Ebonyi rape: Èèmọ̀! Àwọn adigunjalè yabo ṣọ́ọ̀ṣì, fipá bá obìnrin kan lòpọ̀, yìnbọn fún òmííràn

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Awọn adigunjale yabo ṣọọṣi Assemblies of God Church niluu Abakaliki, ipinlẹ Ebonyi nibi ti wọn ti fipa ba ọmọbinrin lopọ.
Iroyin ti a gbọ ni pe ẹgbẹ oṣere awọn ọdọ lo n ṣe igbaradi fun ere ori itage ti wọn fẹ ṣe lọwọ ninu ṣọọṣi tawọn adigunjale ọhun fi de saarin aago kan si meji oru.
Awọn to mọ nipa iṣẹlẹ naa sọ fawọn akọroyin pe awọn janduku naa yinbọn fun ọdọbinrin keji ni itan rẹ lẹyin to kọ ki wọn fi ipa ba oun lopọ.
- Háà, èyí tún ga! Wó ọkùnrin táwọn obìnrin fipá bá lòpọ̀ ní ẹ̀ẹ̀mejì
- Ilé ẹjọ́ ju ọmọ ìjọ tó fi ìpá bá ọmọ pásítọ̀ rẹ̀ sùn ní ìpínlẹ̀ Ondo sí ẹ̀wọ̀n gbére
- Iyabo Ojo, Toyin Abraham, Mercy Aigbe, ta làwọn òṣèrébìnrin yìí gbè lẹ́yìn lórí ọ̀rọ̀ ìfipábánilòpọ̀?
- Ẹ gbọ́ òhun tí àwọn olùdíjé sípò gómìnà nípínlẹ̀ Ondo sọ nípa Bàbá ìsàlẹ̀...
- Oluwo kọ̀ láti sọ̀rọ̀ lórí àwọn afọbajẹ tó fẹ́ yọ ọ́ nípò, aráàlú fọ́n síta láti fẹ̀hónú hàn
Bakan naa ni a gbọ pe awọn ole naa tun ko ọpọ nkan ṣọọṣi naa lọ.
Nigba ti akọroyin iwe iroyin abẹle ṣabẹwo si ṣọọṣi ọhun, ọkan lara awọn alagba ijọ naa to ba nibẹ fidi iṣẹlẹ naa mulẹ pe otitọ lo ṣẹlẹ.
- Èkúté tó sàwárí bọ́mbù ilẹ̀ gbàmi ẹ̀ye wúrà fún iṣẹ́ takuntakun
- Àwọn tó fẹ́ kí ọba máa ta ilẹ̀ ilú ló fẹ́ yọ Oluwo lóyè- Ẹgbẹ̀ Baálẹ̀ Iwo.
- Nǹkan yan, àwọn aṣẹ́wó fẹ́ daṣẹ́ sílẹ̀ nítorí ẹ̀kúnwó epo ní Nàìjíríà
- Ìbúgbàmù gbogbo ìgbà nílù ú Èkó, kí ló ń ṣokùnfà rẹ̀?
- Ọlọ́pàá kọlu àwọn ọmọ onílẹ̀, ní ìbọn àṣìyìn pa ènìyàn méjì
Alagba naa ṣalaye pe awọn ti fi ọrọ naa to ileeṣẹ ọlọpaa leti, bakan naa lawọn si ti gbe awọn ọmọbinrin mejeeji lọ si ile iwosan fun itọju.
Alufaa ijọ naa ko si nile nigba ti akọroyin ṣabọwo si ṣọọṣi ọhun.











