Happy new year 2022: Ohun tí CAN fi ṣíde ọdún 2022 fún gbogbo ọmọ Nàìjíríà nìyí

Aarẹ ẹgbẹ CAN ati ami idanimọ wọn

Oríṣun àwòrán, Others

Ẹgbẹ́ àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi lorileede Naijiria, CAN ti fi ọrọ àkọsọ wọn síta fún àwọn ọmọ Naijiria.

Nínú ọrọ ìkíni kú ọdun tuntun to jade èyí tí Ààrẹ ẹgbẹ́ CAN, Ayokunle Aremu fi ọwọ si lọjọ aisun ọdun.

Ninu atẹjade náà, Alufaa Ayotunde sọ pe ki gbogbo ọmọ Naijiria lai ya ẹṣin kankan sọtọ pé kí wọn gbàdúrà fún àánú Ọlọ́run to lee daabo bo gbogbo orileede to si le fofin si ìṣòro aabo.

"Mo ń pe gbogbo ọmọ Naijiria lai ya ẹṣin kankan sí ọ̀tọ̀ lati dide gbe ohun adura soke fun aanu Ọlọrun to n dáàbò bò wá àti pe ko ba wa fofin si gbogbo ìnira yii ".

Ayokunle ni ó han gbangba pé bii pe ko si ibi ti awọn ijoba lè lọ mọ, wọn ti dé ibi aile sun siwaju lori ìṣòro aabo.

"Afojusun wọn kan ṣoṣo báyìí ni lori idibo ọdun 2023. Àmọ́ njẹ eto idibo leè wáyé bí gbogbo ilu ba kun fún ẹrujẹ̀jẹ̀ àwọn adigunjale".

Àkọlé fídíò, Prophet Hezekiah New Year Prayer: Gbogbo wa ni ká ṣiṣẹ́ fún ìdàgbàsókè Naijiria

Pasitọ yìí ni orileede yii gbudọ ruu ja na lakọkọ ko si wa ni alafia ki idibo kankan to le waye.

Ó ní bi ko ba kí n ṣe ti aanu Ọlọrun ni ati ilọwọsi rẹ ni, orileede yìí ko ba ti di nii ilu Sodomu ati Gomorrah inú bibeli tí Ọlọ́run parun t'ọkùnrin t'obinrin.

"Ọlọ́run nikan lo le jẹ ki idibo ọdun 2023 waye ó!"

O ni Ọlọ́run nikan ni ọna ti ara rẹ lo leè kọ awọn adari ni ọna to tọ láti maa tọ.

"Ọlọ́run nikan lo leè fún wa ní iranlọwọ latoke wá".

O ni nitori iṣẹlẹ aidaa to ń ṣẹlẹ̀, awọn gomina kọ̀ọ̀kan ti ń wá aabo ara wọn ti wọn si n kede konile o gbele. O ni awọn nkan airotẹlẹ ni.

"Bàa bá wà bójú wo àwọn nkan táa gbé ṣe lọdun 2021, ògo ni fún Ọlọ́run wa tó rán wa lọwọ láti borí gbogbo ewu àti idunkoko mọ ni to waye eyi ti awọn ọ̀daràn tún ti kí ara bọọ báyìí fi ń ṣe iṣẹ́ ṣe. Afi bíi pé wọn wọn ti gba ìjọba orileede.

Ó ní ti lo awọn oṣiṣẹ alaabo yọ tan ni apá wọn ko ṣe ka aduru ìṣòro aabo to n yọjú.

"Taa bá ní ká sọ tòótọ́, àwọn Ọlọpaa ń fi ojú àwọn ajinigbe hàn lóòótọ́ lórí Telifisan àmọ́ ìyàlẹ́nu lọ jẹ pe o dabi pé ojú wọn di pẹlu iwadi ṣíṣe nìkan tí wọn ò fi wọn jofin.

Bákan náà lọ mẹ́nu bá pè àwọn àjọ agbaye bíi United Nations tí gba ojú mọ ọrọ Covid-19 ju to bẹẹ tí ẹ̀mí àwọn aráàlú at ààbò wọn kò jọ wọn lójú mọ.

Alufa Ayotunde rọ gbogbo adari ìjọ ọmọlẹ́yìn Kristi ti lo anfani àwọn awẹ àti àdúrà ọdún tuntun tí wọn máa ń ṣe fi yọ Naijiria kúrò lọwọ awọn ti ọkan wọn ti jingiri láti lọ ọrùn àpáàdì, kí wọn mọọmọ gbàdúrà fún àánú Ọlọ́run.

Òun fúnra rẹ gbàdúrà pé ọdún 2022 yóò jẹ ọdún itusilẹ pátápátá kúrò lọ́wọ́ gbogbo ìṣòro aabo to wa ni Naijiria.