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post, 2

End of Instagram post, 3
Blessing ni mama Laycom ati ọmọ rẹ obinrin ti n pe oun lori aago lati dupẹ fun bi oun ṣe n gbaruki ti i.
Ko ṣai ṣalaye pe awọn okowo oun loun gbajumọ bayii lati igba ti ajakalẹ aarun covid-19 ti ṣakoba fun gbogbo nkan to fi mọ ere ori itage naa.
Amọ, o ni oun n gbero lati gbe sinima kan jade ni bii oṣu meji si asiko yii.
- Èkúté tó sàwárí bọ́mbù ilẹ̀ gbàmi ẹ̀ye wúrà fún iṣẹ́ takuntakun
- Afurasí Boko Haram pa ológun àti ọlọ́pàá mẹ́rìnlá ní Borno
- Nǹkan yan, àwọn aṣẹ́wó fẹ́ daṣẹ́ sílẹ̀ nítorí ẹ̀kúnwó epo ní Nàìjíríà
- Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ arábìnrin tó fẹ́ ta alòkù kọ́ńdọ́ọ̀mù 324,000 padà f'áwọn èèyàn
- Ìbúgbàmù gbogbo ìgbà nílù ú Èkó, kí ló ń ṣokùnfà rẹ̀?
- Ọlọ́pàá kọlu àwọn ọmọ onílẹ̀, ní ìbọn àṣìyìn pa ènìyàn méjì