Condom factory: Páńpẹ́ òfin gbé arábìnrin tó fẹ́ ta alòkù kọ́ńdọ́ọ̀mù 324,000 padà f'áwọn èèyàn

Aworan aloku kọọndọmu

Oríṣun àwòrán, nld.com.vn

B i o ba n lọ si Vietnam, yaa ri pe o mu rọba idaabobo kọndọọmu rẹ lọwọ ki o ma ba a ṣeṣi ra aloku kọndọọmu.

Ọrọ yi ko ṣẹyin bi awọn alaṣẹ ti ṣe ka ẹgbẹrun okoo le mẹrin o le lọọdunrun (324,000) aloku kọndọọmu mọ arabinrin kan lọwọ to n fọ wọn lati le tun wọn ta.

Ni agbegbe Binh Duong ni ọwọ awọn agbofinro ti tẹ awọn alaburu yi ni ileeṣẹ kan ti wọn ti n fọ kọndọọmu aloku fun tita pada.

Arabinrin kan ti orukọ rẹ n jẹ Pham Thi Thanh Ngoc to ni ileeṣẹ naa jẹwọ fọlọpaa pe eeyan kan lo maa n ko aloku kọndọọmu naa wa fawọn lẹẹkan loṣu.

Pupọ awọn kọndọọmu ti wọn ka mọ wọn lọwọ ni ko ni ami idanimọ lara.

Iroyin sọ pe wọn ti di kilo ọgọtalelọọdunrun kọndọọmu kalẹ ki ọwọ to tẹ wọn.

Aworan aloku kọọndọmu

Oríṣun àwòrán, Newsflash

Bawo ni wọn ti ṣe n fọ kọndọọmu wọn yi?

Iroyin ti a ri ka lati ileeṣẹ iroyin VietNamNews sọ pe wọn maa n fọ aloku kọndọọmu, wọn yoo si sa wọn soorun ki wọn to tun wọn di.

Eyi a maa jẹ ki o dabi ni pe tuntun lawọn aloku kọndọọmu yi loju awọn to ba ra wọn.

Alaṣẹ ijọba kan ṣalaye pe ''ohun eelo ara ni kọndọọmu jẹ nitori naa awọn yoo ṣayẹwo na tawọn eeyan yi fi gba rufin''

Kọndọọmu

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ko daju iye awọn ayederu kọndọọmu tawọn eeyan yi ti ta fara ilu ṣugbọn awọn agbofinro lawọn yoo ṣe iwadii lori rẹ.

Wọn gba awọn kọndọọmu yi lọwọ wọn gẹgẹ bi ẹri ti wọn si ni awọn yoo pada jo wọn nina.

Àkọlé fídíò, SS3 ní mo wà báyìí, mo sì ti gba àmì ẹ̀yẹ̀ púpò nílé-lóko gẹ́gẹ́ bí onílù - Ayansike